Àwọn jàndùkú agbébọn tún ya wọ ṣọ́ọ̀ṣì Kerubu (C&S) ní Kogi, jí pásítọ̀ àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn míì gbé lọ

Awọn agbebọn to tẹle ara wọn pẹlu ibọn lejika wọn

Oríṣun àwòrán, Google

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iroyin to tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Kogi ti sọ pe awọn janduku agbebọn tun ti ya wọ ile ijọsin kan nipinlẹ Kogi nibi ti wọn ti ji pasitọ ati iyawo rẹ pẹlu awọn eeyan mii gbe lọ.

Ile ijọsin ọhun ni a gbọ pe o wa lawujọ Ejiba ni ijọba ibilẹ guusu Yagba.

Oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Kogi kan lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun BBC.

A gbọ wi pe ṣadeedee lawọn janduku agbebọn ọhun ya wọ ṣoọṣi C & S naa ti wọn si bẹrẹ sii yinbọn lera lera.

Iroyin naa sọ pe bayii lawọn olujọsin bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wọn.

Ẹwẹ, agbẹnusọ ijọba ipinlẹ Kogi, Kingsley Fanwo, ti sọ pe ijọba n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ eleto aabo atawọn fijilante lati doola awọn tawọn agbebọn naa ji gbe lọ nile ijọsin C&S ni awujọ Ejiba.

''Loootọ ni mo gbọ nipa iṣẹlẹ ijinigbe to ṣẹlẹ, awọn ẹṣọ eleto aabo atawọn fijilante ti bẹrẹ iṣẹ lati mawọn janduku agbebọn naa.

Awọn to ṣiṣẹ laabi yii naa mọ pe ipinlẹ Kogi yoo ri pe gbogbo awọn eeyan ti wọn ji gbe lo kuro lakata wọn,'' Fanwo lo sọ bẹẹ fun BBC.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin oniruuru iṣẹlẹ ijinigbe bẹẹ to ti ṣẹlẹ lawọn ile ẹkọ ati ile ijọsin nipinlẹ Kebbi, Niger ati Kwara.

Laipẹ yii ni lawọn janduku agbebọn ji akẹkọọ 300 ni ile ẹkọ ijọ Katoliiki kan to wa nipinlẹ Niger gbe lọ.

Bakan naa lawọn janduku agbebon tun ji awọn akẹkọọbinrin ile ẹkọ onileegbe kan lọ nipinlẹ Kebbi.

Lasiko kan naa ni wọn ti ji awọn olujọsin lọ ninu ijọ CAC kan niluu Eruku nipinlẹ Kwara nibi ti wọn tun ti ṣekupa awọn eeyan.

Iṣẹlẹ ti Kogi yii yoo tun jẹ ki ijọba tun okun ṣokoto rẹ so lori ati pese aabo fawọn akẹkọọ atawọn olujọsin nile ijọsin ti ko si ni igboro.