Ìwakùsà lọ́nà àìtọ́ ló ń ṣokùnfà ètò àbò tó mẹ́hẹ lọ́dọ̀ wa, a fẹ́ kí Ààrẹ gbẹ́sẹ̀le – Àwọn gómìnà Àríwá

Awọn gomina iha ariwa nibi ipade naa niluu Kaduna

Oríṣun àwòrán, OGA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn gomina ni Ariwa Naijiria ti ke si Aarẹ Bola Tinubu pe ko gbẹsẹle iwakusa lagbegbe naa fun oṣu mẹfa gbako lati le koju iṣoro eto to n ba agbegbe naa finra.

Ọrọ yii lo jẹyọ nibi ipade awọn gomina mọkandinlogun agbegbe ọhun to waye niluu Kaduna.

Ipade naa ti awọn ori ade agbegbe naa yọju si ni wọn ti fẹnuko pe ki wọn maa ko owo ti iye rẹ to biliọnu kan naira jọ loṣoṣu fun eto abo agbegbe naa.

Gbọgan nla Sir Kashim Ibrahim House ni ipade naa ti waye labẹ asia ẹgbẹ Northern States Governors' Forum (NSGF) ati Northern Traditional Rulers' Council.

Ohun ti ipade naa da lori ni eto abo agbegbe wọn to mẹhẹ ati ọna abayọ.

Gomina ipinlẹ Gombe ati adari ẹgbẹ NSGF, Inuwa Yahaya, sọ pe awọn ti ṣakiyesi pe iwakusa lọna ti ko ba ofin mu lo n ro awọn agbebọn atawọn ọdaran mii lagbara lagbegbe ọhun.

O wa rọ Aarẹ Bola Tinubu ko gbẹsẹle gbogbo iwe aṣẹ iwakusa lagbegbe naa fun igba diẹ.

O tun kan sara si Aarẹ fun akitiyan bi wọn ṣe da awọn ọmọde ti awọn agbebọn ji gbe pada wa sọdọ awọn obi wọn.

Yahaya sọ pe awọn adari agbegbe Ariwa ti ṣetan lati rẹyin gbogbo ohun to n ṣokunfa eto abo to mẹhẹ lagbegbe awọn.

"A ti fọwọ si ọlọpaa ipinlẹ bayii"

Awọn gomina ati ori ade naa tun sọ pe awọn fọwọ si idasilẹ ọlọpaa agbegbe, wọn si rọ awọn aṣofin lati ṣe ohun to yẹ ni kankan fun idasilẹ ileeṣẹ agbofinro naa.

Yahaya ni awọn ti fẹnuko lati fọwọsowọpọ pẹlu Aarẹ Tinubu fun alaafia agbegbe wọn.

O ni biliọna kan naira ti wọn fẹ maa ko jọ loṣoṣu yoo wa fun eto abo pajawiri agbegbe maa, ijọba ipinlẹ ati ijọba ibilẹ ni yoo si lọwọ si akojọpọ owo naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, kii ṣe ileeṣẹ ologun nikan ni yoo yanju iṣọro eto abo to mẹhẹ, ipese iṣẹ fun awọn ọdọ atawọn ohun amayedẹrun mii yoo tun ṣeranwọ lati ri alaafia lagbegbe ọhun.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Uba Sani sọ pe bi ijọba apapọ nikan ṣe n dari ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ yii ko bojumu mọ, ko si daa fun bi nnkan ṣe ri lode oni.

O wa kilọ fun awọn kọlọrọsi ẹda kan to n lo anfani eto abo to mẹhẹ fun anfani ara wọn ki wọn ki ọwọ ọmọ wọ bọ aṣọ.