BBC tú àṣírí àwọn èèyàn tó ń fi ẹran ara èèyàn jóògùn, ọlọ́pàá kó wọn sí àtìmọ́lé

Àkọlé fídíò, BBC tú àṣírí àwọn èèyàn tó ń fi ẹran ara èèyàn jóògùn, ọlọ́pàá kó wọn sí àtìmọ́lé
    • Author, Tyson Conteh
    • Role, BBC Africa Eye
    • Reporting from, Sierra Leone
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọpọlọpọ mọlẹbi lo ti wa ninu ibanujẹ bayii lẹyin iku awọn eeyan wọn ti awọn kan pa lati fi joogun ni Sierra Leone, ikọ oluwadii BBC Africa Eye ṣe ọfintoto awọn to wa nidii iṣekupani naa.

Ikilọ: Awọn iroyin kan wa nibi to le ba inu rẹ jẹ.

Iya ọmọ ọdun mọkanla kan ti wọn pa lati fi joogun lọpọ ọdun sẹyin ṣi wa ninu ibanujẹ bayii latari pe ẹnikẹnikẹ ko tii jiya ṣiṣe iku pa ọmọ naa.

Nigba to n ba BBC Africa Eye sọrọ nipa ọmọ rẹ Papayo, Sallay Kalokoh ni "inu mi bajẹ lonii nitori a ko gbọ nnkankan mọ nipa idajọ ododo."

Ẹja ni ọmọdekunrin naa lọ ta ninu ọja ti ko si pada wale mọ.

Odidi ọsẹ meji gbako lawọn mọlẹbi rẹ fi n wa kiri ki wọn to ri oku rẹ ninu kanga kan ti wọn ti ge ẹya ara rẹ wẹlẹwẹlẹ.

Arabirin Kalokoh ni "A maa n kilọ fun awọn ọmọ wa ki wọn maa ṣọra pe ki wọn ma lọ si awon kọrọkọndu lati ta ọja tabi gba owo lọwọ ẹni ti wọn ko mọ ri.

Ipaniyan naa to waye niluu mi Makeni, to wa ni aringbungun Sierra Leone jẹ eyii to ba mi ninu jẹ pupọ lẹyin ti awọn alaṣẹ ko ṣe nnkanka nipa rẹ.

Lori iku Papayo, ọlọpaa ko tilẹ fidi rẹ mulẹ pe ni ṣe wọn fi ọmọ kekere naa joogun.

Pupọ irufẹ iku bẹẹ ni ọlọpaa kii ṣewadii latari igbagbọ ati ibẹru awọn funra nipa oogun abẹnu gọngọ.

Babalawo to wọ awọtẹlẹ funun to si fi aṣọ pupa bo oju rẹ
Àkọlé àwòrán, Babalawo kan ree ni Sierra Leone to maa n fi ẹya ara eeyan joogun
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Orilẹede naa jẹ ibi ti ọpọ akọmọṣẹ dokita ko si, fun apẹrẹ, akọṣẹmọṣẹ onimọ isegun nipa ayẹwo oku, 'pathologist', kan ṣoṣo lo wa nibẹ pẹlu eeyan to fẹẹ to miliọnu mẹsan an.

Ẹyii mu ko ṣoro lati ṣe iwadii ibi ti iku Papayo ti wa.

Yatọ si eyii, ọpọ eeyan nilẹ naa lo ni igbagbọ ninu ooogun abẹnugọ ni Sierra Leone, koda awọn ọlọpaa gan gbagbọ ninu rẹ, eyii lo fa a ti wọn kii fi n ri idi ọpọ iku wọnyii.

Ninu iwadii BBC Africa Eye, a ṣawari babalawo meji ti wọn si sọ pe awọn maa n fi ẹran eeyan ṣetutu.

Wọn sọ fun wa pe wọn wa lara ẹgbẹ kan ti wọn ti n se irufẹ owo bẹẹ nilẹ ọhun, ọkan ninu wọn tilẹ sọ pe gbogbo ẹkun iwọ oorun Afrika ni oun ni awọn eeyan si amọ a ko le fidi rẹ mulẹ.

Ọkan ninu awọn akọroyin wa to ni kamẹra idankokọ lara pe ara rẹ ni Osman to jẹ oloṣelu to si fẹ fi eeyan joogun ko le wọle ibo.

A pade babalawo kan ninu igbo Kambia, o pe ara rẹ ni Kanu.

Nigba ti a ba sọrọ o ni "Mo ti ṣoogun fun awọn oloṣelu nla-nla ni Guinea, Senegal ati Naijira. A ni awọn to n ba wa ṣiṣẹ, fọfọ ni ibi yii maa n kun lasiko ibo."

Nigba keji ti a maa lọ sọdọ rẹ, o fi agbari eeyan han Osman lati fi han pe oun ko ṣere.

O ni "Ṣe o ri, ẹnikan ni a fi agbari yii ṣiṣe fun, agbari obinrin ni, emi ni mo si yan an gbẹ… ibi la ti n pa wọn, ibẹyẹn ni ẹjẹ wọn n lọ.

Awọn olowo, gbogbo wọn lo maa n wa sibi ti wọn ba ti n wa agbara."

Nigba ti Osman sọ fun pe oun n fẹ ẹsẹ obinrin fun etutu idibo, o ni oun yoo gba 70m leones to jẹ £2,500 tabi $3,000.

Sally Kalokoh ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC
Àkọlé àwòrán, Iya to bi Papayo Sally Kalokoh ṣi n daro iku ọmọ rẹ titi di oni

Ninu igbagbọ wa pe Kanu le jẹ onijibiti, a ko gbogbo ẹri to wa lọwọ wa fun ọlọpaa.

Awọn babalawo kan maa n pe ara wọn ni oniṣegun.

Ajọ WHO sọ pe ni Sierra Leone nnkan nii ẹgbẹrun kan dokita lo forukọsilẹ lọdọ ijọba nibẹ lọdun 2022, nigba ti wọn ni oniṣegun ẹgbẹrun marundinlaadọta.

Pupọ ninu awọn eeyan orilẹede naa lo gbẹkẹle awọn oniṣegun wọnyii fun iwosan oniruru aisan.

Sheku Tarawallie, to jẹ olori ẹgbẹ awọn oniṣegun sọ fun wa pe awọn kii fi eeyan joogun amọ awọn kọlọrọsi bii Kanu lo n ba orukọ awọn jẹ.

O ni "A n gbiyanju lati wẹ orukọ wa mọ amọ awọn eeyan nigboro ko mọ iyatọ to wa laarin wa, oniṣegun naa ni gbogbo wọn n pe wa. Ẹja kikẹ kan lo maa n ba gbogbo ẹja inu apẹrẹ jẹ."

Ọgbẹni Sheku Tarawallie ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu ijọba bayii lati fi oju awọn aṣebi naa lede.

Oju ọna adugbo kan ni Sierra Leone
Àkọlé àwòrán, Sierra Leone jẹ ọkan lara awọn orilẹede to tọṣi julọ lagbaaye lẹyin gun abẹle ọdun mọkanla

O ṣoro lati mọ iye eeyan pato ti wọn n fi joogun ni Sierra Leone ti ọpọ eeyan rẹ n pe ara wọn ni Musulumi tabi Kristẹni.

Emmanuel Sarpong Owusu, to jẹ oluwadii ni fasiti Aberystwyth nilẹ Gẹẹsi sọ fun BBC pe ijọba orilẹede naa ko ya fifi eeyan joogun sọtọ gẹgẹ ẹṣẹ ipaniyan kan pato.

O sọ pe "wọn maa n ka iku awọn kan bii igba ti ẹranko ba pa eeyan tabi bii igba ti eeyan ba ni ijamba tabi iku atọrunwa. Ida 90% awọn to n fi eeyan joogun ni kii foju wina ofin."

Babalawo mii to n fi eeyan joogun niluu Freetown, ti orukọ rẹ n jẹ Waterloo sọ pe oun ni to Babalawo bii 250 ti wọn n ba oun ṣiṣẹ.

Waterloo sọ pe "ko si irufẹ ẹya ara eeyan ti a ko ni, ti a ba ti bere eyikeyi ẹya ara bayii ni awọn eeyan wa maa n fi ṣọwọ si wa.

Sheku Tarawallie, to jẹ olori ẹgbẹ awọn oniṣegun
Àkọlé àwòrán, Sheku Tarawallie, to jẹ olori ẹgbẹ awọn oniṣegun sọ fun wa pe awọn kii fi eeyan joogun amọ awọn kọlọrọsi bii Kanu lo n ba orukọ awọn jẹ

Lakoko kan, o pe akọroyin wa pe awọn ti ri ẹni ti wọn yoo pa lati fi joogun, lẹsẹkẹsẹ ni a ke si ileeẹẹ ọlọpaa.

Nigba ti ọwọ tẹ Babalawo naa ninu orule ile rẹ pẹlu ọbẹ lọwọ rẹ wọn ṣawari oniruru eegun eeyan, irun atawọn nnkan to da bii yẹpẹ ti wọn wu jade lati inu iboji oku nibẹ.

Ninu oṣu Kẹfa ọdun yii ni wọn gbe oun atawọn meji mii lọ ile ẹjọ pẹlu ẹsun oogun ṣiṣe lọna aitọ.

Awọn afurasi naa ni awọn ko jẹbi ẹsun ti ọlọpaa fi kan wọn nile ẹjọ.

Ile ẹjọ naa si gba beeli wọn pe ki wọn maa lọ sile amọ ki iwadii lori ẹsun maa tẹsiwaju.

Ọlọpaa meji ya bo ile awọn to n fi eeyan joogun
Àkọlé àwòrán, Asiko ti ọlọpaa ya bo ile awọn to n fi eeyan joogun
Map