"Àlàyé rèé lórí bí ọmọ mi, ọmọ ọdún mẹ́fà ṣe bọ́ lọ́wọ́ ajínigbé ní Papiri àmọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ méjì sì wà lọ́dọ̀ agbébọn"

Baba ọmọ kan to wa lara awọn ọmọ ti wọn ji gbe nileẹkọ St Mary Catholic nilu Papiri nipinlẹ Niger, ti ba BBC sọrọ.
Baba naa, ti a paarọ orukọ rẹ si Lucas, tori a fẹ fi orukọ bo o ni asiri salaye nipa bi ọmọ naa se bọ ni ahamọ awọn ajinigbe.
Nigba to n ba BBC sọrọ, baba ọmọ ọdun mẹfa naa, sọ bi ọmọ rẹ se bọ ni akata awọn ajinigbe naa ati bi awọn mejeeji se pada ri ara wọn.
"Nigba ti mo ri ọmọ mi, inu mi dun pupọ.
"Mo pe e ni orukọ abisọ rẹ, o boju wẹyin, o si sare wa ba mi, Mo di mọ ọ, mo si fa a mọra."
Lucas salaye pe ọmọ oun sọ fun oun pe awọn akẹkọọ n sun ninu ilegbe wọn nile ẹkọ St Mary's Catholic nigba ti wọn gbọ̀ọ iro awọn ajinigbe naa.
Awọn ajinigbe naa fọ ferese ilegbe ọhun, ti gbogbo gilaasi si da silẹ, bẹẹ ni wọn fi tipa mu ki awọn akẹkọọ naa silẹkun yara ilegbe wọn loju ibọn, bẹẹ ni awọn ọmọ naa si n toogbe.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn ọmọ kan fo ogiri ile ẹkọ naa ti wọn to irin yika rẹ lati sa lọ amọ Lucas ni ọmọ oun si kere pupọ lati fo ogiri, sugbọn o sa pamọ.
Bi o tilẹ jẹ pe Lucas ti ri ọmọ rẹ kekere pada amọ awọn ko ti ri awọn ọmọ rẹ meji mii ti wọn ti dagba.

Ìjọba kede pe wọn doola aadọta akẹkọọ amọ ko si ọkankan obi to n wa ọmọ wọn lati akoko ijinigbe, ti wọn tii ri awọn ọmọ wọn
Bi ẹ ko ba gbagbe, awọn akẹkọ to to mẹtalelọọdunrun ati olukọ mejila ni awọn agbebọn ji gbe nilu Papiri.
Amọ awọn alasẹ ijọba ti kede pe mọkanlelaadọta ninu awọn ọmọ naa lo ti pada sile.
Gẹgẹ awọn se salaye fun BBC, kii se pe awọn akẹkọọ bii aadọta yii sa ni akata ajinigbe ni amọ eyi ni apapọ iye awọn akẹkọọ to sa lọ lasiko ti isẹlẹ ijinigbe naa n waye titi di irọlẹ ọjọ Aiku.
Iye awọn akẹkọ naa si lo fara han lẹyin eto ayẹwo ti ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi (CAN) gbe sita.
"A se awari yii pe awọn akẹkọ bii aadọta maa wa pẹlu awọn obi wọn nigba ti a kan sawọn obi kan, ti a si se abẹwo si wọn."
Akọroyin BBC salaye pe ko si ọkankan obi to n wa ọmọ wọn lati akoko ijinigbe naa, to ba sọrọ, ti wọn tii ri awọn ọmọ wọn laarin ọjọ Aiku si ọjọ Aje.
Ikede ijọba pe wọn ti ri mọkanlelaadọta gba silẹ lọwọ ajinigbe ti da iporuru ọkan silẹ laarin awọn obi.
Ọpọ awọn obi yii si lo pa agọ si ẹnu ọna ileẹkọ naa, nibi ti ajinigbe ti gbe wọn lọmọ lọ, ti inu wọn si bajẹ, bẹẹ ni inu n bi wọn pe ki lo de ti wọn ko kọkọ fi iroyin naa to awọn leti na.
"Ki lo de to jẹ pe ori ayelujara la ti kọkọ n ri iroyin pe awọn akẹkọọ bii aadọta ti gba itusilẹ,, ti ijọba ko si kọọkan kan siwa taara, titi di akoko yii, a ko tii foju se mẹrin awọn ọmọ wa.

Gbogbo awọn ileẹkọ to wa ni agbegbe Papiri ni wọn ti ti pa lati ọdun mẹrin sẹyin, iyalẹnu lo jẹ fun mi pe ile ẹkọ naa si n ba isẹ lọ - Gomina Niger
Lasiko to n bawọn akọroyin labẹle fọrọjomitoro ọrọ, Gomina ipinlẹ Niger, Umar Bago, ni wọn bu mọ iye ọmọ ti awọn ajinigbe naa ko, asọdun si ni iye ti wọn kede kiri.
"Ti a ba ka awọn akẹkọọ naa ni eni, eji, iye awọn ọmọ ti ajinigbe ko kere si iye ti aye n pariwo.
'Gomina naa wa n di ẹbi ru awọn alasẹ ile ẹkọ naa lori bi wọn ko se gbe ilẹkun ile ẹkọ naa ti pa lẹyin ti awọn agbebọn ti kọkọ dunkooko pe awọn n bọ wa ka wọn mọle ni ọdun mẹrin sẹyin ati idunkooko miran ni osu meji sẹyin.
"Gbogbo awọn ileẹkọ to wa ni agbegbe naa ni wọn ti ti pa lati ọdun mẹrin sẹyin, iyalẹnu lo jẹ fun mi pe ile ẹkọ naa si n ba isẹ lọ."
O wa tẹnumọ pe idunkookomọni lasan ni isẹlẹ ijinigbe naa, gbogbo awọn akẹkọ ti wn ji gbe ọhun si ni wọn yoo gba silẹ laipẹ tabi to ba ya.
Amọ ọpọ awọn obi to ba BBC sọrọ ni bi igbesẹ ijọba lori isẹlẹ naa, to n fa bii igbin, ko tẹ lọrun.

Ijakulẹ bawọn obi lori igbesẹ ijọba nipa isẹlẹ ijinigbe naa
Ọpọ obi ni ijakulẹ ti ba lori igbesẹ ijọba ti ko mọyan lori nipa isẹlẹ ijinigbe naa.
"N ko le salaye ohun to mo n la kọja bayii, inu mi ko bajẹ to bayii ri" Peter, (kii se orukọ rẹ gangan), salaye fun BBC.
Se ni iporuru ọkan baa tori bi gomina ipinlẹ naa ko se tii se abẹwo sile ẹkọ naa nibi ti isẹlẹ ijinigbe ti waye.
Amọ se ni gomina naa lọ si agbegbe kan to sun mọ ileẹkọ yii lati bawọn osisẹ agbofinro ati adari agbegbe sọrọ lori isẹlẹ naa.
"Tori naa, a ti pinnu pe ijọba ko gba ọrọ wa ro, a si ri ara wa bii ẹni pe a kii se ara orilẹede yii, wọn ti kọ wa silẹ."
Lẹba ibẹ ni Theo, (Kii se orukọ rẹ gangan) duro si ilegbe akẹkọọ nibi ti ọmọ rẹ maa n sun, to si foju se mẹrin isẹlẹ ijinigbe naa.
"Ẹsẹ ni awọn akẹkọọ naa fi n rin, wọn si n da wọn bii igba ti Olusọaguntan ba n da maalu, awọn akẹkọ kan n subu, tawọn agbebọn naa si n ta wọn nipa, ti wn n jagbe mọ wọn pe ki wọn kide duro pada." Theo salaye fun BBC
"Awọn agbebọn naa lo wa lori Ọkada to to aadọta lasiko ti wọn n da awọn ọmọ naa lọ."
O ni oun ko lagbara lati se ounkohun fi dawọn agbebọn naa lọwọkọ lati mase ko awọn akẹkọọ naa, o pe awọn ọlọ̀paa amọ nigba ti wọn yoo fi de sibẹ, ẹpa ko boro mọ.
"O se mi bii pe ki n lọ ran wọn lọwọ amọ mo da ro lẹẹmeji, ti mo ba lọ gan, ki ni mo fẹ se, n ko le da wọn lọwọkọ."
O si foju han gbangba pe awọn obi awọn ọmọ ti wọn ji gbe naa n la irora nla kọja.
"Inu mi ko dun, gbogbo aye mi lo kun fun ibanujẹ, ọmọkunrin kan soso ti mo bi ree, oun ni akọbi mi, ẹ jọọ, ẹ ran mi lọwọ." Ọkan lara wọn iya ti wọn gbe ọmọ rẹ lọ lo sọ bẹẹ.
Ọpọ eeyan ni inu n bi pe awọn alasẹ ko se ohun to to lati dẹkun iwa ijinigbe eyi to ti di tọrọ fọn kale ni Naijiriia bayii.
Ẹkun ariwa ipinlẹ Niger nibi ti ilu Papiri wa, lo ti di ibudo ijinigbe gba owo amọ awọn agbofinro ko tiẹ si rara ni agbegbe naa lai naani awọn isẹlẹ ijinigbe to n waye.

Ọpọ eeyan lo n di ẹbi isẹlẹ ijinigbe ati ọsẹ agbebọn ru bi ipinlẹ Niger se tobi pupọ
Ti a ba ni ka sọrọ bi ilẹ se tẹju si, ipinlẹ Niger lo tobi julọ nilẹ Naijiria, koda, o tobi ju awọn ilu kan ilẹ Europe bii Denmark ati Netherlands lọ.
Idi si ree ti awọn igbo kijikiji to wa ni ipinlẹ naa ko se ni amojuto to yẹ, ti awọn agbebọn si n lo awọn inu igbo naa lati pagọ si ati oju ọna sawọn ipinlẹ miran ati orilẹede mii nilẹ Afirika.
Laarin ọsẹ to kọja, iwa ijinigbe lawọn ile ẹkọ yii si ni ikẹta iru rẹ.The abduction at the school was the third to hit Nigeria in a week.
Ni ọjọ Aje to kọja, o le ni ogun akẹkọbinrin ti BBC gbọ pe wọn jẹ Musulumi, tawọn agbebọn ji gbe nilegbe wọn nipinlẹ Kebbi.
Bakan naa, awọn agbebọn tun ya bo sọọsi kan ni ilu Eruku nipinlẹ Kwara, ti wọn si pa eeyan meji nigba ti wọn ko eeyan mejidinlogoji lọ.
Idi si ree ti aarẹ Bola Tinubu se wọgile irinajo rẹ lọ si ibi ipade apero G20 nto n waye nilẹ South Africa, eyi ti yoo fun ni anfaani lati koju isoro to wa nilẹ.
Aarẹ Bola Tinubu si kede loju opo ayelujara rẹ pe gbogbo eeyan ti agbebọn ji gbe nilu Eruku ni wọn ti gba pada wa sile.
Bakan naa, ọpọ awọn ile ẹkọ jakejado ilẹ wa ni wọn ti gbe ilẹkun wọn ti pa tori isẹlẹ ijinigbe naa, tawọn obi si n sare lọ gbe awọn ọmọ wọn.
BBC rinrinajo lọ silu Papiri lati ilu Minna, tii se olu ilu ipinlẹ Niger, irianjo naa si lo kun fun ọpọ ewu.
Nibo miran, wọn yoo sọ fawọn akọroyin BBC pe ki wọn mase gba awọn ọna kan, nibomiran, awọn ọlọpaa lo n lewaju wọn lọ.















