PDP yọ Makinde, Bode George àtàwọn míì kúrò nínú ẹgbẹ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Rogbodiyan inu ẹgbẹ oṣelu PDP ti tunbọ fẹ loju si lẹyin rogbodiyan to waye nibi ipade igun ẹgbẹ naa to n ṣatilẹyhin minisita fun FCT, Nyesom Wike, niluu Abuja.
Nibi ipade igun ẹgbẹ naa to waye niluu Abuja ni wọn ti yọ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Awọn mii ti wọn tun yọ bii jiga yatọ si Makinde ni gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed; gomina ipinlẹ Zamfara, Dauda Lawal; ati igbakeji adari ẹgbẹ naa tẹlẹ ni guusu Naijiria, oloye Bode George.
Awọn mii ti wọn tun gbọn yọ ni alaga igbimọ tẹẹkoto ẹgbẹ naa tẹlẹ, Adolphus Wabara, alaga ti wọn ṣẹṣẹ burawọle fun, Tanimu Turaki (SAN), igbakeji alaga ẹgbẹ ọhun tuntun ni guusu Naijiria, Taofeek Arapaja atawọn mii.
Wọn tun kede ituka igbimọ ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Bauchi, Oyo, Zamfara, Yobe, Lagos, Edo, ati Ekiti.
Lẹyin naa ni wọn kede agbekalẹ igbimọ fidihẹ fun naa ẹgbẹ ti wọn si tun kede pe ipade gbogbogbo mii yoo waye laipẹ.
Ko tan sibẹ, igun ẹgbẹ naa tun paṣẹ fun ẹka to n ri si ọrọ ofin ninu ẹgbẹ naa lati bẹrẹ igbẹjọ ti yoo gba awọn aga awọn ti wọn dibo yan sipo ninu ẹgbẹ ọhun amọ ti wọn kuro lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mii.
Wọn ni eyii wa ni ibamu pẹlu abala 68(1)(g) ati 109(1)(g) ofin orilẹede Naijiria ti wọn kọ lọdun 1999.
Igbesẹ igun ẹgbẹ yii lo n waye lẹyin ipade gbogbogbo ẹgbẹ naa to kọkọ waye niluu Ibadan ti ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa kan kọ lati yọju si.
Lara awọn gomina ti ko yọju sibe ni gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke.
Papa iṣere Lekan Salami to wa ni Adamasingba niluu Ibadan ni ipade ọhun ti waye, ibẹ si ni wọn ti fi ọwọ osi juwe ile fun Ayodele Fayose, Nyesom Wike atawọn mii ninu ẹgbe ọhun.
Wọn ni igbesẹ wọn ko ṣẹyin awọn ohun tawọn eeyan naa n ṣe to lodi si ilọsiwaju ẹgbẹ.
Lẹyin ipade naa lọjọ Abamẹta to kọja ni igun ẹgbẹ naa ti Wike ko sọdi gbe igbesẹ ti wọn l'Abuja lati yọ Makinde atawọn mii bii jiga ninu ẹgbẹ.















