Àwọn ọ̀dọ́ ìlú Eruku fẹ̀hónú hàn, nítorí ìpànìyàn tó wáyé ní ṣọ́ọ̀ṣì CAC ní Kwara

Oríṣun àwòrán, @CAC, Eruku
Latari ipaniyan ati ijinigbe to waye ni ṣọọṣi CAC Oke Iṣẹgun lọjọ Iṣẹgun ana, eyi to wa ni Eruku, ijọba ibilẹ Ekiti nipinle Kwara, awọn ọdọ ilu naa fi ẹhonu wọn han l'Ọjọru, oni.
Awọn ọdọ ilu naa gbe igi dina ni nkan bii aago mẹwaa owurọ oni lati fẹhonu wọn han.
Lasiko to n ba aṣojukọroyin BBC News Yorùbá sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, ọkan lara awon ọdọ ilu naa, Segun, sọ pe inu awọn awọn ko dun rara.
Segun salaye pe lati bii ọsẹ mẹta sẹyin ni awọn ti n gbọ finrin finrin, pe wọn fẹ kọlu ilu naa.
O ni awọn si fi to awọn alaṣẹ leti sugbọn ko si igbesẹ kankan lori ẹ.
O salaye pe agọ ọlọpaa ilu naa ni awọn eeyan ilu Eruku n sa lọ bayii, latari ibẹru bojo awọn agbesunmọmi.
Ninu ọrọ tiẹ, ọdọ miran to pe ara re ni Ajayi, salaye pe ikọlu awọn agbesunmọmi si ilu naa kọni lominu pupọ.
Bakan naa ni Ọgbẹni Afọlabi toun naa ba BBC Yorùbá sọrọ ní ko si lilọ bibọ ọkọ mọ ni ilu Eruku. O fikun pe awọn ọdọ ti ko igi dina ni ilu naa .
Pẹlu alaye pe, awọn ọmọ ogun lati ipinlẹ Ekiti ati lati ipinlẹ Kogi ti de si ilu naa bayii.
O fidi ẹ mulẹ pe, nnkan bii ọgbọn awọn ọmọ ijọ CAC naa wọn jigbe tawon o ti ri wọn bayii.
Afolabi sọ pe ẹnikan n gba itọju lọwọ ni ile iwosan lara awọn to farapa, wọn si ti sin oku awọn tó kú nibi iṣẹlẹ naa.
O ni awọn ti ri ẹnikan ninu awọn ti wọn ji gbe naa laarọ oni. O kan sara sawọn fijilante bi wọn se koju ija si awọn agbebọnja naa.
Kọmiṣanna ọlọpaa Kwara gunlẹ si Eruku

Oríṣun àwòrán, Kwara Police
Ẹwẹ kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Adekimi Ojo, ṣe abẹwo si ilu Eruku lati wo bi nnkan se ri .
Adekimi sabẹwo sọdọ Kabiesi Ọwa ti ilu Eruku, bẹẹ lo ba awọn ilu sọrọ. O rọ araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu ọlọpaa.
Kọmiṣanna ni bawo lawọn agbebọnja se gbọ pe ẹni ti wọn ji gbe, to ṣẹṣẹ de, tun n ṣe idupẹ ni ile ijọsin bi ko ba lọwọ ara ile ninu.
Lẹyin eyi lo jẹjẹ ifarajin ajọ ọlọpaa fun ipinlẹ Kwara.
Ninu ọrọ agbẹnusọ Gomina ipinlẹ Kwara ,Mallam Rafiu Ajakaye , o ni Gomina Abdulrahman Abdulrazak ba ilu Eruku kẹdun, pẹlu mọlebi awọn to doloogbe.
Gomina pe fun afikun awọn ọmọ ogun latọdọ ijọba apapọ, lati mu ki eto aabo gbopọn si i.
Bakan naa lo pe fun ki ìjọba àpapọ tete fi awọn ọmọ ogun sọwọ si ijọba ibilẹ Ekiti, ipinlẹ Kwara.
Àwọn agbébọn kọlu ṣọ́ọ̀ṣì C.A.C. ni Kwara, wọ́n sekúpa èèyàn méjì, jí ọ̀pọ̀ gbé lọ

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Awọn agbebọn tun ṣoro lanaa ojo Iṣẹgun ọjọ kejidinlogun oṣu Kọkanla yii niluu Eruku nijọba ibilẹ Ekiti ni ipinlẹ Kwara.
Ni nnkan bIi ago mẹfa irọlẹ ana lawọn agbebọn naa ya wọ ile ijọsin CAC ilu Eruku nibi ti wọn ti ṣeku eeyan meji ti si ji awọn mii gbe lọ.
Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa soju rẹ to ba aṣoju kọroyin wa BBC Yorùbá sọrọ, Ọgbẹni Sunkanmi sọ pe lasiko ti isin n lọ lọwọ ni iṣẹlẹ naa waye.
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ni eeyan meji lawọn agbebọn ọhun ṣekupa, oṣoju-mikoro to ba BBC Yoruba sọ pe eeyan mẹrin ni wọn pa nibi iṣẹlẹ naa, awọn olùjọsìn mẹta ni wọn pa sinu sọọṣi.
O salaye wi pe pe awọn ko ti mọ iye awọn eeyan ti wọn jigbe lọ bayii.
Ọgbẹni Sunkanmi ni lati bii ọsẹ mẹta sẹyin ni wọn ti n kọlu ilu Eruku ti awọn ti n fi to ìjọba leti.
O ni awọn o ri alaga ijọba ibilẹ naa lati bi ọsẹ mẹta sẹyin ti awọn ti n fi iṣẹlẹ naa to o leti pe awọn gbọ pe awọn agbebọn fẹ kọlu ilu Eruku.
Ọgbẹni Sunkanmi ni titi di asiko yii, awọn o tii ri awọn ẹṣọ eleto abo yatọ si awọn to ti wa ni ilu naa tẹlẹ.
Ọgbẹni Sunkanmi ni awọn ọdẹ ati fijilante ti wọ inu igbo lọ lati wa awọn ti wọn ji gbe.
O parọwa si ijọba ipinle Kwara ati alaga ijọba ibilẹ Ekiti lati ran ilu naa lọwọ nitori ilu naa bọ si ala ipinlẹ Kwara ati ipinle Kogi.
Ọkan lara awọn ọm bibi ilu Eruku to jẹ gbajumọ Olorin Toyin dollar sọ pe ilu Omu-Aran ni oun wa lanaa lasiko ti iṣẹlẹ ọhun waye.















