2027: Wàhálà bẹ̀rẹ̀ ní APC, ẹkùn ìlà oòrùn Àríwá fòǹtẹ̀ jan Tinubu fún sáà kejì, àmọ́ dákẹ́ lórí Shettima bíi igbákejì ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Presidency
Bi wọn ko se darukọ Kashim Shettima gẹgẹ bi igbakeji Aarẹ Bola Tinubu fun saa keji ti bẹrẹ sii da wahala silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
Awuyewuye to waye nibi ipade ẹgbẹ APC apa ila oorun ariwa lo fidi ọrọ yii mulẹ.
Ọrọ bẹyin yọ nibi ipade ẹlẹkunjẹkun to waye lopin ọsẹ nipinlẹ Gombe lẹyin tawọn adari ẹgbẹ naa kede Tinubu gẹgẹ bii oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu APC lọdun 2027 lai darukọ Shettima gẹgẹ bi igbakeji re.
Ikede naa da wahala silẹ ninu gbọngan ti ipade ọhun ti waye nibi ti alaga gbogbogbo APC, AbdulLahi Ganduje, awọn gomina, minisita, awọn gomina tẹlẹ ri atawọn abẹnugan ninu ẹgbẹ APC ti w ani ijokoo.
Ṣaaju ipade yii lawọn kan ti n sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC ti n gbe igbesẹ lati rọ Shettima nipo, ti ẹlomiran ti yoo dije pẹlu Tinubu ninu ibo aarẹ ọdun 2027.
Adari ẹgbẹ APC kan nipinlẹ Yobe, Alhaji Adamu Yahaya, fidi rẹ mulẹ pe ede-ai-yede bẹ silẹ nibi ipade awọn olori ẹgbẹ APC lẹkun ila oorun ariwa naa to waye ni Gombe.
Alhaji Adamu sọ pe ''ai darukọ Shettima gẹgẹ bi oludije pẹlu Tinubu ninu ibo aarẹ ọdun 2027 da ariyanjiyan silẹ.
Olori ẹgbẹ APC gan an ko darukọ Shettima, awọn kan n sọ pe o ṣee ṣe ki wọn fi ẹlomiran rọpo rẹ.
Ọrọ ti adari ẹgbẹ APC sọ wi pe Tinubu nikan ni Naijiria lai na-an ni Shettima lo bi ọpọ eeyan to wa nibi ipade naa ninu.
Eyi lo jẹ kawọn kan to wa nibi ipade ọhun ran alaga APC leti pe ko tii darukọ Shettima, amọ, ko tori eyi da orukọ igbakeji aarẹ.''
Awọn olori ẹgbẹ APC kan sọ pe o yẹ kawọn adari ẹgbẹ naa fi ọwọ wọ Shettima papaa julọ pẹlu bi ipade ọhun ṣe waye lẹkun rẹ.
Bayii lawọn eeyan bẹrẹ sii lẹ ẹ ni ọra omi ati aga titi tawọn ẹṣo eleto abo fi sin in jade lati ibi ipade naa.
Gomina ipinlẹ Bauchi tẹlẹ, Alhaji Abdulmalik Mahmud, sọ pe irinajo laarin aarẹ ati igbakeji ni ọrọ naa jẹ eyi to yẹ ki gbogbo ẹgbẹ gbaruku ti awọn mejeeji.
Lara awọn to binu nibi ipade ọhun ni gomina ipinlẹ Borno, Babagana Umara Zulum, to wa lati ipinlẹ kan naa pẹlu Shettima.
Gomina Zulu dide nibi ipade naa, o si sọ pe ''Tinubu ati Kashim ni wọn gbọdọ yan.''
Ọrọ akin ti gomina Borno atawọn olori ẹgbẹ mii sọ lo jẹ ki wọn buwọ lu Shettima gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije pẹlu Tinubu ninu ibo aarẹ ọdun 2027.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba Tinubu ṣẹṣẹ pe ọdun meji ni, ọpọ oloṣelu lo ti bẹrẹ ipolongo fun eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.
Ki ni rogbodiyan yii tumọ si fun ẹgbẹ oṣelu APC?
Ẹwẹ, awọn onimọ nipa eto oṣelu ti sọ pe nnkan iyalẹnu lo jẹ wi pe rukerudo ti n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC lati isinyii lọ ti eto idibo ọdun 2027 si wa niwaju.
Ọjọgbọn Abubakar Kari to jẹ onimọ nipa eto oṣelu sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ APC kan wa ti wọn fẹ ki ẹlomiran rọpo Shettima ki ẹni naa si dije pẹlu Tinubu ninu ibo aarẹ ọdun 2027.
Ọjọgbọn Kari ni ''ọpọ awọn abẹnugan ẹgbẹ APC lẹkun ti Shettima ti wa lo wa lẹyin rẹ, awọn eeyan kan fẹ ki wọn rọpọ rẹ.
Wahala ni ọrọ naa yoo da silẹ ti wọn ba fi le rọpọ Shettima pẹlu ẹlomiran.''
Ọjọgbọn Kari ni nnkan to ṣẹlẹ nibi ipade awọn olori ẹgbẹ APC to waye ni Gombe fi han pe rogbodiyan yoo bẹẹ silẹ ninu ẹgbẹ naa ti wọn ba gbiyanju lati fi ẹlomiran rọpo Shettima.
Awọn adari ẹgbẹ APC lẹkun iwọ oorun ariwa ninu eyi tawọn gomina, ọmọ ile aṣofin agba l'Abuja atawọn minisita wa kede atilẹyin wọn fun Aarẹ Tinubu loṣu Karun un to kọja ṣaaju ibo aarẹ ọdun 2027.
Bo tilẹ jẹ pe Tinubu fun ra rẹ ko tii kede pe oun yoo dije fun ipo aarẹ fun saa keji, awọn onimọ nipa eto oṣelu n kọminu lori awọn nnkan tawọn oloṣelu ti bẹrẹ sii ṣe ṣaaju ibo gbogbogbo ọdun 2027.















