Irọ́ ni pé agbébọn jí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lọ ní Nasarawa – Ọlọ́pàá

Ọwọ agbebọn pẹlu ibọn

Oríṣun àwòrán, Anadolu Ajansı

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Nsarawa ti sọ pe irọ ni iroyin to n lọ ni igboro pe awọn agbebọn yabo ile ẹkọ St. Peter's Academy to wa ni ijọba ibilẹ Rukubi ti wọn si ji akẹkọọ meji gbe lọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Ramhan Nansel, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan lorukọ kọmiṣọna ọlọpa, Shetima Mohammed.

Atẹjade ọhun sọ pe irọ ni iroyin to ni awọn agbebọn ya bo ile ẹkọ naa ni ijọba ibilẹ Doma lati ji akẹkọọ meji lọ.

O ni "irọ to jina si ootọ ni irọyin naa, ko si ohun to jọ bẹẹ."

"Ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ni iroyin kan ti ko fidi mulẹ sọ pe wọn ji akẹkọọ meji lati ile ẹkọ St. Peter's Academy lasiko ti wọn n ṣere idaraye lori papa ile ẹkọ wọn.

"Ni kete ni kọmiṣọna ọlọpaa, Shetima Mohammed, fi awọn agbofinro atawọn ologun to wa lagbegbe naa ṣowọ sibẹ.

"Wọn ṣakiyesi pe ọdẹ ni awọn akẹkọọ naa ri pẹlu ibọn lọwọ wọn ti wọn si ro pe ajinigbe ni wọn.

"Awọn agbofinro ti yẹ gbogbo agbegbe naa wọn finifini, gbogbo nnkan si ti pada bọ sipo lagbegbe ọhun."

Irọ ni pe wọn ji akẹkọọ wa meji gbe lọ - Adari ile ẹkọ

Ọlọpaa ni adari ile ẹkọ naa, Peter Zabutu, ti fidi rẹ mulẹ pe ko si ohun to jọ ijinigbe akẹkọọ nile ẹkọ oun.

O ni "lonii ni wọn n ṣe ire idaraya, fun idi eyii, wọn lọ sori papa lati ṣere idaraya.

"Nigba ti meji ninu awọn akẹkọọ naa ri awọn ọdẹ pẹlu ibọn lọwọ wọn, wọn sare lọ ba awọn olukọ wọn pe wọn ri awọn eeyan to gbe ibọn dani."

O ni lasiko ti olukọ wọn ni ki wọn pada si kilaasi lawọn ninu awọn akẹkọọ naa bẹrẹ si n pariwo pe wọn ri awọn ajinigbe.

O ni "ni kete ti awọn akẹgbẹ wọn gbọ ajinigbe ni gbogbo wọn fi ẹsẹ fẹ. Ka to wi, ka to fọ, wọn ti lọ sọ fun awọn obi wọn pe awọn ajinigbe wa sile ẹkọ wọn.

"Fun odidi wakati mẹta bayii, ko si obi kankan to wa sọ fun wa pe awọn ko ri eyikeyi ninu awọn ọmọ wọn."

Wayi o, ọlọpaa ti ni ki awọn araalu ko ọrọ ijinigbe nile ẹkọ naa danu.