Ohun tí a mọ̀ nípa ìgbésẹ̀ Trump láti ti ilẹ̀kùn Amẹrika mọ́ Naijiria àti orílẹ̀èdè 35 míì

Aarẹ Donald J. Trump

Oríṣun àwòrán, Donald J. Trump

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba Amẹrika ti n gbe igbeṣe to le mu ko tun fofin de orilẹede mẹrindinlogoji mii lati ma le wọ Amẹrika mọ.

Igbesẹ yii lo wa ninu lẹta abẹle kan ti ajọ to n ri si ọrọ iṣejọba Amẹrika, State Department kọ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ibẹrẹ oṣu yii ni ijọba ilẹ naa fofin de orilẹede mejila pe wọn ko gbọdọ wọ Amẹrika mọ lọna ati daabo awọn ọmọ ilẹ naa lọwọ awọn agbesunmọmi lati ilẹ okere.

Ileeṣẹ iroyin Reuters jabọ pe Naijiria wa lara awọn orilẹede tuntun to ṣeeṣe ki Trump tun fofin de.

Ibẹrẹ ọdun yii ni Trump kọkọ da awọn ọmọ orilẹede Venezuela kan pada si El Salvador lori ẹsun pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ onijagidijagan to n da ilu ru.

Ki ni eredi ti Amẹrika fi fẹ fofin de awọn orilẹede tuntun yii?

Akọwe ijọba Amẹrika, Marco Rubio sọ pe ijọba ilẹ naa n kọminu lori awọn ohun kan to n ṣẹlẹ, tabi to ṣeeṣe ko ṣẹlẹ lo jẹ ko maa mura lati gbe igbesẹ tuntun yii.

Rubio ni "Ijọba yii ti ṣawari awọn orilẹede mẹrindinlogoji ti a n kọminu nipa wọn, o si ṣeeṣe ki a fofin de wọn patatapa tabi ki a fofin de wọn fun igba diẹ ti wọn ko ba ṣe awọn nnkan ti a n fẹ."

Lara awọn nnkan ti Rubio mẹnuba ni bi ko ṣe si ibaṣepọ to dan mọran laarin Amẹrika ati ijọba awọn orilẹede naa, to fi mọ bi wọn ṣe kuna lati pese awọn iroyin kan nipa awọn eeyan wọn to wa l'Amẹrika.

State Department tun mẹnuba abo ti ko dantọ to wa lori iwe irinna awọn orilẹede ọhun.

A tun gbọ pe awọn kan lara awọn orilẹede naa kọ lati mu awọn eeyan wọn kuro l'Amẹrika lẹyin ti ijọba Amẹrika paṣẹ pe ki wọn ṣe bẹẹ.

Wọn tun fi kun pe awọn ọmọ awọn orilẹede naa kan tun kọ lati fi Amẹrika silẹ lẹyin ti ọjọ ti lọ lori fisa ti Amẹrika fun wọn.

Ijọba Amẹrika tun fi kun pe eredi igbesẹ oun tun da lori bi awọn ọmọ orilẹede ti ọrọ naa kan ṣe n kopa ninu igbesunmọmi l'Amẹrika.

O ti wa fun kọ, o ṣeeṣe ko fofin de awọn eeyan rẹ lati ma le wọ Amẹrika mọ.

Awọn orilẹede ti ọro naa kan

Awọn orilẹede ti ọrọ yii kan ni Angola, Antigua and Barbuda, Benin, Bhutan, Burkina Faso, Cabo Verde, Cambodia, Cameroon, Cote D'Ivoire, Democratic Republic of Congo, Djibouti, Dominica, Ethiopia, Egypt, ati Gabon.

Awọn to ku ni The Gambia, Ghana, Kyrgyzstan, Liberia, Malawi, Mauritania, Niger, Naijiria, Saint Kitts and Nevis, Saint Lucia, Sao Tome and Principe, Senegal, South Sudan, Syria, Tanzania, Tonga, Tuvalu, Uganda, Vanuatu, Zambia, ati Zimbabwe.