Mọ̀ nípa Ken Saro Wiwa, Soyinka, Femi Falana àti àwọn èèyàn tí Iléeṣẹ́ Ààrẹ foríjìn, fún ní àmì ẹ̀yẹ

Aworan Ken Saro Wiwa ati Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Tim Lambon /Greenpeace/Presidency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti paṣẹ iforijin ati fifun ami ẹyẹ nla orilẹede Naijiria fun awọn ọmọ ẹgbẹ Ogoni Nine, ti olori wọn jẹ ajafẹtọ agbegbe ati onkọwe, Ken Saro Wiwa.

Awọn ẹgbẹ Ogoni Nine lo gbe igbesẹ tako iṣẹ ileeṣẹ epo rọbi Shells ni agbegbe Niger-Delta ni ọdun 80s, ti wọn si dero ahamọ, ti ijọba lasiko Sani Abacha si gba ẹmi wọn.

Bakan naa ni aarẹ tu pin ami ẹyẹ nla fun MKO Abiola, Alfred Rewane, Anthony Enahoro ati awọn yooku lasiko to n sọrọ ni ile igbimọ aṣofin niluu Abuja.

Ninu ọrọ rẹ Aarẹ ni o ṣeṣe koko lati fi ẹmi imore han si awọn eeyan to ja fun ijọba awarawa lorilẹede Naijiria.

Tinubu dupẹ lọwọ Aarẹ ana lorilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari fun bi o ṣe gbe igbesẹ lati sọ June 12 di ọjọ ijọba awarawa lorilẹede Naijiria.

Bakan naa ni Aarẹ ni otitọ ni pe Oloye Moshood Kashimawo Olawale Abiola ati akẹgbẹ ti wọn jọ gbe apoti ibo, Babagana Kingibe, lori bori eto idibo June 12, ọdun 1993.

Tinubu tun pin ami ẹyẹ fun eeyan nla lorilẹede Naijiria bi Femi Falana, Wole Soyinka, ati olori ijọ Aguda ni Sokoto Hassan Kukah.

Akọjọpọ orukọ awọn eeyan to gba ami National honours

  • Ọjọgbọn Wole Soyinka (GCON)
  • Ọjọgbọn Olatunji Dare (CON)
  • Kunle Ajibade (OON)
  • Nosa Igiebor (OON)
  • Dapo Olorunyomi (OON)
  • Bayo Onanuga (CON)
  • Ayo Obe (OON)
  • Dare Babarinsa (CON)
  • Biṣọọbu Matthew Hassan Kukah (CON)
  • Sẹnetọ Shehu Sani (CON)
  • Gomina Uba Sani (CON)
  • Femi Falana, SAN (CON)
  • Ọjọgbọn Shafideen Amuwo (CON)
  • Amofin Luke Aghanenu (OON)
  • Sẹnetọ Tokunbo Afikuyomi (CON)
  • Labaran Maku (OON)
  • Ọmọwe Tunji Alausa (CON)
  • Nick Dazang (OON)
  • Abdul Oroh (OON)
  • Odia Ofeimun (CON)
  • Seye Kehinde (OON)
  • Amofin Felix Morka (CON)
  • Amofin Ledum Mitee (CON)
  • Olawale Osun (CON)
  • Amos Akingba (CON)
  • ỌjọgbọnSegun Gbadegesin (CON)
  • Mobolaji Akinyemi (CFR)
  • Dokita Kayode Shonoiki (CON)
  • Ọjọgbọn Julius Ihonvbere (CON)
  • Ọjọgbọn Bayo Williams (CON)
  • Sen Abu Ibrahim (CFR),
  • Sen Ameh Ebute (CFR)
  • Ọgagun Alani Akinrinade, GCON
  • Sam Amuka Pemu CON

Akọjọ awọn oloogbe to gba ami ẹyẹ National Honours

  • Shehu Musa Yar'Adua (GCFR)
  • Ọjọgbọn Humphrey Nwosu (CON)
  • Ọgagun Ojuomi Ndubuisi Kanu (CON)
  • Alhaji Balarabe Musa (CFR)
  • Pa Alfred Rewani (CFR)
  • Bagauda Kaltho (OON)
  • Chima Ubani (OON)
  • Dokita Beko Ransome-Kuti (CON)
  • Alao Aka Bashorun (CON)
  • Oloye Frank Kokori (CON)
  • Emma Ezeazu (OON)
  • Bamidele Aturu (OON)
  • Fredrick Fasehun (CON)
  • Ọjọgbọn Festus Iyayi (CON)
  • Dokita John Yima Sen (OON)
  • Alhaja Sawaba Gambo (CON)
  • Dokita Edwin Madunagu (CON)
  • Dokita Alex Ibru (CON)
  • Oloye Bola Ige (CFR)
  • Pa. Reuben Fasoranti (CFR)
  • Sen Ayo Fasanmi (CON)
  • Sen Polycarp Nwite (CON)
  • Dokita Nurudeen Olowopopo (CON)

Ta ni Ken Saro Wiwa?

Ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, lọdun 1995 ni ile ẹjọ ologun kan dajọ iku fun Ken Saro Wiwa atawọn akẹgbẹ rẹ mẹjọ ti wọn n ja fun irapada ayika agbegbe Ogoni lorilẹ-ede Naijiria.

Ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan wọn, ijọba ologun nigba naa labẹ ọgagun Sani Abacha fi ẹsun kan wọn pe wọn lọwọ ninu iku awọn agba ilẹ Ogoni mẹrin kan.

Ọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun 1995 ni wọn pa wọn.

Ni igba aye rẹ, Ken Saro Wiwa ko jẹ ki awọn ileeṣẹ ìwapo rọ̀bì lẹkun naa o sinmi nitori awọn idibajẹ ti aibikita iṣẹ wọn n ko ba ayika nigba naa.

Titu epo si oju agbami, eleyi to n ṣe ọpọ akoba fun awọn ohun abẹmi ninu omi agbegbe naa. n mu inira nla ba awọn eeyan ibẹ nitori iṣẹ ẹja pipa ni gbajugbaja iṣẹ nibẹ.

Ohun to yẹ ko mọ nipa Kudirat Abiola

Kudirat Abiola jẹ opo nla gidi nidi agbekalẹ eto isejọba alagbadada, a ko sile sọrọ June 12, ka yọ ipa to ko sẹyin nitori o fi ẹmi rẹ lelẹ fun ijọba alagbada ni.

Wọn bi Kudirat Olayinka Adeyemi ni ilu Zaria lọdun 1951, lati igba ọdọ rẹ lo ti n fi apẹrẹ akinkanju han.

Ijẹri ohun to ṣe ni ileewe girama. Muslim Girls High School lo soo di odidi alagbara obinrin pẹlu iṣẹ takuntakun to fi jẹ adari gbogbo ọmọ ile iwe ni kilaasi aṣekagba rẹ.

Ọmọ ọdun mọkanlelogun lo fẹ Oloye Moshood Abiola.

Alhaja Kudirat ni iyawo keji ti Abiola fẹ ṣugbọn oun ni iyale ninu awọn iyawo rẹ lasiko ti wọn pa a.

Ọmọ meje ni Kudirat bi fun ọkọ MKO Abiola - Yisau Olalekan, Hafsat Olaronke, Abdul Mumuni Khafila, Hadi, Moriam, Jamiu Abiodun ati Olalekan Yisau Abiola.

Ta a ni Wole Soyinka?

Igi araba ni Akinwande Oluwole Babatunde Soyinka nile ati lẹyin odi gẹgẹ bi ọmọ kaaro o jiire ati ọmọ Naijiria ṣugbọn Wole Soyinka sọọ ni awọn eeyan mọ ọ si.

Ọmọ bibi ilu Isara-Remo ni Ọjọgbọn Wole Soyinka jẹ to si jẹ ẹlẹkeji ninu ọmọ mẹfa ti iya rẹ bi ni ilu Abeokuta ipinlẹ Ogun. Wọn bi i lọjọ kẹtala, oṣu keje, ọdun 1934.

Baba Wole, Samuel Ayodele Soyinka jẹ olufọkansin alufa ijọ Anglican ati adari ile iwe alakọbẹrẹ ti iya rẹ, Grace Eniola Soyinka si jẹ ontaja o tun jẹ ajafẹtọ nipa oṣelu laarin awọn obinrin.

Nitori naa, ọgba inu ile ijọsin Anglican ni wole Soyinka gbe ni kekere to si n kọ ẹkọ nipa ẹsin Kristẹni lọdọ awọn obi rẹ.

Amọ, bo ṣe n kọ eyi naa lo tun n kọ imọ nipa aṣa ati ẹsin Yoruba lọdọ baba baba rẹ.