Kí ló mú kí Soun kéde kónílé-ó-gbélé ọlọ́jò mẹ́jọ fáwọn obìnrin l'Ogbomoso?

Oríṣun àwòrán, Soun of Ogbomoso/Instagram
Soun ilẹ Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, ti kede konile o gbele ọlọjọ mẹjọ fawọn obinrin niluu Ogbomoso nitori ọdun Oro.
Ọba Olaoye sọrọ yii ninu atẹjade kan ti akọwe Aafin Ogbomoso, Toyin Ajamu, fi sita.
Kabiyesi sọ ninu atẹjade naa wi pe lalẹ oni ọjọ Ẹti ọjọ kẹtala ni konile o gbele ọhun yoo bẹrẹ.
Lati ago mejila oru oni ọjọ Ẹti ọjọ kẹtala oṣu Kẹfa ni ọdun Oro naa yoo bẹrẹ.
Ọdun naa yoo maa waye lati ago mejila titi di ago mẹrin idaji lojoojumọ titi di ogunjọ ọjọ Ẹti ọsẹ to n bọ ti ọdun naa yoo kasẹ nlẹ.
Soun wa rọ awọn obinrin niluu Ogbomoso lati duro sinu ile wọn titi ti ọdun Oro naa yoo pari.
Kabiyesi tun sọ ninu atẹjade naa wi pe awọn ọlọpaa ni yoo gbe ẹnikẹni to ba tapa si ofin konile o gbele yii.
Bakan naa ni Ọba Ghandi sọ ninu atẹjade ọhun wi pe ko gbọdọ si ilu lilu lati ibẹrẹ titi de ipari ọdun Oro naa niluu Ogbomoso.
Soun rọ gbogbo olugbe ilu Ogbomoso lati fọwọ sowọ pọ ki ọdun Oro naa le kẹsẹ jari.

Oríṣun àwòrán, Aafin Ogbomoso















