Malik gún orogún ìyá rẹ̀ lọ́bẹ pa ní Ìlọrin

Aworan ile oloogbe
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iṣẹlẹ a gbọ bo mi loju lo ṣẹlẹ lana niluu Ilọrin, to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara nigba ti ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni malik gun orogún ìyá rẹ Falilat Yusuf lọbẹ pa.

Iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bi ago kan ọsan ana, lagbegbe Danialu ni Gaa Akanbi niluu Ilọrin.

BBC Yoruba ṣabẹwo si ile oloogbe lati mọ bi iṣẹlẹ ṣe waye.

Tesilim to jẹ ọkan lara awọn ọmọ oloogbe naa sọ pe, nnkan bi ago kan ọsan lẹyin ti awọn kirun Jimọh tan ni iṣẹlẹ naa waye.

O fikun pe, Malik jẹ ọmọ obirin kan ti Baba awọn n fẹ, to si gbatọ ṣugbọn obirin naa ati ọmọ rẹ n gbe ile mii ti Baba awọn gba fun wọn ladugbo kan naa.

O salaye pe, Malik ma n jale ni ile awọn lawọn se ni ko ma de ile awọn mọ.

O tẹsiwaju pe lana ọjọ jimọh lẹyin ti awọn kirun Jimọh tan ni oun ri Teslim lẹgbẹ ile awọn.

Teslim salaye pe bi oun se n ti ibi irun Jimọh bọ oun ri Teslim to n fọwọ ni ita, bi o ṣe ri oun lo sa lọ.

Igba ti oun wọ le loun ba iya oun ninu agbara ẹjẹ ti oun si pariwo sita .

Bi awọn se n sunkun ninu ile awọn ni Teslim pada de to si ti parọ aṣọ to wọ.

Ibẹ ni oun ti pariwo pe oun lo pa mama oun, bi awọn se n bi lere ni awọn ri ẹjẹ lara bata rẹ.

Ti awọn si ti fa a le awọn ọlọpaa lọwọ nibi to ti jẹwọ pe lootọ loun pa mama oun.

Teslim fikun ọrọ rẹ pe, titi ti awọn fi sin mama awọn ni nnkan bi ago meje alẹ ana ẹjẹ o da lara rẹ.

Ọkan lara awọn ara adugbo naa, arabinrin Omotayọ sọ pe, iya Teslim to n ta oduku ti salọ nitori awọn eeyan ti wọn fẹ wa kọlu.

Aṣojukọroyin wa kan si Alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ kwara Arabinrin Ejirẹ Adeyemi Adetoun ṣugbọn ko ti fesi.