Ìdúnàádúrà pẹ̀lú agbébọn jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ sọ́mọ Nàíjíríà, kò sí ibi tó ti so èso rere ní àgbáyé, àbàmọ̀ ló ń gbẹ̀yìn rẹ̀ - Àwọn aṣòfin kan yarí

Àwọn ajínigbé tó fi aṣọ bojú, gbé ìbọn kọ́rùn, tí wọ́n sì tún fi ọta ìbọn kọ́rùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Àwọn aṣòfin kan nílé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ ìjọba Tinubu lórí ìlànà tó ń gbà kojú ìpèníjà ètò ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra.

Àwọn aṣòfin náà, láti ẹkùn mẹ́fẹ́ẹ̀fà tó wà ní Nàìjíríà, kọminú lórí ìpèníjà ààbò ṣe ń fi ojoojúmọ́ peléke síi àti bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ń wà nínú inú fu àyà fu lójoojúmọ́.

Àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde lọ́jọ́rú ni wọ́n ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìlànà tí ààrẹ ń gbà kojú ìṣòro ààbò, tí wọ́n sì ní ààrẹ kò ṣe ojúṣe rẹ̀ bó ṣe yẹ.

Ṣáájú níbi ìjòkó ilé tó wá lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, àwọn aṣòfin fi ẹdùn ọkàn wọn hàn lórí ìpèníjà ààbò Nàìjíríà, tí wọ́n sì rọ ìjọba àpapọ̀ láti tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ìpèníjà yìí.

Àwọn aṣòfin tí wọ́n kó ara wọn jọ náà bu ẹnu àtẹ́ lu bí ìjọba ṣe ń bá àwọn agbébọn jíròrò lórí ìkọlù tí wọ́n ṣe sáwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Lára àwọn aṣòfin náà ni Muhammed Soba láti ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá, Zakari Mohammed láti ààrin gbùngbùn àríwá, Olasupo Abiodun láti gúúsù ìwọ̀ oòrùn, Sadiq Ibrahim láti ìlà òòrùn àríwá, Uko Nkole láti ìlà oòrùn gúúsù, àti Bassey Ewa láti ààrin gbùngbùn gúúsù.

Wọ́n wòye pé ṣíṣe ìdúnàádúrà pẹ̀lú àwọn agbébọn jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ sáwọn èèyàn Nàìjíríà nítorí wọ́n ń bá àwọn ọ̀daràn jíròrò dípò kí wọ́n fi òfin gbé wọn.

Wọ́n ní kìí ṣe irú àsìkò yìí táwọn èèyàn Nàìjíríà ń sunkún lórí pípè fún ààbò tó péye ló yẹ kí ìjọba máa bá àwọn tó jí àwọn ọmọdé gbé, tí wọ́n ń ṣe ìkọlù sáwọn obìnrin láì bìkítà, tí wọ́n sì ń da ọ̀pọ̀ ìlú láàmú ló yẹ kí ìjọba máa bá jíròrò.

Nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù tó wáyé ní Kano, Kwara, Kebbi, Niger àtàwọn ìpínlẹ̀ míì, àwọn aṣòfin náà níṣe ni ìjọba dákẹ́, tí wọ́n sì ń gba ọ̀nà ẹ̀yìn láti máa bá àwọn ọ̀daràn ṣe ìpàdé.

'Kò sí ibití bíbá àwọn agbébọn jíròrò ti so èso rere káàkiri àgbáyé, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tó ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Kò sí orílẹ̀ èdè tó ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ tó máa ma bá àwọn ọ̀daràn ṣe ìdúnàádúrà. Kò sí ibití bíbá àwọn agbébọn jíròrò ti so èso rere káàkiri àgbáyé, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tó ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn.

"Ní Colombia, ìjíròrò tí ìjọba bá àwọn ikọ̀ Revolutionary Armed Forces mú àlékún bá ìjínigbé láti fi máa bèèrè owó, tó sì tún rọgun sápá àwọn ikọ̀ náà.

"Ní Afghanistan, ààyè tí wọ́n fi gba àwọn Taliban tó fi mọ́ pípàrọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ló fi ààyè gba àwọn ẹgbẹ́ láti gba ìjọba orílẹ̀ èdè náà.

Àwọn aṣòfin náà ṣèkìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ láti yàgò fún bíba àwọn agbéṣùmọ̀mí jíròrò àti pé ìgbésẹ̀ náà yóò túnbọ̀ máa pọnkún ìwà ipá tó ń wáyé.

Wọ́n ní ìjọba ń sọ pé àwọn kò kajú òṣùwọ̀n, tí wọ́n sì ń pè fún àlékún ìjínigbé àtàwọ n ìwà ọ̀daràn míì, tí kò sì ní jẹ́ káwọn aráàlú ní ìgboyà nínú wọn mọ́.

Àwọn aṣòfin náà tẹmpẹlẹmọ pé iṣẹ́ àkọ́kọ́ ìjọba ni láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èèyàn.

Wọ́n ní àwọn ọmọ Nàìjíríà nílò orílẹ̀ èdè tí àwọn ọ̀daràn yóò máa bẹ̀rù àwọn aláṣẹ, kìí ṣe èyí tí àwọn aláṣẹ yóò ti máa bẹ̀rù ọ̀daràn.

Wo kókó ohun tó fà á tí Ààrẹ Tinubu ṣe kó àwọn ọlọ́pàá kúrò lẹ́yìn àwọn èèkànlú ní Nàíjíríà

Ọlọpaa to n ba obinrin kan gbe baagi

Oríṣun àwòrán, @Fifi_Ify

Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu ti pàṣẹ pé gbogbo àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n máa ń ṣe ẹ̀ṣọ́ lẹ́yìn àwọn èèkàn ìlú ni kí wọ́n kó kúrò báyìí láti lè máa pèsè ààbò tó péye fún aráàlú.

Ìkéde ààrẹ yìí ló jáde nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ, Bayo Onanuga sọ pé gbogbo àwọn ọlọ́pàá náà ni wọ́n máa dá padà sí ojúlówó iṣẹ́ wọn.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, ààrẹ pàṣẹ ìgbésẹ̀ náà níbi ìpàdé tó ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀gá ẹ̀ṣọ́ ààbò tó fi mọ́ ọ̀gá ọlọ́pàá, ọ̀gá ẹ̀ṣọ́ ààbò orí omi, iléeṣẹ́ ológun àti adárí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, DSS ní ìlú Abuja.

Ààrẹ ní èèkàn ìlú tó bá ń fẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò, kí wọ́n lọ kọ̀wé sí iléeṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò ara ẹni lààbò ìlú ìyẹn Nigeria Security and Civil Defence Corps, NSCDC láti fún wọn ní ẹ̀ṣọ́ ààbò tó ní nǹkan ìjà ogun.

Ààrẹ wòye pé ọ̀pọ̀ àwọn agbègbè pàápàá àwọn tó jẹ́ abúlé ni wọn kò ní ọlọ́pàá tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó sì jẹ́ kó ṣòro fún àwọn ọlọ́pàá péréte tó wà ní agbègbè náà láti máa dá ààbò bo àwọn aráàlú bó ṣe yẹ.

"Pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà tó ń kojú ètò ààbò Nàìjíríà lọ́wọ́ yìí, Ààrẹ Tinubu ń gbèrò láti pọnkún ìpèsè àwọn ọlọ́pàá ní gbogbo ìlú."

Àtẹ̀jáde náà tún fi kun pé Ààrẹ Tinubu ti buwọ́lu gbígba àwọn ọlọ́pàá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000) kún àwọn tó ti wà tẹ́lẹ̀.

Bákan náà ló ní ìjọba àpapọ̀ yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ láti mú àtúnṣe bá àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó wà fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn ọlọ́pàá.

Ìkéde ààrẹ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn táwọn agbébọn ṣe ìkọlù sáwọn ilé ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ Kebbi àti Niger tí wọ́n sì jí ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé lọ.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kọjá ni àwọn agbébọn tún ṣe ìkọlù sí àwọn olùjọsìn ní ilé ìjọsìn CAC, ìlú Eruku, ìpínlẹ̀ Kwara níbi tí wọ́n ti jí àwọn olùjọsìn méjìdínlógójì gbé lọ.

Ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹtàlélógún, ọjọ́ Kọkànlá, ọdún 2025 ni ààrẹ kéde pé àwọn olùjọsìn náà ti gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àkàtà àwọn ajínigbé.