Akẹ́kọ̀ọ́ 50 sá wálé lákàtà ajínigbé nínú àwọn 315 tí wọ́n jí gbé nípìnlẹ̀ Niger

Aworan ajuwe ile ẹkọ ti ajinigbe ti ṣọṣẹ naa

Oríṣun àwòrán, BBC VIA ZAHRADDEN

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Agbébọn tó gbé ìbọn dání ní apá òsì pẹ̀lú pátákó àkọ́lé ilé ẹ̀kọ́ St Mary's Catholic ní ọ̀tún

Oríṣun àwòrán, Getty/Images/BBC

Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorilẹede Naijiria (CAN), ti fidi ẹ mulẹ pe aadọta akẹkọọ (50) ninu awọn ti wọn ji gbe nile ẹkọ St. Mary Catholic School, Papiri, to wa nipinlẹ Niger ti jajabọ lakata awọn ajinigbe.

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ CAN fi sita lọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni wọn ti fidi ikoyọ naa mulẹ.

Atẹjade ti Alaga CAN, Ẹniọwọ Bulus Dauwa Yohanna to tun jẹ oludasilẹ ile ẹkọ naa fi sita, ṣalaye pe laaarin ọjọ Ẹti si Satide ni awọn ọmọ naa ri ọna abayọ ti wọn fi sa wale.

Wọn fi kun un pe wọn si ti wa pẹlu awọn obi wọn.

"Eyi ni lati fi to gbogbo ilu leti, pe nigba ti yoo fi di Satide ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025, a ti ri awọn iroyin ayọ kan gba, bi aadọta akẹkọọ ṣe jajabọ ti wọn si ti wa pẹlu awọn obi wọn.

"A fidi eyi mulẹ nigba ti a pinnu lati ṣabẹwo si awọn obi awọn ọmọ naa"

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

Àwọn tó ṣì wà lákàtà ajínigbé

Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe tẹsiwaju, awọn akẹkọọ to ṣẹku si akata ajinigbe naa lọ bayii:

"Fun akọsilẹ, a ni akẹkọọ alakọọbẹrẹ 251, ti girama mẹrinla (14) ati awọn olukọ mejila (12) lọdọ awọn ajinigbe bayii."

Alaga CAN naa rọ awọn eeyan lati ṣe suuru, ki wọn si kun fun adura si i.

O ni ajọṣepọ n tẹsiwaju laaarin ijọba ati awọn ẹṣọ alaabo, lori bi awọn akẹkọọ to ṣẹku sigbekun naa yoo ṣe gba ominira.

"Bi a ṣe ri aadọta akẹkọọ ti wọn raye sa yii tu wa lara diẹ, mo rọ gbogbo yin lati tẹsiwaju ninu adura yin fun ipada de pẹlu alaafia awọn to ṣẹku nigbekun.

Biṣọọbu Yohanna lo ṣe afikun bẹẹ.

Tẹ o ba gbagbe, oruganjọ ni awọn ajinigbe yawọ ile ẹkọ naa lọsẹ to kọja, ti wọn si ko awọn akẹkọọ ati awọn olukọ wọgbo lọ.

A ò tíì gbọ́ ohunkóhun látọ̀dọ̀ àwọn ajínigbé tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 315 gbé ní ilé ẹ̀kọ́ St Mary's - CAN

Ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi ní Nàìjíríà, Christian Association of Nigeria (CAN) tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Niger ti jiyàn ìròyìn kan tó gbòde wí pé àwọn agbébọn tó jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ 315 gbé ní ilé ẹ̀kọ́ St. Mary's Catholic Primary and Secondary Schools, Papiri, ìpínlẹ̀ Niger ń bèèrè fún bílíọ̀nù mẹ́ta náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtúsílẹ̀.

Alága CAN ìpínlẹ̀ Niger, Ẹni ọ̀wọ̀ Bulus Dauwa Yohanna ló fi ìròyìn náà léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Yohanna ní àwọn agbébọn náà kò ì tíì kan sí ẹnikẹ́ni lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ tí wọ́n jí gbé náà.

Ó ní lóòótọ́ ni onírúurú ìròyìn ti gbilẹ̀ lórí ayélujára èyí ló sì ṣokùnfà tí àwọn fi ń gbé àtẹ̀jáde síta lóòrèkóòrè.

Bákan náà ló fi kun pé iye èèyàn tí àwọn agbébọn náà jí gbé nílé ẹ̀kọ́ ọ̀hún jẹ́ 315 – àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 303, àwọn olùkọ́ 12 – lòdì sí iye èèyàn 227 tí wọ́n ti kọ́kọ́ kéde pé àwọn agbébọn náà gbé.

Bíṣọ́ọ̀bù náà sọ pé lẹ́yìn tí àwọn kúrò ní Papiri, tí àwọn bẹ̀rẹ̀ sí ní kàn sáwọn èèyàn ni àwọn ri pé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn rò wí pé wọ́n móríbọ́ ló jẹ́ pé wọ́n wà ní àkàtà àwọn ajínigbé náà.

Ó ní àwọn ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjìléláàádọ́rùn-ún (88) míì ṣì wà ní àkàtà àwọn ajínigbé náà.

Lórí ọ̀rọ̀ pé ìjọba ti ṣèkìlọ̀ fáwọn ilé ẹ̀kọ́ lórí ìkọlù àwọn agbébọn náà, Yohanna ní àwọn kò gba ìwé ìkìlọ̀ kankan yálà láti ọ̀dọ̀ ìjọba tàbí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò.

"Ìjọba mọ̀ọ́mọ̀ sọ èyí ni láti fi gbé ẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ru àwọn ẹlòmíràn dípò kí wọ́n gba ẹ̀bi wọn."

Akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ 227 láwọn ajínigbé gbé lọ ní ilé ẹ̀kọ́ St Mary - CAN

Àkọ́lé ilé ẹ̀kọ́ St Mary Catholic Church

Oríṣun àwòrán, ABDULLAHI KABIR/BBC

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alága ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristẹni, Christian Association of Nigeria, CAN tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Niger, Ẹni ọ̀wọ̀ Bulus Dauwa Yohanna ti sọ pé èèyàn 227, tó fi mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ láwọn ajínigbé tó ṣe ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ St Mary Catholic Schools, Papiri ní ìjọba ìbílẹ̀ Agwara ní ìpínlẹ̀ náà ni wọ́n jí gbé lọ.

Ẹni ọ̀wọ̀ Yohanna nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀ Daniel Atori fi léde sọ pé òun ṣe àbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ náà níbi tí òun ti ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ó ní òun ṣe àrídájú rẹ̀ fáwọn òbí àwọn ọmọ náà pé àwọn ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti ṣe àwárí àwọn ọmọ náà àti láti láti gbà wọ́n sílẹ̀ láyọ̀ àti àlááfíà.

"Nínú àkọ́sílẹ̀ tí a rí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 215 àtàwọn olùkọ́ 12 láwọn ajínigbé náà jí gbé lọ."

Ó fi kun pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan móríbọ́ lásìkò ìkọlù ọ̀hún, tí àwọn òbí sì ti ń lọ mú àwọn ọmọ wọn nítorí wọ́n máa ti ilé ẹ̀kọ́ náà pa fún ìgbà kan ná.

Bákan náà ló rọ àwọn èèyàn láti ṣe sùúrù, kí wọ́n sì máa gbàdúrà fún ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láìpẹ́ ọjọ́.

Àwọn agbébọn tún ti jí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ St Mary's Catholic School ní ìpínlẹ̀ Niger gbé lọ

Ọkunrin gbe ibọn dani, o si wọ aṣọ olomi aro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣaaju ni a ti mu iroyin wa pe awọn janduku agbebọn tun ti ji awọn akẹkọọ atawọn osiṣẹ ile ẹkọ St Mary's Catholic school ni Papiri, nijọba ibilẹ Agwara ni ipinlẹ Niger gbe lọ.

Ijọba ipinlẹ Niger ti ṣapejuwe iṣẹlẹ naa bi eyi to bani lọkan jẹ.

Ijọba ni oun ti gba iroyin bonkẹlẹ ṣaaju wi pe o ṣee ṣe ki iṣẹlẹ aburu waye lẹkun ariwa ipinlẹ Niger nibi ti iṣẹlẹ ijinigbe yii ti waye.

Awọn alaṣẹ ipinlẹ naa tun sọ pe ijọba ti paṣẹ ṣaaju wi pe ki gbogbo ile ẹkọ onileegbe ni ipinlẹ naa wa ni titi pa nitori eto aabo to mẹhẹ.

Ṣugbọn a ko le fidi rẹ mulẹ bo ya ile ẹkọ St Mary's pa aṣẹ ijọba yii mọ ki iṣẹlẹ yii to waye.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin lẹyin tawọn janduku agbebọn ji awọn akẹkọọ gbe nipinlẹ Kebbi ati awọn olujọsin ninu ijọ CAC niluu Eruku nipinlẹ Kwara.