Báǹkì àgbà ilẹ̀ wa, CBN, mú àdínkù bá owó gbígbà síta

Aworan bi eeyan se n gbo owo naira lati ẹnu ATM

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Banki apapọ orilẹede Naijiria, CBN ti kede iye owo ti awọn eeyan le gba sita lọsẹ, bẹrẹ lati ọjọ kinni oṣu Kinni ọdun 2026, eyi ti yoo mu adikun ba bi awọn araalu se n ni anfani si ni ni owo lọwọ dipo lilo ẹrọ ayelujara lati san owo.

Eyi lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti CBN fi sita, lọjọ keji oṣu Kejila, ti Dr. Rita I. Sike buwọlu, CBN fi di rẹ mulẹ pe #500,000 ni araalu le gba sita lọsẹ bayii, nigba ti awọn ileeṣẹ nla yoo ni anfani lati #5m sita laarin ọsẹ kan.

Igbesẹ tuntun yii ni yoo wọgile eyi to ti wa ni ilẹ tẹlẹ, to fun awọn araalu ni anfani lati gba owo toto milọnu marun un sita lọsẹ, ti awọn ileeṣẹ si le gba milọnu mẹwaa sita.

Gẹgẹ bii CBN ṣe ṣalaye, awọn ayipada yii ni wọn gbe sita lati mu adikun ba bi awọn araalu se ti n na owo pepa ju, ti yoo si tun se afikun eto aabo, gbe ogun ti sise owo mọkumọku.

"Awọn ilana yii, ti a n gbe sita ni o da lori bi a ti se n na owo, ti a si fẹ mu adikun ba bi a se n na owo pepa, ti a si fẹ ki awọn eeyan bẹrẹ sini lo ohun igbalode lati lo owo wọn, paapa si san owo lori ayelujara," CBN ṣalaye.

Ohun to yẹ ko nipa gbigba owo sita bẹrẹ lati ọjọ Kini oṣu Kini ọdun 2025

Gbigba owo sita lẹyin gbedeke ọsẹ kan ti CBN gbe kalẹ lo jẹ pe o nilo lati san owo ko to le gba owo sita

To ba ẹnikan ni- Yoo san ida mẹta owo to ba fẹ gba sita

To ba jẹ ileeṣẹ ni: ida marun un ni yoo san lati le gba owo sita.

Owo yii ni yoo jẹ pinpin laarin CBN ati ile ifowopamọ

Lilo ẹrọ ATM ati sọwedowo gba owo

Labẹ ilana tuntun yii:

O ni anfani lati gba ₦100,000 lojumọ, pẹlu ₦500,000 laarin ọsẹ kan.

Gbogbo ohun to ba fi ATM gba ni yoo jẹ akojọpọ laarin ọsẹ kan.

Awọn ilefowopamọ, bayii yoo nilo lati ma ko orisirisi owo sinu ẹrọ ATM

To ba wọle sinu Banki, pe o fẹ lo iwe sọwedowo, ko yi pada rara, to si le gba ₦100,000 lojumọ, eyi ti ohun yoo jẹ kika pe o ti gba owo laarin ọsẹ.

Ajọ CBN ni igbesẹ yii yoo jẹ ki ọpọ araalu tẹramọ lilo ohun igbalode lati ma san owo tabi fun karakata wọn.

CBN rọ awọn araalu, paapa awọn olokowo pe asiko ti to bayii lati tẹwọgba ọna miiran lati gba owo tabi san owo.

Bẹẹ ba gbagbe Ile ifowopamọ apapọ ni Naijiria, CBN ti mu alekun ba iye owa tawọn ile ifowopamọ yoo maa ja nigba ti eeyan ba gba owo lẹnu ATM.

Ọgọrun-un kan naira (₦100) ni wọn yoo maa ja bayii lodi si naira marundinlogojì (₦35) ti wọn n ja tẹlẹ̀.