Kókó àbájáde ìwádìí àwọn aṣòfin Amẹrika lórí ọ̀rọ̀ tí Trump sọ pé ìpanirun àwọn Kristẹ́nì ń ṣẹlẹ̀ ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn aṣofin orilẹede Amẹrika ti fẹsun kan awọn ẹgbẹ alakatakiti ẹsin pe wọn fẹ pa ẹsin kristẹni run ni Naijiria lo jẹ ki wọn maa ṣe oriṣiiriṣii ikọlu sawọn ile ijọsin atawọn kristẹni.
Awọn aṣofin naa tun fẹsun kan ijọba Naijiria wi pe o ti kuna lati pese eto aabo to peye.
Ọrọ yii jade nibi ipade apapọ awọn aṣofin ti Aarẹ Donald Trump pe fun lori ọrọ ikọlu sawọn kristẹni to n ṣẹlẹ ni Naijiria.
Awọn aṣofin to jẹ ọmọ igbimọ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ati ọrọ awọn ẹgbẹ agbesunmọmi bii Boko Haram, ISWAP to fi mawọn Fulani to n ṣekolu si ileto awọn kristẹni laarin gbungbun ati apa ariwa orilẹede Naijiria sọrọ nibi ipade ọhun.
Brian Mast to n ri sọrọ ilẹ okeere sọ pe ko si nnkan to jọ ija ileto kan si omiran ninu nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria bayii, Mast ni awọn to n ṣe ikọlu yii mọọmọ fẹ pawọn kristẹni run lori ilẹ ati nile wọn ni.
Chris Smith toun naa n dari igbimọ kan to n ri sọrọ to niṣe pẹlu Afirika sọ pe awọn janduku to n ṣe ikọlu ni Naijiria n huwa ta ni yoo mu mi pẹlu bi wọn ṣe n pawọn eeyan, ji eeyan gbe ti ẹnikankan ko si dawọn lọwọ kọ.
''Naijiria kii ṣe orilẹede ti eeyan ti le ṣe ẹsin to ba wu u mọ''
Awọn akọṣẹmọṣẹ kan nibi apero naa sọ pe bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe ati bi wọn ṣe n lo awọn ofin ẹsin kan lati ṣekupa awọn eeyan lawọn ipinlẹ ariwa Naijiria kan n ṣafihan pe Naijiria kii ṣe orilẹede ti eeyan ti le ṣe ẹsin to ba wu u mọ.
Vicky Hartzler, aṣofin to jẹ alaga igbimọ Amẹrika to n ri si ominira lati ṣe ẹsin to ba wu eeyan, sọ pe ko si ominira lati ṣe ẹsin to wu eeyan mọ ni Naijiria.
Hartzler ni ijinigbe awọn akẹkọọ to le ni 300 nile ẹkọ ijọ Katoliiki kan nipinlẹ Niger jẹ ọkan lara ẹri to le fidi eyi mulẹ.
Ọpọ akọṣẹmọṣẹ lori eto aabo ti sọ fun ijọba Amẹrika wi pe ko ma fi Aarẹ Bola Tinubu lọrun silẹ lori ọrọ eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria, titi ti ijọba apapọ yoo fi ṣẹgun gbogbo ẹgbẹ alakatakiti ẹsin to n ṣoṣẹ ni Naijiria.
Ile aṣofin Amẹrika ti bẹrẹ iṣẹ lori abọ to fẹ fun Aarẹ Trump lori nnkan to kan fun Amẹrika lati ṣe lori oniruuru ikọlu to n waye ni Naijiria.
Amẹrika ti kede wi pe ọrọ nnkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria n kọ awọn lominu, eyi lo si jẹ ki Aarẹ Trump dunkoko lati ko ọmogun wa Naijiria lati wa koju awọn to wa nidi ikọlu to n waye.
Bo tilẹ jẹ pe awọn aṣofin Amẹrika ti pe fun atunṣe ofin Sharia lawọn ipinlẹ kan lapa ariwa Naijiria, iwe ofin Naijiria ko fun Tinubu lagbara lati dasi ọrọ naa bo ba ṣe wu u.
Ipinlẹ mejila lẹkun ariwa Naijiria lo n lo ofin Sharia lati ọdun 1999, atunṣe ofin yii maa nilo ayipada iwe ofin Naijiria, aarẹ Naijiria ko si lagbara ṣe atunṣe iru ofin bayii.
Aarẹ Naijiria ko laṣẹ lori awọn ile ẹjọ ipinlẹ, tori naa, ọpọ ni yoo ṣe atako si iru igbesẹ bẹẹ ti aarẹ ba le gbiyanju lati yi ofin Naijiria pada.
Ijọba apapọ le gba awọn ijọba ipinlẹ ni imọran lati ṣe atunṣe ofin Sharia, amọ, ko laṣẹ lati fopin si ofin Sharia.
''Ko si nnkan to jọ iṣekupani kristẹni ni Naijiria, gbogbo ẹlẹsin lawọn janduku n pa''
Ṣaaju ipade awọn aṣofin Amẹrika yii lawọn aṣoju ijọba Naijiria kan ti oludamọran aarẹ lori eto aabo, Nuhu Ribadu, dari wọn ṣabẹwo si Amẹrika lati fọrọ jomitoro ọrọ pẹlu ijọba Amẹrika lori ọna lati fopin si ikọlu to n ṣẹlẹ ni Naijiria.
Lasiko abẹwo naa lawọn aṣoju Naijiria sọ pe ko si ohun to jọ iṣekupani awọn kristẹni ni Naijiria gẹgẹ bii Trump ṣe sọ.
Awọn aṣoju Naijiria ni awọn janduku agbebọn to n ṣọṣẹ ni Naijiria ko fi ti ẹsin kan ṣe, bi wọn ṣe n kọlu kristẹni ni wọn n kọlu musulumi naa.
Imọran awọn aṣofin Amẹrika fun Naijiria
Lara imọran tawọn aṣofin Amẹrika fun ijọba Naijiria lori eto aabo to n buru sii ni pe ijọba Amẹrika yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu Naijiria, yoo si ṣe iranwọ nipa ṣiṣe idanilẹkọọ fawọn ọlọpaa Naijiria.
Awọn aṣofin naa tun sọ pe ijọba Naijira gbọdọ tete maa gbe igbesẹ ti wọn ba ti ri ikilọ nipa ikọlu to le ṣẹlẹ.
Nnkan mii ni pe ijọba Amẹrika yoo tun tẹsiwaju lati lo awọn akọṣẹmọṣẹ rẹ lati le koju awọn agbesunmọmi to n ṣoṣẹ ni Naijiria.















