Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Edo ní kí ìyàwó Tuface, Natasha Osawaru, wáá ṣàlàyé ara rẹ̀, ìdí rèé

Oríṣun àwòrán, Others
Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Edo ti paṣẹ pe ki iyawo gbajugbaja olorin taka-sufee nni, Tuface Idibia, iyẹn Ọnarebu Natasha Osawaru Irobosa, yọju si igbimọ to n ri si iwa ọmọluabi ati anfaani nile naa.
Natasha ti ifẹ oun ati Tuface gbode lojiji, ni aṣofin to n ṣoju ẹkun Egor, nipinlẹ Edo.
Ibẹrẹ ọsẹ yii si ni iwa ti awọn aṣofin ẹgbẹ rẹ ka si idojuti, jẹ jade ti wọn fi ni ko waa ṣalaye .
Abẹnugan ile igbimọ aṣofin Edo, Blessing Agbebaku lo kede lọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji oṣu Kẹjila ọdun 2025 lasiko ipade, pe:
"Ọnarebu Natasha Irobosa ni lati yọju si igbimọ to n ri si iwa ọmọluabi ati anfaani, lati jẹ ka mọ idi to ṣe fi ile igbimọ wọlẹ."
Bakan naa ni Agbebaku kede pe Natasha tun ni lati ṣalaye idi ti ile naa ko ṣe ni I fi iya jẹ ẹ.
Laaarin ọsẹ kan ni wọn ni ki Iyawo Tuface yọju, ki igbimọ ti yoo ri si ọrọ rẹ si mu abọ wa laaarin ọsẹ meji.
Kí ni Natasha Osawaru ṣe gan-an, kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú?

Oríṣun àwòrán, Hon. Natasha Osawaru/ Facebook
Bi Tuface ṣe jẹ gbajumọ olorin ti ọpọ eeyan fẹran to, awọn ohun to n ṣe awọn ololufe rẹ ni kayeefi lo n ṣẹlẹ si i to si n tori rẹ di ọmọ ti aye n sọ lori ayelujara latigba to ti fẹ Natasha Osawaru.
Ọpọ igba ni wọn maa n yanna-an ọrọ rẹ pẹlu iyawo to ṣẹṣẹ fẹ naa, ti iroyin si maa n gbe e pe oju ọkunrin ti wọn tun n pe ni Tu-Baba yii n ri nnkan ninu igbeyawo tuntun yii.
Ni ti eyi to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ ti ile igbimọ aṣofin Edo fi ranṣẹ pe iyawo rẹ yii, o waye lasiko ti Tuface fi ara han lori eto ori Instagram kan ti atọkun eto, Daddy Freeze, n dari.
Lori eto naa ni awọn eeyan mi-in naa ti darapọ, pẹlu awon eeyan ti Tuface paapaa ti ba ṣiṣẹ pọ ri.
Ko pẹ ti Tu-Baba darapọ mọ eto naa ni Natasha naa fi ara han, ariyanjiyan bẹ silẹ laaarin tọkọ-tiyawo naa bi eto ọhun ṣe n lọ lọwọ, kia si ni Tuface kuro lori eto ọhun.
Atọkun eto naa ti i ṣe Daddy Freeze lo gbe fọnran ohun to ṣẹlẹ yii jade lọjọ Aje ọsẹ yii loju opo Facebook rẹ.
Ṣaaju ni fidio kan naa ti jade sori ayelujara, nibi ti wọn ti ni ọlọpaa mu Tuface ni UK, lẹyin ti ọrọ ṣe bii ọrọ laaarin oun ati Ọnarebu Natasha.
Ta a ni Natasha Osawaru?

Oríṣun àwòrán, Hon. Natasha Osawaru/Facebook
Ọrukọ rẹ ni kikun ni Natasha Irobosa Osawaru, awọn eeyan maa n pe e ni Ọnarebu Natasha.
Oloṣelu ni, ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Edo lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP ni.
Akọsilẹ iyawo Tuface yii lati ọdọ ajọ eleto idibo, INEC, sọ pe ijọba ibilẹ Egor, nipinlẹ Edo ni wọn ti bi Natasha lọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla odun 1994.
Lọwọlọwọ yii, oun ni Igbakeji olori ọmọ ẹgbẹ to pọ ju lọ nile igbimọ aṣofin Edo.
Amofin ni Natasha, o gboye ninu ẹkọ imọ ofin ni Yunufasiti Igbinedion, ipinlẹ Edo, o si kẹkọọ agba (Masters) ni Full Sail University, orilẹede America. Ẹkọ nipa fiimu ṣiṣe lo kọ nibẹ.
Ko too darapọ mọ oṣelu, awọn ọdọ ati awọn obinrin lo maa n gbẹnusọ fun, lati ri i pe idagbasoke n ba wọn.
Oṣu Kokanla ọdun yii ni oun ati Tuface bi akọbi ọmọ wọn, ọmọ ọkunrin.
Ẹ o ranti pe Annie Macaulay ni iyawo ti ọpọ eeyan mọ pẹlu Tuface fun ọdun pipẹ, ti wọn jọ maa n fi ifẹ han kiri.
Ṣugbọn lojiji ni Tu-Baba ati Annie tuka, ti eyi si dun ọpọ awọn ololufẹ wọn pupọ.
Bi Annie ṣe lọ ni Natasha gba ipo iyawo tuntun lọọdẹ Tuface, bo tilẹ jẹ pe awuyewuye jẹyọ lọtun-un losi lori ajọṣepọ naa nigba yẹn.














