Orúkọ àwọn aṣojú Naijiria sílẹ̀ òkèèrè ti Tinubu fi ránṣẹ́ sí àwọn aṣòfin di ariwo

Reno Omokri ati Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Reno Omokri /Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 11

Lẹyin iku akan, ariwo ẹnu lo kan ni ọrọ da bayii lati igba ti Aarẹ Bola Tinubu ti kede orukọ awọn eeyan marundinlogoji to fi ranṣẹ sile igbimọ aṣofin lati buwọ lu gẹgẹ bii aṣoju Naijria si awọn ilẹ okeere.

Ẹ o ranti pe opin ọsẹ to kọja yii ni iroyin orukọ awon eeyan ti aarẹ fẹ lo naa jade sita.

Lara awọn eeyan ti Tinubu fi orukọ wọn ranṣẹ lẹyin ọdun meji to ti n ba iṣakoso yii bọ ni Femi-Fani Kayode, Reno Omokri, Ọjọgbọn Mahmud Yakubu, Florence Ajimobi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣugbọn pupọ ninu awọn eeyan ti aarẹ fẹ lo naa ni awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ati awọn ọmọ Naijiria paapaa n koro oju si.

Wọn ni awon eeyan ti ko ni akọsilẹ ire lẹka ti wọn di mu, ti wọn ko ṣe ododo, ti wọn si le jẹ kilẹ okeere maa fi oju abuku wo Naijiria ni Tinubu ko jọ lati ṣoju wa.

Ọpọ lo n sọ pe Aarẹ Tinubu fi orukọ awọn eeyan naa ranṣẹ lati san oore ti wọn ṣe fun un lọna kan tabi ikeji pada ni.

Bẹẹ ni awọn mi-in si n sọ pe ki aarẹ tete pa orukọ naa pada, ko ma ba Naijiria loju jẹ ju bẹẹ lọ kaakiri agbaye.

Eyi ni diẹ lara ẹgbẹ oṣelu ati awọn araalu ti wọn ti fi aidunnu wọn han si awọn aṣoju ti Tinubu fẹ lo nilẹ okeere.

Dá orukọ àwọn to o fi ranṣẹ yẹn pada, yan awọn mi-in ti wọn jẹ́ ọmọluabi

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹgbẹ alatako gboogi fun APC ni Naijiria, PDP ti ṣapejuwe iyansipo naa bii jibiti, ohun ti eeyan gbọdọ bu ẹnu atẹ lu ati eyi ti ko ni ẹtọ ninu rara.

Wọn ni awọn eeyan ti orukọ ati ìṣe wọn ko ṣee ranti si rere ni aarẹ yan, o si fi han pe ko si ètò mọ nipa yiyan ẹni to yẹ si ọfiisi ijọba.

Akọwe apapọ fun PPDP, Ini Ememobong, sọ pe awọn ti Tinubu yan yii fi han pe Aarẹ funra rẹ ko ka jijẹ ọmọluabi ati kiko akoyawọ kun .

O ni o fi han pe aarẹ ko ka oju yowu ti wọn ba fi n wo Naijiria si nilẹ okeere kun pẹlu.

"Oju ohun ti aarẹ n ri lọwọlọwọ yii lo fi fẹ ran iru awọn eeyan yii lati ṣoju Naijiria, oju ti awọn ilẹ okeere yoo fi wo Naijiria ko kan an, nitori ẹ lo ṣe n ran iru awọn eeyan yii lọ lati ṣoju Naijiria."

Ememobong lo sọ bẹẹ.

Bakan naa lo ni bi Tinubu ṣe yan alaga INEC tẹlẹ, Mahmud Yakubu, ko daa.

Ememobong sọ pe Yakubu to jẹ magomago pọ lasiko to n ṣe alaga INEC.

O ni bi Aarẹ ṣe fa a kalẹ yii tumọ si idupẹ oore magomago to ṣe fun un lasiko ibo ọdun 2023 ni.

PDP ni ki Aarẹ Tinubu tete gba iwe orukọ to fi ranṣẹ sile igbimọ aṣofin naa pada, nitori awọn eeyan ti orukọ wọn kun fun iwakiwa lo fi ranṣẹ pe ki wọn ṣoju Naijiria nilẹ okeere.

Ẹgbẹ Alaburada ni ki Tinubu yan awọn mi-in ti orukọ wọn muni ranti iwa ọmọluabi lati ṣoju Naijiria.

O fi han pe ijọba yii ko ka ṣiṣe oju Naijiria nilẹ okeere si nnkan kan-ADC

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) koro oju si igbesẹ aarẹ yii.

Agbẹnusọ ADC, Bolaji Abdullahi, ṣapejuwe rẹ bii pe APC ko ni nnkan kan lati ṣe.

"To ba jẹ pe ohun ti wọn ri mu wa ree lẹyin ọdun meji aabọ ti wọn ti fi ṣọfo, o fi han pe wọn ko ni nnkan kan lati ṣe.

"Bii igba ti wọn fi san ara wọn lẹsan ni, ki i ṣe pe wọn ni ohun ti wọn fẹ ṣe fun Naijiria lasiko yii lori awọn ohun to n ṣẹlẹ."

"O ni awọn ti wọn fẹ ṣoju ilẹ Africa ninu wọn le maa koju ayẹwo finni-finni lati awọn orileede naa, ṣugbọn awọn to ba fẹ ṣoju Naijria ni United States, Moscow, abi UK, le ma tete ri itẹwọgba wọn gba titi di ọdun to n bọ.

NNPP:

Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party, (NNPP) Ladipo Johnson, ni tiẹ koro oju si orukọ alaga INEC tẹlẹ, Mahmud Yakubu to wa lara awọn aṣoju naa.

O ni bi aarẹ tilẹ ni aniyan rere to fi yan Yakubu, araalu ko fi oju ire wo eyi, afi bi a ba fẹ maa tan ara wa.

"Ẹ ma gbagbe pe alaga to ṣẹsẹ fipo silẹ naa lo ṣeto idibo apapọ ni INEC, ibo naa lo si gbe Aarẹ Tinubu wọle, gbogbo wa naa la si mọ pe awuyewuye pọ ninu ibo yẹn."

Agbẹnusọ NNPP yii sọ pe ko tọna rara bi Tinubu ṣe yan Yakubu to ṣẹṣẹ fipo alaga INEC silẹ.

Èyí burú jáì, ó sì dójú tini-Human Rights Writers Association of Nigeria (HURIWA)

Lara awọn ẹgbẹ to tun ti koro oju si awọn eeyan ti Aarẹ Tinubu yan lati ṣoju Naijiria nilẹ okeere ni ẹgbẹ to maa n kọwe lori ẹtọ ọmọniyan ni Naijiria, Human Rights Writers Association of Nigeria (HURIWA).

HURIWA pe iyansipo naa ni ohun to buru jai to si tun mu idojutini dani.

Oludari HURIWA, Emmanuel Onwubiko, sọ pe Tinubu n san oore fun awọn oloṣelu ti nnkan ko ṣe ẹnu ire fun wọn mọ ni, awọn arire-bani-jẹ ati awọn eeyan ti wọn ko ni iwa ọmọluabi.

Awọn eeyan bii Femi Fani-Kayode ati Reno Omokri, ni HURIWA kọminu lori wọn ju, wọn ni iṣẹ ka maa bu awọn alatako wọn ti wọn yan laayo ni Aarẹ san ẹsan rẹ fun wọn bayii.

Èrò aráàlú lójú òpó X

Loju opo X, ẹnikan to pe ara rẹ ni @InibeheEffiong, kọ ọ sibẹ pe:

"Iwe orukọ awọn aṣoju ti Aarẹ Tinubu fi ranṣẹ yii tun fidi ẹ mulẹ si i, pe ilu ti wọn ti maa n da awọn ọdaran lọla ni a n gbe.

"Awọn ti wọn lọwọ si bi Naijiria ṣe bajẹ ni wọn tun pọju ti wọn yan lati ṣoju orilẹede wa nilẹ okeere.

"Pupọ ninu awọn orukọ to wa lori iwe naa lo jẹ ti awọn oloṣelu ti wọn ti kuna lati ṣiṣẹ nipo ti wọn ti di mu ri, awọn arijẹni-madaru ati awọn ti jijẹ ọmọluabi wọn ko fẹsẹ rinlẹ."

@ruffydfire kọ ọ pe: "Awọn ọmọ Naijiria duro fun ọpọ ọdun lati ni aṣoju, lẹyin naa lo si wa han si wọn pe oṣelu ni gbogbo ẹ ba de, iṣẹ awọn ọkunrin ati obinrin wọn ni.

@engr_shaibu_: " Abuku ni eyi fun gbogbo ọmọ Naijiria kọọkan to n gbiyanju lati jẹ eeyan. Tinubu ti yan Reno Omokri bii aṣoju. Reno Omokri kan naa to fi ọpọlọpọ ọdun pe Tinubu ni ọba awọn to n gbe egboogi oloro, to ni ẹwọn lo yẹ ki Tinubu wa, pe ki i ṣe Aso Rock. Ẹni kan yii naa lo gbe iwe yunifasiti Chicago jade, to ni Tinubu ko yẹ lati jẹ olori. Reno yẹn. Lonii, afẹsunkanni ti di aṣoju. Agabagebe ti ni ọmọ iranṣẹ tuntun.

"Eyi ni ohun to fi han wa pata, pe jijẹ ọmọluabi ko nitumọ ninu iṣakoso yii, iwọ ṣaa ti jẹ oloootọ leyin idibo"

@Samzonal: "Tinubu san oore fun awọn isọngbe rẹ, Reno Omokri ati Femi Fani-Kayode, pẹlu eeyan Wike; Okezie Ikpeazu ati Ifeanyi Ugwuanyi, o sọ wọn di aṣoju.

"Ko jọ ọpọ loju, Bola Tinubu n tẹsiwaju ninu sisan oore fawọn to n ṣe tiẹ ni Naijiria ni."

@macburnertunes: "Tinubu n yan awọn oloṣelu to ti darugbo, ti wọn ti fẹyinti, lati ṣoju Naijiria nilẹ okeere.

"Ko si ohun kan to maa yipada, bi a ba n tẹsiwaju lati maa lo awọn arugbo ni ẹka oṣelu wa."

@Nwafresh: "Reno ati FFK bii aṣoju. Koda Ikpeazu to jẹ ipinlẹ Abia run ati Yakubu… Ẹ ko le ri awọn eeyan to ni otitọ inu layika Tinubu. Awọn eeyan bii tiẹ naa lo fi yi ara rẹ po…"

Àwọn to gbóróyìn fún Ààrẹ Tinubu

Ko ni i buru buru ki ma ku ẹnikan mọ ni, ẹni ti yoo kù la o mọ niYoruba wi.

Bi awọn kan ṣe bu ẹnu atẹ lu awọn ti Aarẹ Tinubu fẹ lo yii naa ni a ri awọn ti wọn gbe ori yin fun un.

Diẹ lara awọn wọnyi ni:

Senetọ Teslim Folarin

Ọkunrin to dupo ipo gomina ipinlẹ Oyo ni 2023 yii ko ri ohun to buru ninu orukọ awọn eeyan ti Aarẹ Tinubu fi ranṣẹ.

Teslim Folarin gboriyin fun Tinubu fun bo ṣe yan Florence Ajimobi, iyawo gomina Oyo tele, Oloogbe Abiola Ajimobi, gẹgẹ bii aṣoju Naijiria nilẹ okeere.

O ni ipo to yẹ Florence Ajimobi ni Aarẹ Tinubu fun un.

Bakan naa ni ẹgbẹ kan, ''The Security Committee of Yoruba Leaders, naa gboriyin fun Aarẹ Tinubu fun orukọ Ayo Oke, adari NIA tẹlẹ to wa lara awọn aṣoju naa.

Wọn ni o kaju ẹ gidi.

Eletekete ni awọn alatako, iyansipo Yakubu ko yẹ ko fa ẹjọ-APC

Ninu awijare ẹgbẹ APC lori ẹsun yii, Alukoro apapọ fun ẹgbẹ naa, Bala Ibrahim, sọ pe eletekete ni awon ẹgbẹ oṣelu to n tako orukọ awọn eeyan ti Aarẹ fa kalẹ .

"Ṣe o wa tumọ si pe bi eeyan ba ti ṣe alaga INEC ri, ki i ṣe ọmọ Naijiria mọ niyẹn, tabi ko le dipo mu mọ?"

Bẹẹ ni Bala beere.

O ni bi ẹnikẹni ba n tako Yakubu lasiko yii nitori pe o ṣe alaga INEC ri, itako ti ko lesẹ nilẹ ni.

Alukoro APC naa sọ pe iṣẹ INEC kọ ni Yakubu n lọ ṣe bayii, iṣẹ aṣoju Naijiria ni.

O fi kun un pe Yakubu nikan kọ lo kuro ni INEC to si tun gba iṣẹ oṣelu, o ni bẹẹ lo ri fun aṣiwaju rẹ ti I ṣe Ọjọgbọn Atahiru Jega naa.

O ni Jega naa gba iṣe ilu lẹyin to kuro ni INEC

Bala sọ pe koda ko jẹ pe ẹsan oore ni eyi jẹ fun Yakubu, ẹsan oore to le kan oun abi ọmọ Naijiria eyikeyi to ba ṣe iṣẹ rẹ daadaa ni.

Tinubu yan Fani-Kayode, Reno, Yakubu, iyawo Ajimobi àtàwọn 28 míì sípò aṣojú ìjọba Naijiria nílẹ̀ òkèèrè lẹ́yìn ọdún méjì ìjọba rẹ̀

 Femi Fani-Kayode, alaga ajọ INEC tẹlẹ, Mahmood Yakubu, oludamọran aarẹ Naijiria tẹlẹ, Reno Omokri ati Florence Ajimobi, aya gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ wọ oniruuru aṣọ ibilẹ

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X

Aarẹ Bola Tinubu ti yan mínísítà ọkọ ofurufu tẹlẹ, Femi Fani-Kayode, alaga ajọ INEC tẹlẹ, Mahmood Yakubu, oludamọran aarẹ Naijiria tẹlẹ, Reno Omokri, Florence Ajimobi to jẹ aya Gomina ipinlẹ Oyo nigba kan ri at'awọn mejidinlọgbọn mii sipo aṣoju ijọba Naijiria nilẹ okeere.

Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, lo fọrọ yii lede loju opo X rẹ lanaa ọjọ Àbámẹ́ta tíì ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kọkànlá yii.

Awọn mii to wa ninu awọn ti Tinubu kede orukọ wọn ni gomina ipinlẹ Abia tẹlẹ, Okezie Ikpeazu, igbakeji gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Femi Pedro, Sẹnẹtọ Jimoh Ibrahim lati Ondo, aya Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Erelu Angela Adebayo ati Sẹnẹtọ Grace Bent lati ipinlẹ Adamawa.

Aarẹ Tinubu ti forukọ awọn eeyan mejilelọgbọn náà ṣọwọ sile aṣofin agba l'Abuja fún ibuwọlu iyansipo wọn.

Lẹta meji ọtọọtọ ni Tinubu kọ sí aarẹ ile igbimọ aṣofin agba, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, wí pe ki ile buwọ́lù mẹẹdogun ninu won gẹgẹ bii akọṣẹmọṣẹ aṣojú ìjọba Naijiria nilẹ okeere ati metadinlogun mii gẹgẹ bii aṣoju Nàìjíríà lasan an.

Obinrin mẹwaa lo wa ninu awọn ti Tinubu ṣẹṣẹ yan sipo aṣoju ijọba Naijiria nilẹ okeere

Atupalẹ orukọ awọn eeyan naa fi han pe obinrin mẹwàá lo wa ninu awọn ti Tinubu ṣẹṣẹ yan sipo ọhun.

Awọn mii to wa lara awon ti Tinubu yan sipo naa ni Ogbonaya Kalu lati ipinlẹ Abia, Tasiu Musa Maigari lati Katsina ati kọmíṣọ́nà tẹlẹ lati ipinlẹ Plateau, Yakubu N. Gambo.

Awọn mii tun ni Sẹnẹtọ Nora Ladi Daduut lati Plateau, Nkechi Ufochukwu lati Anambra, kọmiṣọna nipinlẹ Eko tẹlẹ, Lola Akande ati asojú ìjọba Naijiria si Holy See tẹlẹ, Paul Oga Adikwu lati ipinlẹ Benue.

Lara awọn mii ti aarẹ tun yan sipo aṣoju ijọba Naijiria nilẹ okeere tun ni Enebechi Monica Okwuchukwu lati Abia, Yakubu Nyaku Danladi lati Taraba, Miamuna Ibrahim Besto lati ipinlẹ Adamawa, Musa Abubakar lati Kebbi, Syndoph Endoni lati Bayelsa, Chima Geoffrey Lioma David lati ipinlẹ Ebonyi ati Mopelola Adeola-Ibrahim lati Ogun.

Onanuga ṣàlàyé nínú atẹjade to fi síta náà pé àwọn orílẹ̀ede to ni ibasepọ to dan mọran pẹlu Naijiria bíi India, South Korea, Canada, Mexico, UAE, Qatar, South Africa, àti Kenya lawọn eeyan naa yoo ti lọ ṣojú ìjọba Naijiria.

O ni lẹyìn tí ile aṣòfin ba ti buwọ́lù iyansipo wọn tán ni wọn yoo mọ orilẹede ti wọn n lọ.

Iyansipo yìí wáyé lẹyìn tí Tinubu ti kọkọ forukọ eeyan mẹta ranṣẹ sile aṣofin agba fun ibuwọlu.

Awọn eeyan naa ni Ayodele Oke lati ipinlẹ Oyo, Amin Mohammed Dalhatu láti Jigawa ati Ajagunfẹyinti Lateef Kayode Are lati Ogun.

Ileeṣẹ aarẹ ni o ṣee ṣe kawon eeyan yii lọ ṣojú ìjọba Naijiria lorilẹede UK, Amerika ati France.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post