'Inú mi kò dùn sí bí Tinubu kò ṣe foyè dá gbogbo àwọn tó jà fún ìjọba àwaarawa lọ́lá'

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹfà ọdún 2025 ni Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu nígbà tó ń bá àpapọ̀ àwọn aṣòfin sọ̀rọ̀ ní àyájọ́ ètò ìṣèjọba àwaarawa kéde fífún àwọn èèyàn kan lámi ẹ̀yẹ pàápàá àwọn tó jà fún ètò ìṣèjọba àwaarawa ní Nàìjíríà.

Lára àwọn tí ààrẹ dá lọ́lá ni aya olóògbé Moshood Abiola, alága àjọ ètò ìdìbò (NEC) nígbà náà, Humphrey Nwosu, tó fi mọ́ igbakeji ààrẹ nígbà kan rí, Shehu Yar'Adua.

Láti ìgbà tí ààrẹ ti kéde ìdálọ́lá yìí ni àwọn kan ti ń kan sáárá sí ààrẹ táwọn míì sì ń bu ẹnu àtẹ́ lu ààrẹ pé kò ṣe tó pẹ̀lú àwọn tó fún lóyè náà.

Lára nǹkan táwọn èèyàn ń sọ ni pé Tinubu kọ̀ láti fi oyè dá àwọn èèyàn bíi Yinka Odumakin, Babafemi Ojudu, Ọ̀jọ̀gbọ́n Mokwugo Okoye, Dr Tunji Abayomi, Dele Momodu, Arthur Nwankwo, Niran Malaolu, Tunde Oladepo, táwọn náà jà fún ìṣèjọba àwaarawa.

Ẹ̀wẹ̀, ààrẹ sọ pé fífi oyè dá àwọn èèyàn náà lọ́lá kò ì tíì pin rárá.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn Channels TV, gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀ rí, tí òun náà wà lára àwọn tó jà fún ìjọba àwaarawa June 12, Dókítà Kayode Fayemi sọ pé inú òun kò dùn sí gbogbo orúkọ tí ààrẹ náà tó.

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn awakọ̀ tó jà fún ìjọba àwaarawa ni ààrẹ kò fi oyè dá lọ́lá nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Fayemi, tó jẹ́ alákòóso fún ètò rédíò Kudirat Abiola nílẹ̀ òkèèrè nígbà náà, sọ pé lára àwọn tó jà fún ìjọba àwaarawa bíi Yinka Johnson, Gbolahan Olalemi, Daniel Johnson, George Noah àti Dókítà Tajudeen Abdul-Raheem àtàwọn míì tó ṣiṣẹ́ lórí rédíò náà ni ààrẹ kò rántí lára àwọn tí ààrẹ fi oyè dá lọ́lá.

Bákan náà ni Dele Momodu sọ pé àwọn kan ń kàn sí òun pé ààrẹ mọ̀ọ́mọ̀ yọ orúkọ òun kúrò lára àwọn tó fi oyè dá lọ́lá.

Dele Momodu ní òun gbàgbọ́ pé ìjọba máa ń fún àwọn èèyàn lọ́lá tó bá ṣe wù wọ́n àti pé kìí ṣe ẹ̀ẹ̀kan péré ní irúfẹ́ oyè bẹ́ẹ̀ máa ń wáyé.

Ó ní òun gbà lóòótọ́ pé àwọn tó ṣe kókó kan wà tí ààrẹ kò fi orúkọ wọn sára àwọn tó fún lóyè náà.

Ó fi kun pé June 12 ti ṣe dada fún òun nípa gbogbo àwọn nǹkan mèremère tó ṣẹlẹ̀ sí òun, tí òun di ọmọ onílùú nílẹ̀ UK.

Bákan náà ló kí àwọn tí wọ́n fún ní oyè náà kú oríire.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ikọ̀ Movement for the Survival of the Ogoni People náà yin Tinubu lákin fú bí ó ṣe fi oyè dá àwọn Ogoni mẹ́sàn-án lọ́lá.

Wọ́n ní kí ààrẹ yọ ẹ̀sùn ìpànìyàn tí wọ́n fi kan Ken Saro-Wiwa àtàwọn yòókù rẹ̀ kúrò lọ́rùn wọn.