Tórí ìgbélárugẹ àṣà àti ìṣe Yorùbá ló jẹ́ kí n fi iṣẹ́ agbẹjọ́rò sílẹ̀ fún eré orí ìtàgé - Bolanle Austen-Peters

Àkọlé fídíò, Tórí ìgbélárugẹ àṣá àti ìṣe Yorùbá ló jẹ́ kí n fi iṣẹ́ agbẹjọ́rò sílẹ̀ fún eré orí ìtàgé - Bolanle Austen Peters
Tórí ìgbélárugẹ àṣà àti ìṣe Yorùbá ló jẹ́ kí n fi iṣẹ́ agbẹjọ́rò sílẹ̀ fún eré orí ìtàgé - Bolanle Austen-Peters

Gbajugbaja oludari ati olootu ere n ni, Bolanle Austen-Peters, sọ pe igbelarugẹ aṣa ati iṣe Yoruba lo jẹ koun fi iṣẹ agbẹjọro silẹ fun ere ori itage.

Bolanle sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC Yoruba wi pe lati kekere loun ti fẹran lati maa kọ itan.

O ni awọn nnkan yii lo jẹ koun nifẹẹ si ere ori itage.

Bolanle ni ''ọmọbibi ipinlẹ Ekiti ni baba mi, amọ, ilu Eko ati Ibadan ni mo dagba si.

Ẹkọ amofin ni mo kọ nile ẹkọ giga fasiti.

Nigba ti mo ri i pe ko si ibi tawọn eeyan ti le kọ nipa aṣa, ounjẹ, ijo ati orin wa ni mo da ''Terra Kulture'' silẹ.''

Gbajugbaja olootu ere naa ni oun rii pe awọn eeyan fẹ ko nipa aṣa ati iṣe Yoruba lati igba ti oun ti bẹrẹ ere ori itage.

''Ọpọ lo fẹ lati wa wo ere wa, igba yẹn ni mo wa ri pe iṣẹ ti a n ṣe yii ṣe pataki gan an.''

Bolanle ti ṣe oriṣiiriṣii ere, amọ, o ni ''Moremi'' jẹ ere to ṣe pataki soun tori o sọ nipa agbara obinrin.

''Mo lo aṣọ wa, mo lo aṣa wa lati sọ itan Moremi, awọn eeyan si gbadun itan naa.

Emi naa gbadun ere ọhun tori mi o mawọn itan yii tẹlẹ, iyẹn lo fi n dun mi pe a ko maa gbe aṣa wa larugẹ daadaa,'' Bolanle lo sọ bẹẹ.

Oludari ere naa sọ pe inu oun dun pe nnkan ti oun n ṣe yoo wulo fawọn ọmọ oun atawọn ''ọmọ wa to n bọ lọjọ iwaju.

Idi ni pe ta ni wa ti gbogbo wa ba gbagbe aṣa, iṣe, ẹkọ ati ede wa?

Inu mi dun pe mo jẹ awokọṣe fun awọn to n bọ lẹyin,'' Bolanle lo sọ bẹẹ.