Ọlọ́pàá Kwara bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú obìnrin tí wọ́n fún lọ́rùn pa nílé ìtura kan ní Ilorin

Adekimi Ojo, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Kwara ninu aṣọ iṣẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, State State Police Command

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àwọn afurasí apànìyàn fún òṣìṣẹ́ bìnrin òtẹ́ẹ̀lì kan lọ́rùn pa ni Kwara

Arabinrin kan to jẹ osisẹ ile idana nile itura kan niluu Ilorin ti jade laye.

Eyii ko ṣẹyin bi awọn kọlọrọsi kan ṣe fun obinrin naa lọrun pa.

Arabinrin naa ti orukẹ rẹ n jẹ Yemi ni a gbọ pe wọn pa ni nnkan bii ago mejila oru lọjọ Abamẹta.

Idi ti awọn apaniyan naa fi paa si ṣokunkun si awọn eniyan titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ.

BBC Yoruba ri gbọ pe, aṣọ ni awọn ọdaran naa fi fun oloogbe ọhun lọrun pa.

Aṣọ ni wọn fi fun lọrun pa - Oṣojumi-koro

Awọn kan ti wọn ni ka fi orukọ bo awọn lasiri sọ pe "a gbọ ohun rẹ ti o pariwo ole, ole, lẹyin naa ni wọn fi aṣọ fun-un lọrun pa.

Ọrọ yii ti fa ariyanjiyan bayii laarin awọn eniyan.

Awọn kan sọ pe niṣe ni wọn gbe iṣẹ ẹmi oloogbe naa fun awọn apaniyan ọhun lati pa arabinrin naa nigba ti awọn kan ni ko ri bẹẹ.

Awọn mii sọ pe rara o, "ẹni to ni otẹẹli naa ni wọn wa wa ni pato, sugbọn wọn o ba a."

Wayi o, iṣẹlẹ naa ti da ibẹrubojo silẹ ni ile itura naa nigbati awọn onibara wọn to wa nibẹ tib a ẹsẹ wọn sọrọ.

Agbegbe Baba Ode ni ilu Ilorin ni ile itura ti iṣẹlẹ naa ti waye wa.

Kí ni ọlọ́pàá Kwara sọ?

Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ ọlọpaa ni Kwara, Ejire Adetoun Adeyemi, o fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

O ni iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Adetoun sọ pe nigba ti awọn agbofinro de ile itura naa, wọn ri oku obinrin ọhun, wọn tun ri aṣọ funfun ti wọn fura si pe oun ni wọn fi fin ọrun rẹ.

O ni iṣẹ ti n lọ lọwọ lati ṣawari awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa ki wọn le foju wina ofin.

O pari ọrọ rẹ pe ileeṣẹ naa yoo fi to araalu leti bi iwadii iṣẹlẹ ọhun ba ṣe n lọ.