Inú ìbànújẹ́ ni èmi àti ìyàwó mi wà látìgbà tí wọ́n ti jí ọmọ wa lọ- Bàbá ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Kebbi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Inú ìbànújẹ́ ni èmi àti ìyàwó mi wà látìgbà tí wọ́n ti jí ọmọ wa lọ- Bàbá ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Kebbi

Baba jokoo loun nikan, o n wo orere

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Baba jokoo loun nikan

Ibanujẹ ọkan ati ipayinkeke lo ti ba awọn obi ti awọn agbebọn ji ọmọbinrin wọn ko wọgbo lọ lọjọ Aje ọsẹ yii, nile ẹkọ GGCSS, Maga, ipinlẹ Kebbi.

Ọkan lara awọn obi awọn ọmo naa to BBC ba sọrọ lori iṣẹlẹ yii, ẹni ti a ko fẹ lati darukọ rẹ nitori aabo, ṣalaye pe lẹyin ti oun kirun owurọ tan ni iroyin aburu naa de.

"Inu mọṣalaṣi la wa ta a fi gba ipe kan lati ọdọ imaamu wa. O sọ fun wa pe awọn agbebọn ti ji awọn akẹkọọ gbe lọ nile ẹkọ naa.

"Ọdun to koja ni mo mu awọn ọmọbinrin mi meji lọ sile ẹkọ naa lati maa kawe nibẹ.

"Ọmọ mi keji sọ fun mi pe awọn n sun lọwọ ni lasiko ti awọn agbebọn naa de.

" O ni oun atawọn ẹgbẹ oun kan sare wọ ile igbọnsẹ lọ lati sa sibẹ, awọn kan si sa si abẹ ibusun."

Awọn agbebọn naa bẹrẹ si i dunkooko lati yinbọn mọ wọn bi wọn ko ba jade nibi ti wọn sa si gẹgẹ bo ṣe wi.

Nigba ti ọmọkunrin kan si ṣilẹkun ile igbọnsẹ naa ni wọn ko wọn lọ.

"Latigba ti wọn ti gbe ọmọ mi lọ ni emi ati iya rẹ ti wa ninu ibanujẹ, ọmọ naa ni akọbi mi lobinrin. Mi o mọ ipo to wa bayii lakata ajinigbe."

Baba sọ pe oun ati awọn ẹbi oun ko foju kan oorun lati ọjọ Aje ti wahala naa ti bẹ silẹ.

Igbákejì Ààrẹ, Kashim Shettima, ṣàbẹ̀wò sí Kebbi

Ni ibanikẹdun iṣẹlẹ yii, Aarẹ Bola Tinubu ti ran Igbakeji rẹ, Kashim Shettima, lati ṣabẹwo si ipinlẹ Kebbi, nibi ti wọn ti ji akẹkọọbinrin mẹẹẹdọgbọn lọ lọjọ Aje ọsẹ yii.

Oni Ọjọru, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni Shettima rin irin ajo lọ si Kebbi, lati ba ẹbi awọn ọmọ naa kẹdun.

Ẹ o ranti pe ṣaaju ni ijọba ti ni igbesẹ ti bẹrẹ nipa bi wọn yoo ṣe ri awọn ọmọbinrin to wa nigbekun ajinigbe naa gba pada.

Irinajo Igbakeji Aarẹ naa si tun jẹ ọna kan lati mu awọn eeyan ti ọrọ naa kan lọkan le.

Akẹ́kọ̀ọ́ méjì sá kúrò lóko ajínigbé tó kó 25 nínú wọn wọgbó lọ nílé ẹ̀kọ́ girama ní Kebbi

Aworan orukọ ile ẹkọ naa ati awọn ibusun to ṣofo lẹyin ikọlu ati ijinigbe, awọn apamọwọ kan naa wa nilẹẹlẹ pẹlu.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Aworan orukọ ile ẹkọ naa ati awọn ibusun to ṣofo lẹyin ikọlu ati ijinigbe

Meji ninu awọn akẹkọọbinrin ile ẹkọ girama Government Girls Comprehensive Secondary School, (GGCSS) Maga, nipinlẹ Kebbi, tawọn ajinigbe ji gbe lanaa ọjọ Aje ti sa kuro ni àkàtà awọn ajinigbe naa bayii.

Ẹnikan to sun mọ ile ẹkọ naa lo fidi eyi mulẹ fun BBC.

Bẹẹ la gbọ pe mẹẹẹdọgbọn (25) ni apapọ awọn ọmọbinrin ti awọn agbebọn naa ji gbe.

O ṣoju mi koro to ni ka fi orukọ bo oun laṣiri naa sọ pe ọna ti awọn ọmọbinrin meji yii fi bọ lọwọ ajinigbe ko ye oun.

O ni ṣugbọn oun ti foju kan wọn laaarọ oni ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun.

Bi awọn ọmọbinrin meji ṣe pada yii, mẹtalelogun (23) lo ṣi wa lakata awọn to mu wọn sigbekun.

Ijọba apapọ Naijiria ni igbesẹ ti bẹrẹ ni pẹrẹwu nipa bi wọn yoo ṣe ri awọn to ṣẹku sigbekun naa gba pada.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?

Abawọle ile ẹkọ naa pẹlu awọn ọmọdekunrin kan to duro niwaju ibẹ

Oríṣun àwòrán, Mustapha Ibrahim

Àkọlé àwòrán, Abawọle ile ẹkọ naa

Inu ibanujẹ ni awọn eeyan Maga ji si laaarọ ọjọ Aje ana, iro ibọn lakọlakọ lo ji wọn.

Malam Abdullahi, ọkan lara awọn araalu naa, ṣalaye fun BBC pe:

"Ọwọ idaji ni rogbodiyan naa bẹrẹ, a n palẹmọ lati ki irun aarọ ni.

"Ni nnkan bii aago mẹta aabọ aarọ la kọkọ bẹrẹ si i gburo ibọn yinyin, ṣugbọn a ro pe awọn fijilante adugbo lo n wọ́de ni.

"Nigba to ya la bẹrẹ si i gbọ iro iboyin yẹn to rinlẹ gan-an, ni nnkan bii aago mẹrin aabọ idaji. Nigba ti mo si yọju sita, mo ri i ti awọn eeyan n sare kuro nile ẹkọ ti awọn agbebọn ti pitu naa."

Bakan naa ni awọn o ṣoju mi koro kan sọ pe awọn agbebọn naa n yinbọn lakọlakọ ni, eeyan meji lo si pada padanu ẹmi wọn nibi ikọlu ọhun.

Ṣaaju ki wọn too wọ ile ẹkọ naa ni a gbọ pe wọn ti kọkọ kọlu awọn abule to wa nitosi Maga, ti wọn si ji awọn eeyan gbe lọ.

"Wọ́n ti kọ́kọ́ wọlé pa ọkọ mi kí wọ́n tóó wọ ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọbínrin"

Obinrin kan to padanu ọkọ rẹ sinu ikọlu yii ṣalaye pe nnkan bii aago mẹta oru ni awọn agbebọn wọ ile awọn.

O ni iro ẹsẹ girigiri ni awọn kọkọ n gbọ nibi oju ferese awọn, kawọn si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn agbebọn ti ya wọle .

"Ni nnkan bii aago mẹta oru, mo gburo ẹsẹ nibi ẹyin ferese wa. Mo gbiyanju lati ji ọkọ mi, mo fẹ sọ fun un pe boya awọn ẹranko ni wọn n da nnkan ru nita.

"Ṣugbọn ka too mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn ọkunrin to dihamọra ogun ti wọle .

"A bẹrẹ si i ba ara wa fa a, ọkan ninu wọn si fa ibọn yọ, o yin in mọ ọkọ mi.

"Ọkan ninu wọn fa ọwọ mi, o wọ mi jade. Mo ni ko fi mi silẹ, pe mi o ni i tẹle wọn lọ nigba ti wọn ti pa baba awọn ọmọ mi."

Obinrin naa sọ pe ẹnu eyi ni awon wa ti ọmọ oun obinrin fi jade sita, nigba naa ni wọn si fi oun silẹ, ti wọn gbe ọmọ oun.

"Wọn gbe ọmọ mi obinrin lọ, wọn ni ko mu awọn lọ si ile ti awọn akẹkọọ n gbe."

Bẹẹ ni iya naa ṣalaye.

Àwọn agbébọn yawọ ilé ẹ̀kọ́ ní Kebbi, jí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin gbé lọ, ṣekúpa èèyàn méjì

Aworan ile ẹkọ Govt Girls Comprehensive Sec. Sch ni Kebbi

Oríṣun àwòrán, Mustapha Ibrahim/BBC

Awọn agbebọn ti kọlu ile ẹkọ awọn obinrin ni apa ariwa ipinlẹ Kebbi, ti wọn si tun ṣekupa oṣiṣẹ ile ẹkọ meji.

Lọwọ yii a ko le sọ iye awọn akẹkọọbinrin ti awọn agbebọn gbe lọ.

Awọn oṣojumikoro ni awọn agbebọn yawọ ile ẹkọ Government Girls Comprehensive Secondary School niluu Maga, ni ijọba ibilẹ Danko Wasagu ni ooru ọgajọ.

Oṣojumikoro ni ọpọ awọn agbebọn ọhun lo yawọ ile ẹkọ, ti wọn si yinbọn ni kikankikan.

Lasiko ikọlu yii, oṣiṣẹ kan ni ile ẹkọ ni wọn yibọn lu lasiko to n gbiyanju lati da bobo awọn akẹkọọ.

Ọdẹ kan to n sọ ile ẹkọ naa fara gba ọta ibọn lasiko ikọlu naa.

Olugbe agbegbe kan sọ fun BBC pe ọpọ awọn akẹkọọ obinrin ni awọn agbebọn yii ko wọ inu igbo.

Iye awọn akẹkọọ ti awọn agbebọn yii jigbe ni a ko ti le fidi rẹ mulẹ, ti awọn obi awọn akẹkọọ si ti bẹrẹ si ni ma ṣe akọjọpọ orukọ awọn akẹkọọ.

Alaga ijọba ibilẹ Danko/Wasagu, Hussaini Bena ni awọn ẹsọ alabo ti gbera tẹle awọn agbebọn ti wọn mo ri ile igbo kan to wa agbegbe kan to wa laarin ipinlẹ Kebbi ati Zamfara.

Awọn idilẹ niluu Maga ti n rọ ijọba lati ṣawari awọn ọmọ wọn.

Ki ni iṣẹlẹ ọlọpaa sọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kebbi ti kede pe awọn ti da ọlọpaa si ilu, pẹlu awọn soja ati fijilante lati bẹrẹ si ni ma wa awọn ọdọmọbinrin akẹkọọ ti awọn agbebọn ji ni ile ẹkọ Govt Girls Comprehensive Secondary School niluu Maga, ni ijọba ibilẹ Danko/Wasagu.

Nafiu Abubakar Kotarkoshi, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kebbi sọ pe ago mẹrin aarọ ọjọ Aje ni awọn agbebọn naa yawọ ile ẹkọ naa, ti wọn si bẹrẹ si ni sina bọlẹ.

Awọn ọlọpaa to wa ni ayika ile ẹkọ naa gbe ija koju awọn agbebọn ṣugbọn ọpọ wọn fo ferese, ti wọn si mu awọn ọdọmọbirin naa dani lọ sibi ti ẹnikẹni ko mọ.

Gẹgẹ bii ọlọpaa kan ṣe sọ, Hassan Makuku, padanu ẹmi rẹ lasiko ikọlu naa, ti ọkunrin mii, Ali Shehu, si farapa nibi ori rẹ.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti da ọpọ ọlọpaa sita lati darapọ mọ awọn ologun ati fijilante lati le ṣawari awọn akẹkọọ naa.

Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kebbi, Bello Sani, wa ti fi da araalu loju pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ri daju pe o tun bọ tẹsiwaju ninu didabo ẹmi ati dukia araalu.

Ki lo ti sẹlẹ ṣaaju?

Ko ki n ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ iṣẹlẹ yoo waye ni apa ariwa orilẹede Naijiria, ti awọn agbebọn yoo ji awọn akẹkọọ gbe.

Lọdun 2020, ọpọ iṣẹlẹ yii waye, ti awọn agbebọn si n bẹrẹ ọpọ owo lẹyin ti wọn ji awọn akẹkọọ gbe.

Pẹlu bii ọpọ awọn ologun ati awọn ẹsọ alabo se wa ni agbegbe naa, awọn agbebọn si n kọlu awọn agbegbe ni apa ariwa orilẹede Naijiria.