EFCC figbe ta lórí báwọn ọmọ Yahoo kò ṣe dúró mọ́ lórí jìbìtì ayélujára àmọ́ wọ́n ń jí èèyàn gbé, bá olóṣèlú jí owó kó lọ sókè òkun

Aworan awọn afurasi ọmọ Yahoo

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria ti sọ pe opin ko le tii de ba awọn ọdọ to n lu jibiti lori ayelujara nitori oriṣiiriṣii nnkan ni wọn n ṣe bayii lati lu jibiti.

Alaga ajọ EFCC, Olanipekun Olukoyede, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu fidio kan ti ajọ naa fi lede loju opo Facebook rẹ.

Ọgbẹni Olukoyede sọ pe ọrọ awọn ọmọ Yahoo fẹ amojuto gidi ni kiakia tori ọrọ naa ti di egbinrin ọtẹ, to jẹ pe bi a ti n pa ọkan lominiran tun n ruwe.

Olukoyede ni ''Ọpọ araalu lo maa n sọ pe awọn ọmọ Yahoo nikan ni EFCC n le kiri, nigba ti wọn fi awọn eeyan to n ji ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira owo Naijiria silẹ.

Ohun to yẹ kawọn eeyan kọkọ mọ ni pe awọn ọmọ Yahoo to n lu jibiti lori ayelujara ti ba orukọ Naijiria jẹ.

Oju buruku, oju ọdaran lawọn eeyan ilẹ okeere fi maa n wo awọn ọmọ Naijiria nigba kugba ti wọn ba yọ iwe irinna wọn jade fun ayẹwo.

Awọn mii tiẹ maa sọ fun yin ki eeyan lọ da duro sibi kan, kete ti ẹni naa ba ti yọ iwe irinna rẹ gẹgẹ bi ọmọ Naijiria jade loke okun'' alaga EFCC lo sọ bẹẹ.

Ọgbẹni Olukoyede ni ọpọ igba ti oun ba wa laarin awọn akẹgbẹ oun nilẹ okeere ni oju maa n ti oun nitori bi awọn ọmọ Yahoo ti ba orukọ Naijiria jẹ.

Alaga EFCC ni laipẹ yii ni ajọ naa fọwọ ofin mawọn ọdọ to le ni ọgọfa ti n wọn n lu awọn eeyan ni jibiti lori ayelujara.

Ọgbẹni Olukoyede sọ pe awọn ọdọ aye ode oni ko fẹ jaramọ iṣẹ mọ lati rowo mọ.

''Mo wa lati ipinlẹ ti eto ẹkọ jẹ nnkan iwuri fun wa, ṣugbọn lonii nnkan ti yatọ.

Ti ẹ ba de ile ẹkọ girama ti mo lọ lonii, nigba ti yoo ba fi di ago mejila ọsan, pupọ ninu awọn akẹkọọ ti kuro nile ẹkọ.

Ọpọ ninu wọn ni yoo gba ile itura lọ nibi ti wọn ti n lu awọn eeyan ni jibiti.

Laye ode oni ni ẹ maa ri awọn akẹkọọ ile ẹkọ girama ti wọn n lo ọkọ, ṣe awọn to maa dipo olori mu ni Naijiria lọla niyi?'' Olukoyede lo sọ bẹẹ.

Awọn ọmọ Yahoo ti n gbebọn, wọn n jawọn eeyan gbe, wọn tun bawọn oloṣelu ji owo ko lọ silẹ okeere

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alaga ajọ EFCC ni kii ṣe jibiti ori ayelujara nikan lawọn ọmọ Yahoo n ṣe bayii, o ni ọpọ ninu wọn lo ti n gbe ibọn.

Ọgbẹni Olukoyede ni awọn ọmọ Yahoo ti n ji awọn eeyan gbe pawo bayii.

''Ti wọn ko ba ti ri eeyan lu ni jibiti nigba mii, wọn maa n ji eeyan gbe.

Ẹri to daju lati fidi eyi mulẹ wa, ọpọ eeyan si mọ pẹlu tori o n jade ninu iwe iroyin.

Ni bayii, ọpọ ọmọ Yahoo lawọn oloṣelu n lo lati ji owo ko lọ soke okun.

Nitori naa, ẹ ma foju onijibi ori ayelujara lasan wo awọn ọmọ Yahoo mọ.

Ọna tawọn eeyan fi n ji owo ijọba ko tẹlẹ ti nira bayii, nnkan ti wọn n ṣe bayii ni pe wọn n gbe owo ti wọn ba ti ji ko sinu akaunti awọn ọmọ Yahoo.

Lati ibẹ ni wọn ti n ko owo yii lọ silẹ okeere, apo ikowosi ''crypo'' ni wọn maa n ṣi fawọn ọmọ Yahoo yii.

Lati inu akaunti yii ni wọn ti maa n gba owo yii lati ra ile, ra ọkọ tabi ra dukia ti wọn ba fẹ.

Awọn oloṣelu yii lo maa n fi awọn ọmọ Yahoo si ile itura nibi ti wọn ti n ṣi akaunti ''Crypto'' fun wọn.

Lẹyin naa ni wọn yoo paarọ owo naira si dọla ti wọn yoo si gbe owo naa sinu apo ikowosi awọn ọmọ Yahoo yii."

Nibo ni ọdunkunrin ti ko tii ṣiṣẹ ri ti ri biliọnu marun un naira laarin oṣu mejidinlogun?

Oludari ajọ EFCC tẹsiwaju pe "Ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan wa ti a mu lẹyin ti a ri i pe owo to le ni biliọnu marun un wọ inu akaunti rẹ laarin ọdun kan ati abọ."

Nibo ni ọdunkunrin ti ko tii ṣiṣẹ ri ti ri biliọnu marun un naira laarin oṣu mejidinlogun?

Iwadii wa fi han pe awọn oloṣelu lo n lo awọn ọdọ yii lati ji owo ko lọ silẹ okeere, ọmọ naa wa ni ahamọ EFCC bayii nigba ti iwadii si n lọ lori ọrọ naa,'' Olukoyede ṣalaye.

Alaga EFCC ni ọrọ awọn ọmọ Yahoo ti kọja ohun tawọn eeyan kan maa n sọ pe ''ẹ fi wọn silẹ, awọn oyinbo ni wọn n lu ni jibiti.

Awọn oloṣelu ti n lo ọmọ Yahoo lati ji owo ijọba ko lọ silẹ okeere bayii.

Ọpọ ọmọ Yahoo ni wọn n lo awọn ọdọbinrin fun etutu ọla, awọn araalu gan na mọ nipa eleyii.

A ba ikoko nile ọmọ Yahoo kan ti a mu, iwadii fi han pe irun ori obinrin lo wa ninu ikoko naa.

Alaga EFCC ni awọn ọmọ Yahoo yii n ṣakoba fun ọrọ aje ati orukọ Naijiria.

Amọ, o ni ajọ naa ko ni kaarẹ ninu akitiyan rẹ lati gbogun ti awọn ọmọ Yahoo to n ba orukọ rere orilẹede Naijiria jẹ.

O wa rọ awọn araalu lati fọwọ sowọ pọ pẹlu EFCC lati gbogun ti awọn ọmọ Yahoo ti wọn jẹ kanda ninu irẹsi ọmọ Naijiria.