Àwọn afurasí Adanranjẹ̀ ló ya wọ Isapa, yìnbọn lu ìyá àgbà, a ti wọnú igbó lọ pẹ̀lú Fijilańté láti gba èèyàn mẹ́wàá tí wọn jí gbé padà - Ọlọ́pàá Kwara

Oríṣun àwòrán, Debo Ore
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti sọrọ sita lori isẹlẹ ijinigbe to waye nilu Isapa nijọba ibilẹ Ekiti, ni ipinlẹ Kwara.
Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyemi Toun fisita ni irọlẹ ọjọ Isẹgun ni wọn ti sọrọ nipa isẹlẹ naa.
Atẹjade naa ni loootọ ni awọn agbebọn kan ṣina ibọn bolẹ ni ilu Isapa, lẹgbẹ Obbo-ile, nijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara.
Ọlọpaa ni iṣẹlẹ naa sẹlẹ ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun oṣu yii.
"Ikọ oludoola ajọ ọlọpaa ti wọ inu Igbo lọ pẹlu awọn Fijilante, lati doola awọn ti wọn ji gbe, ki ọwọ si tẹ awọn oniwa laabi ọhun"
Wọn ni nigba tawọn n gba ipe lọtun-un losi, pe awọn ajinigbe ti ṣina ibọn bolẹ ni awọn fi awọn ọlọpaa sọwọ sibẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa naa sọ pe, awọn kan ti wọn fura si gẹgẹ bi adaranjẹ lo yabo ilu naa, ti wọn si yinbọn lu iya arugbo kan lẹsẹ.
Obinrin naa farapa, wọn gbe e lọ fun itọju, o si ti pada si ile rẹ.
Ileesẹ ọlọpaa Kwara salaye pe ikọ oludoola ajọ ọlọpaa ti wọ inu Igbo pẹlu awọn Fijilante, lati doola awọn ti wọn ji gbe naa, ki ọwọ si tẹ awọn oniwa laabi ọhun.
O fikun ọrọ rẹ, pe kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara; Adekimi Ojo, ti sabẹwo si ilu Isapa lati mọ bi nnkan ṣe ri nibẹ.
"Eeyan mẹwaa ni wọn jigbe ni Isapa, a si maa doola awọn ti wọn ji gbe pada wale layọ"
Atẹjade naa ni lasiko abẹwo naa, Adekimi ba ọba ilu Isapa , Ọba Gbenga Adeyeye ati Olokesa ti Okesa sepade, pẹlu awọn olori ọdọ.
Awọn ọlọpaa naa si fọwọ sọya lati doola awọn ti wọn jigbe pada wale layọ.
O tẹsiwaju pe ileeṣẹ ọlọpaa Kwara fidi ẹ mulẹ, pe eeyan mẹwaa ni wọn jigbe.
Bakan naa ni Adekimi sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara yoo sa ipa rẹ lati doola gbogbo awọn ti wọn ji gbe.
Alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ni alaafia ti pada si ilu naa.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army
Alaye ree lori bi ajínigbé tún se jí èèyàn mẹwaa gbé ní Isapa, lẹ́bà ìlú Eruku
Egbirin ọtẹ, bi a se n pa ọkan, ni ominran n ru ni ẹka eto aabo ni ipinlẹ Kwara ati ilẹ Naijiria lapapọ.
Idi ni pe iroyin miran to tun n tẹ wa lọwọ, ti akọroyin wa si ti fidi rẹ mulẹ ni pe awọn ajínigbé tun ti ya wọ ìlú Ìsàpà nipinlẹ Kwara, ti wọ́n si jí èèyàn mọ́kànlá gbé lọ.
Akọtun isẹlẹ ijinigbe yii si lo n waye lẹyin wakati merinlelogun tawọn agbebọn yọnda awọn olujọsin mejidinlogoji ti wọn ji gbe ni ilu Eruku nijọba ibilẹ Ekiti ipinlẹ Kwara.
Ilu Isapa yii si lo wa ni ijọba ibilẹ Ekiti bakan naa, to si tun sun mọ ilu Eruku.
Awọn ajinigbe naa, ti wọn ji eeyan mọkanla gbe ni ilu naa, tun yinbọn mọ iya agbalagba kan.
"Ọdẹ ibilẹ kan lo kọkọ lọ koju awọn agbebọn, agbebọn yinbọn lu u, sugbọn ibọn kọ wọle si i lara"
Gẹgẹ bi ẹni ti isẹlẹ naa soju rẹ, to ba akọroyin BBC News Yorùbá sọrọ se wi, deedee aago meje asalẹ ọjọ Aje ana ni isẹlẹ naa waye nilu Isapa.
Ọgbẹni kayọde fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ọdẹ ibilẹ kan lo kọkọ lọ koju awọn agbebọn naa, ti wọn si yinbọn lu, sugbọn ibọn naa kọ wọle si lara .
Lẹyin eyi, Kayode ni wọn kọlu awọn araalu, ti wọn si yinbọn mọ iya agbalagba lẹyin eyi, wọn ji eeyan mọkanla gbe.
"Hausa mẹwa lọkunrin ati obinrin pẹlu alaboyun kan to jẹ ẹya Yoruba ni wọn ji gbe.
O salaye pe inu ibẹru bojo lawọn eeyan agbegbe naa wa lati ana, ti ko si ti si igbesẹ kankan lori ẹ.
O fi diẹ mulẹ pe, awon mẹta ninu awọn mọkanla naa ti mori bọ lọwọ awọn ajinigbe naa, ti wọn si wa ni ilu Eruku bayii.
"Alaboyun wa lara awọn ti wọn ji gbe pẹlu eeyan marun ninu mọlebi kan naa"
Ọkan lara awọn ọdẹ agbegbe naa, ọgbẹni Wasiu to ba BBC News Yorùbá sọrọ nipa iṣẹlẹ yii sọ pe, alaboyun wa lara awọn ti wọn ji gbe.
O salaye pe eeyan marun ninu mọlebi kan naa wa lara awọn ti wọn jigbe.
Nigba ti awọn akọroyin kan si alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Toun Adeyemi ,ko tii sọ nkan kan lori iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Kwara ko ti i fi atẹjade kankan sita lori isẹlẹ naa.
"Àwọn agbébọn tó jí wa gbé ti gba gbogbo inú igbó kan, kò sí ọ̀nà tí a fẹ́ gbà sálọ, kò sí ọ̀nà tó wà ní Kwara, tí wọn kò mọ̀"

Oríṣun àwòrán, Ibraheem Lateef
Ọkan ninu awọn olujọsin ti ori ko yọ ninu isẹlẹ ijinigbe to waye ninu sọọsi CAC nilu Eruku nipinlẹ Kwara, ti jade sita lati sọ ohun ti oju rẹ ri.
Ọkunrin naa, to n jẹ Bamidele Emmanuel, ninu fidio kan to wa lori ayelujara, lo ti sọrọ lerefee nipa ohun ti oju gbogbo wọn ri ni ahamọ naa.
Ninu Fidio naa, to ṣafihan igba ti awọn eeyan ti wọn ji gbe naa de si ile ijọba, ni ọkunrin naa ti ṣalaye nipa irinajo wọn sọdọ awọn ajinigbe ọhun.
Ọdọkunrin yii ṣalaye pe aja to re ile ẹkun to bọ, ni ibi ti wọn ko awọn lọ naa.
O ni gbogbo agbegbe naa ni awọn ajinigbe ọhun ti gba akoso rẹ, ko si si ọna ti eeyan le fi sa mọ wọn lọwọ rara.
"Ọpọ awọn agbebọn lo ti gba inu igbo ti a wa kan, koda, wọn tun lori laya maa sọ fun wa pe isẹ agbebọn ati ijinigbe nisẹ awọn"
O fi kun un pe, aya ko awọn agbebọn naa pupọ, niṣe ni wọn n sọ fawọn pe ijinigbe niṣẹ awọn.
Pẹlu ibẹru ti ọmọkunrin naa fi ṣalaye, kedere lo han pe ahamọ ọlọjọ marun-un naa ko rọgbọ.
Ọmọdekunrin naa sọ pe awọn ajinigbe ọhun ti mọ gbogbo agbegbe naa, ati awọn ibi to sunmọ Kwara.
"Iroyin ko to afojuba ni isẹlẹ naa jẹ fun wa.
Nigba ti a de inu igbo ti wọn ko wa lọ, a ri pe ọpọ awọn agbebọn lo ti gba inu igbo naa kan.
Koda, wọn tun lori laya maa sọ fun wa pe isẹ agbebọn ati ijinigbe nisẹ awọn.
Wọn tun fi ọwọ gbaya pe ko si ẹnikankan ninu wa to le sa mọ awọn lọwọ, ti awọn ko ni mọ.
Pẹlu gbogbo ohun ti oju wa ri naa, a ri pe ko seese fun wa lati sa ni ahamọ awọn ajinigbe naa.
Koda, gbogbo oju ọna to wọ ipinlẹ Kwara ni wọn ti mọ, bii igba ti wọn mọ atẹlẹwọ wọn."

Lóòótọ́ la gba àwọn èèyàn tí agbébọn jí gbé ní Eruku padà àmọ́ ìdí rèé tí a kó fi mu àwọn ajínigbé - Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá
Ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria lo n beere pe ki lo de to jẹ pe idasilẹ awọn eeyan mejidinlogoji ti won ji gbe ni CAC Eruku nikan ni araalu n gbọ.
Àmọ́ ti ko sẹni to gbọ pe wọn mu agbebọn kankan lori iṣẹlẹ naa?
Ní báyìí, Kayode Egbetokun, tíí ṣe ọga ọlọpaa pata ni Naijiria, ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ.
Ẹ o ranti pe irọlẹ ọjọ Aiku ọsẹ yii ni iroyin gbode, pe awọn olujọsin ti awọn agbebọn ji gbe niluu Eruku, ipinlẹ Kwara, ti gba itusilẹ.
Aarẹ Bola Tinubu gan-an lo ṣe ikede naa loju opo X rẹ.
Ṣugbọn ijọba Aarẹ Bola Tinubu to kede itusilẹ naa, ko sọrọ nipa mimu awọn to ji eeyan mejidinlogoji naa gbe.
Bakan naa ni wọn ko si sọ nnkan kan nipa boya wọn sanwo itusilẹ ti awọn ajinigbe naa beere.
"Ọdaran to ba fẹ tọ oju opo alaafia, a ko ni i kọ fun un, a maa gba a laaye"
Nigba to n dahun ibeere naa fun awọn akọroyin to beere lọwọ rẹ, ọga ọlọpaa pata ni Naijiria, Kayode Egbetokun, sọ pe
" Ọdaran to ba fẹ tọ oju opo alaafia, a ko ni i kọ fun un, a maa gba a laaye.
"Bi wọn ba fẹ juwọ silẹ pe awọn ko ja mo, a maa ki wọn kaabọ.
Ṣugbọn eyi ko tumọ si pe a maa fi ọwọ yẹpẹrẹ mu bi a ṣe n dọdẹ wọn."
Egbetokun ṣalaye ninu fidio to ti dahun ibeere naa, pe awọn agbebọn ọhun lo jade funra wọn, ti wọn wa ba awọn sọrọ alaafia, to pada ja si bi awọn ti wọn ji gbe ṣe gba ominira.
Tẹ o ba gbagbe, eeyan mẹta ni awọn ajinigbe naa pa ni ṣọọṣi CAC Oke-Isegun, Eruku, ti ijinigbe ọhun ti waye.
Lẹyin ti awọn ajinigbe naa si ko eeyan mejidinlogoji wọgbo lọ tan, ni wọn beere fun ọgọrun-un miliọnu (100m) lori ẹnikọọkan ti wọn ji gbe.
Apapọ owo ti wọn beere naa si jẹ 3.8b, ki wọn too tun pada din i ku.
Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Egbetokun sọ pe ọpọ igba ni ileeṣẹ ọlọpaa ti kilọ fun araalu, lati ma ṣe fiya jẹ agbofinro to n ṣiṣẹ rẹ.
O ni bi wọn ba ri i pe iwa ọlọpaa kan tabi iṣesi rẹ ko ba tiwọn mu, ki wọn fi ẹjọ ọlọpaa bẹẹ sun ni ileeṣẹ ọlọpaa, lọdọ awọn to ju u lọ.
Ọga agba ọlọpaa Naijiria naa fi kun un pe awọn ko ni i da iru ifisun bẹẹ nu.
O ni awọn yoo tuṣu rẹ de isalẹ ikoko lati mọ ohun to ṣẹlẹ gan-a ni.
Àwọn tí wọ́n jí gbé l'Eruku ti dé, ṣùgbọ́n a kò mọ̀ bóyá ìjọba sanwó ìtúsílẹ̀- Ọba Eruku

Oríṣun àwòrán, Getty Images/ BBC
Lati irọlẹ ana ti iroyin itusilẹ awọn olujọsin ṣọọṣi CAC ti wọn ji gbe ni Eruku, ipinlẹ Kwara, ti gbode ni ọpọ eeyan ti n beere pe ṣe awọn ajinigbe naa lo deede tu wọn silẹ ni tabi ijọba lo sanwo idande ti wọn fi de.
Ibeere nipa boya ijọba sanwo itusilẹ yii naa n jẹyọ latari bi awọn eeyan naa ṣe gba ominira lẹyin ọjọ marun-un ti wọn ti wa lakata awọn to gbe wọn lọ lasiko ijọsin, lọjọ Iṣẹgun to kọja.
Lati dahun ibeere to jẹ ọpọ araalu logun ti wọn si n beere naa, BBC Yoruba kan si ọba ilu Eruku, Kabiyesi Busari Olarewaju ti i ṣe Owa ti ilu Eruku.
Nigba ti Owa Eruku n fidi ẹ mulẹ pe awọn olujọsin mejidinlogoji ti wọn ji gbe naa ti de, o ṣalaye pe:
Ninu alaye Owa Eruku, Oba Busari sọ pe:
"A ko duro latigba ti ọrọ naa ti ṣẹlẹ, ẹni kan ti kọkọ fi to mi leti pe awọn eeyan mi maa de, pe wọn maa sun sile wọn lalẹ ọjọ Aiku.
"Ẹni naa sọ fun mi pe a o tiẹ ni i sanwo kankan ti wọn a fi de. Eyi ya mi lẹnu pupọ, ṣugbọn mo ṣaa mu un mọra."
Kabiyesi tẹsiwaju pe ẹnikan pada ba oun sọrọ, o sọ pe awọn naa maa pada sile, nitori wọn ti ṣe ohun ti awọn fẹ fun awọn.
O ni nigba to di bii aago kan oru ni awọn DSS pe oun, wọn ni awọn eeyan ti wọn ji gbe ti de, ṣugbọn kounma ti i sọ fun ẹnikẹni.
Nigba to n ṣafikun lori ibeere olowo itusilẹ yii, Kabiyesi ilu Eruku sọ pe:
"A gbọ pe wọn ti de, a dẹ ri wọn lori Facebook ati lori ẹrọ amohumaworan. Bi wọn ṣe de ko ye wa, ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun."
Àwọn ọ̀dọ́ Eruku bèèrè fún ìtẹ̀síwájú ààbò, wọ́n ní káwọn agbófinró má tí ì lọ
Lasiko ti awọn ọdọ ilu Eruku lọ ṣabẹwo idupẹ si Kabiyesi Busari Olarewaju, iyẹn lẹyin ti awọn to wa nigbekun ti de, wọn beere fun awọn nnkan kan lọwọ ọba naa.
Nnkan akọkọ ti awọn ọdọ naa beere fun ni pe ki awọn ẹṣọ alaabo ti ijọba ran wa si Eruku ma ti i fi ilu naa silẹ bayii.
Wọn ni inu ibẹru ni awọn eeyan ṣi wa.
Awọn ọdọ fi kun un pe awọn kan tilẹ ti sa kuro l'Eruku, awọn to si wa nibẹ paapaa ko fi ifọkanbalẹ gbebẹ.
Wọn ni bi awọn ọlọpaa ba ṣi tẹsẹ duro fun aabo Eruku, yoo mu awọn to ti sa lọ niluu pada, awọn to si fi ọkan akin duro naa yoo le fi ẹdọ le ori oronro.
Bakan naa ni wọn beere fun anfaani lati le da aabo bo ara wọn.
Awọn ọdọ naa sọ pe ọpọ ọlọde Eruku lo ti dagba, ti agbara ko si fun mọ.
Wọn ni to ba ṣe pe awọn ọdọ naa ni nnkan ija lọjọ ikọlu, o ṣee ṣe kawọn naa le pitu meje.
Bakan naa ni wọn tun rọ awọn ọdọ yooku lati ma ṣe fi jagidijagan ṣe e, wọn ni ki wọn ba awọn agbofinro to ba wa niluu ṣe lọna irọrun, ki agbofinro naa si fi ti ọmọniyan ṣe.
Kabiyesi Eruku ninu idahun rẹ, sọ pe oun ko sinmi nipa bi alaafia yoo ṣe jọba.
O ni oun n ba awọn alaṣẹ sọrọ, lorii bi Bareke ologun yoo ṣe wa l'Eruku, ti eto aabo ibẹ yoo si fẹsẹ rinlẹ si i.














