Kí ni ìtúmọ̀ ìlànà 'non-kinetic' tí ìjọba ní òun fi dúnàádúrà gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kebbi àti olùjọ́sìn Eruku lọ́wọ́ àwọn ajínigbé?

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kebbi tí wọ́n gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àkàtà àwọn ajínigbé

Oríṣun àwòrán, Yushau Shuaib

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ni ìjọba àpapọ̀ kéde pé àwọn ti gba ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama Government Girls Comprehensive Senior Secondary School (GGCSS) Maga, ìpínlẹ̀ Kebbi, lẹ́yìn táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lo ọjọ́ mẹ́sàn-án ní àhámọ́ ajínigbé.

Ààrẹ Bola Tinubu, nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀, Bayo Onanuga fi léde sọ pé ìlànà ìdúnàádúrà láì lo ipá ni wọ́n fi gba ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, gómìnà ìpínlẹ̀ Kebbi, Nasir Idris sọ pé ìjọba kò san owó kankan láti gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀.

Ó fi kun pe láyọ̀ àti àlááfíà ,ni àwọn ọmọ náà wà àti pé wọ́n máa darapọ̀ mọ́ àwọn òbí wọn lọ́jọ́rú.

"Ilana Kinetic túmọ̀ sí lílo àwọn ohun ìjà ogun bíi ìbọn, àdó olóró àtàwọn ìjà olóró míì, non-kinetic sì jẹ́ lílo ìdúnàádúrà àti ìlànà bíbá àwọn tí wọ́n ń bá ja ogun sọ̀rọ̀ ìtùnù"

Ìbéèrè tó gba ẹnu ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé kí ló ń jẹ́ ìdúnàádúrà "non-kinetic" tí ìjọba ní àwọn lò láti gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀.

Èyí ló mú BBC News Yoruba kàn sí ọ̀gágunfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ológun Nàìjíríà, Lukman Gidado láti ṣàlàyé ohun tí ìgbésẹ̀ yìí túmọ̀ sí nínú iṣẹ́ ológun.

Gidado, tó tún jẹ́ ọ̀mọ̀wé nínú ìmọ̀ ìpẹ̀tùsááwọ̀ ṣàlàyé pé, nínú iṣẹ́ ológun, ọ̀nà méjì ni wọ́n máa ń gbà láti ja ogun lójúnà àti ri pé ohun tí wọ́n ń fẹ́ wá sí ìmúṣẹ.

"Tí a bá ń sọ̀rọ̀ ogun, ọ̀nà méjì ni a máa ń gba ja ogun, àkọ́kọ́ ni kinetic, tí èkejì sì jẹ́ non-kinetic."

Ó ṣàlàyé pé kinetic túmọ̀ sí lílo àwọn ohun ìjà ogun bíi ìbọn, àdó olóró àtàwọn ìjà olóró míì láti fi kojú àwọn tí wọ́n bá ń bá ja ogun náà.

Nígbà tí non-kinetic sì jẹ́ lílo ìdúnàádúrà, ìlànà bíbá àwọn tí wọ́n ń bá ja ogun sọ̀rọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n ri pé ohun tí àwọn ń ṣe kò dára.

Ó sọ pé èyí máa ń fún àwọn ológun ní àǹfàní láti bá àwọn èèyàn náà jíròrò láti jẹ́ kí wọ́n mọ ipa tí ìgbésẹ̀ wọn le ní lórí ètò ààbò.

'Lílo ìlànà non-kinetic ló dára jùlọ láti fi gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ nítorí ààbò wọn'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gidado wòye pé lílo ìgbésẹ̀ non-kinetic ló tọ̀nà jù láti fi gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kalẹ̀ nítorí òun ni ọ̀nà tó dára jùlọ láti ri pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kò farapa lọ́wọ́ àwọn ajínigbé tó fi wọ́n fi àhámọ́.

"Àwọn ológun ti mọ ibi tí àwọn agbébọn tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gbé wà. Tí wọ́n bá ju àdó olóró síbẹ̀, ó ṣeéṣe káwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà farapa tàbí kí wọ́n ba lọ.

"Ṣé a máa sọ pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ba lọ ni? Ìgbésẹ̀ tí ìjọba gbé ló dáa jù nítorí àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n fẹ́ gbà kalẹ̀."

"Tí ìjọba bá ní kí àwọn lọ yìnbọn níbẹ̀ ó túmọ̀ sí pé wọ́n fẹ́ pa àwọn ọmọ yẹn ni nítorí àwọn agbébọn náà le lò wọ́n láti fi dá ààbò bo ara wọn."

Ọ̀gágunfẹ̀yìntì náà sọ pé pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra lọ́wọ́ yìí, ohun tó tọ́ ni kí ìjọba wádìí ohun tó ń mú àwọn agbébọn náà mọ ohun tó ń ṣokùnfà tí wọ́n fi ń jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjọsọ̀ ló ti máa wáyé láàárín ìjọba àtàwọn ológun kó tó di pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gba ìtúsílẹ̀ tí ìjọba kò sì ní lè jáde sọ fún àwọn èèyàn látàrí ọ̀rọ̀ ààbò tó jẹ́.

'Lílo ìgbésẹ̀ ìdúnàádúrà ní irú àsìkò yìí kò túmọ̀ sí pé ìjọba tàbí àwọn ológun kò kájú òṣùwọ̀n'

Lórí ọ̀rọ̀ pé ìgbésẹ̀ ìdúnàádúrà yìí yóò máa jẹ́ kóríyá fáwọn agbébọn tó ń jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé káàkiri ilé ẹ̀kọ́, Gidado ní kìí ṣe gbogbo ìgbà ni ìlànà yìí máa ń jẹ́ ṣíṣe àmúlò, tó sì jẹ́ pé nígbà tí ìnílò rẹ̀ bá wáyé ni wọ́n máa ń lò ó.

Ó ní tí ìjọba kò bá tètè gbé ìgbésẹ̀ láti gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ lásìkò, ó ṣeéṣe káwọn agbébọn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní lo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún lọ́nà tí kò dára.

Ó ní wọ́n le máa lò wọ́n láti dá ààbò bo ara wọn tàbí kí wọ́n máa fipá báwọn lòpọ̀, èyí tó le ṣàkóbá fún ọjọ́ ọ̀la àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ó tẹ̀síwájú pé lílo ìgbésẹ̀ ìdúnàádúrà ní irú àsìkò yìí kò túmọ̀ sí pé ìjọba tàbí àwọn ológun kò kájú òṣùwọ̀n láti ṣe ohun tó yẹ, ó ní ó máa ń jẹ́ láti wá ààbò àti àlááfíà àwọn èèyàn tó wà ní àkàtà àwọn ajínigbé bíi irúfẹ́ èyí tó wáyé ní Kebbi níbi tí ìjọba ti nílò láti dá ààbò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní àhámọ́ wọn.

Ó sọ pé kìí ṣe Nàìjíríà nìkan ni ìjọba ti máa ń lo ìlànà yìí tí wọ́n bá ń fẹ́ nǹkan, tí wọn kò sì fẹ́ kí ìtàjẹ̀sílẹ̀ wáyé rárá.

Ó ní àwọn orílẹ̀ èdè ńlá bíi Amẹ́ríkà, China àti Russia náà máa ń lo ìgbésẹ̀ yìí pàápàá tí wọ́n bá ri pé lílo ìwà ipá yóò túnbọ̀ ṣàkóbá fún ohun tí àwọn bá ń fẹ́ ni.

Ṣé non-kinetic le fopin sí ìwà ìgbéṣùmọ̀mí àti ìjínigbé àwọn agbébọn?

Ọ̀gágun Gidado ní kìí ṣe gbogbo ìgbà ni ìlànà yìí máa ń mú àṣeyọrí tí èèyàn bá ń fẹ́ jáde.

Ó wòye pé ìjọba kò lè lo ìlànà yìí tí wọ́n bá kẹ́fín pé àwọn agbésùmọ̀mí tàbí àwọn agbébọn bá fẹ́ ṣe ìkọlù sí ibìkan láti dáwọn dúró.

"Tó bá jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń bọ̀ wá láti jí àwọn ọmọ yìí gbé ni àwọn agbébọn náà kojú wọn, ohun tó yẹ láti ṣe ni láti kojú wọn pẹ̀lú gbígbé ìjà kò wọ́n lójú láti ri pé wọn kò súnmọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà rárá."

Ó ní ìjọba nílò láti ri pé gbogbo àwọn ohun ìjà táwọn ológun àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó kù nílò láti máa kojú àwọn ọ̀daràn ni ìjọba nílò láti pèsè fún wọn.

Ó ní èyí yóò jẹ́ kí wọ́n le máa ṣe iṣẹ́ wọn bó ṣe tọ́ àti lọ́nà tó yẹ àti pé yóò lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn ìgbésẹ̀ àwọn agbéṣùmọ̀mí náà kí wọ́n tó ṣọṣẹ́ rárá.

Bẹ́ẹ̀ náà ló fi kun pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ìlú ìyẹn NSCDC tó yẹ kí wọ́n máa ṣọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ni wọn kìí sí ní ilé ẹ̀kọ́ kankan nítorí àìní ohun ìjà tó péye lọ́wọ́ àti àìní òṣìṣẹ́ tó.

Ọ̀gágun náà ní dídá àwọn iléeṣẹ́ ààbò sílẹ̀ ní Nàìjíríà kò dàbí fífún àwọn iléeṣẹ́ náà ní ohun èlò tó péye láti fi ṣe iṣẹ́ wọn.

Ó wá rọ ìjọba láti ṣe àwọn nǹkan tó yẹ lójúnà àti lè jẹ́ káwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ṣe iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún wọn àti láti ri pé ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Nàìjíríà dúró ire padà.