"Koko lara ọta mi le" - Bàbá Ẹda Onile ola sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ tó ní ó kú

Aworan Lere Paimo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Agba ọjẹ onitiata ilẹ Yoruba, Lere Paimọ ti sọrọ lori iroyin ẹlejẹ to jade ni afẹmọju, ọjọ kọkandinlọgbọn, kọkanla ọdun 2025, eyi to kede baba ọhun ti pa ipo da.

BBC Yoruba kan si ilẹ Baba Lere Paimo niluu Ibadan, ti wọn si fidi ẹ mule wi pe iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin naa ati pe alaafia ni baba wa.

Nigba ti baba n ba ikanni BBC News Yoruba sọrọ lori iroyin ọhun, Baba Ẹda Onile-Ọla salaye wi pe ojiji ni iroyin ọhun ba oun ati idile rẹ lati oru ana ọjọ Ẹti.

Baba, to tun jẹ Aarẹ Arobajo ti ilu Ogbomọsọ, rọ awọn ti n ro irokiro lati jawọ, o rọ wọn lati dẹkun a n gbe iroyin ofege kiri.

Bakan naa lo tun gba adura fun awọn ọmọ ẹgbẹ ati ololufẹ wọn fun ifẹ wọn.

"Iroyin ohun ba awa gan lojiji lati oru ana, gbogbo ẹni to ba n gbe iroyin ki iroyin, to n ro irokuro, ki wọn mọ wipe gbogbo ohun ti awọn ba n se, ika kan ni wọn na si ọmọlakeji, mẹsan-an to ku ọdọ wọn ni o maa wa"

"Mo rọ wọn ki wọn mọ gbe iroyin igbekugbe mọ, ohun ti o ba daa yin loju ẹ mọ sọ-ọ mọ, koko lara ọta mi le, ẹẹ ni se aarẹ o, ẹ ronupiwada, ẹmi gbogbo wa o gun titi dọjọ alẹ".

Ọkan lara awọn ọmọ-iṣẹ agba osere ninu iṣẹ tiata ọhun, Nikẹ Afrikana, salaye wi pe afẹmọju l'awọn gbọ iroyin aheso ọhun. O fidi ẹ mulẹ wipe ara baba le koko, ti wọn si wa ni alaafia.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Osere-binrin ọhun, ti a tun mọ si Iya Bukọla Ọmọ daddy, tunbọ rọ awọn oniroyin lati maa fi idi otitọ mulẹ ki wọn to ma gbe iroyin jade.

"A se ajọyọ, a se ọjọ-ibi, ẹ o bawa gbe, a se ohun ribiribi ti ẹnikẹni o bawa gbe-e, kilode ti wọn wa n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri. Kokoko lara baba le, alaafia ni wọn wa, wọn ti rin inu ọgba kiri laarọ yii, ẹdakun ẹ mọ gbe iru iroyin bẹẹ mọ".

Nigba ti wọn n sọrọ, Gomina ana fun ẹgbẹ awọn osere ANTP ni ipinlẹ Ọyọ, Boye Abidoye tunbọ fidi rẹ mule wi pe baba wa laye ati laaye. Abidoye se afikun wipe eniyan gidi, ti awọn ọmọ ẹgbẹ onitiata n kọ ẹkọ ribiribi ati ọgbọn lara rẹ ni Lere Paimo.

Abidoye rọ awọn ti n gbe iroyin ofege pe ki wọn ronupiwada nitori wipe ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ osere o le sun latari iroyin ẹlẹjẹ ọhun.

Sunday Olu-ọmọ Ẹda salaye wipe deede aago mẹwaa ni alẹ ana ọjọ Aje lawọn gbọ iroyin ọhun. Sunday tunbọ fidi rẹ mulẹ wipe kebekebe ni agba osere ọhun wa nigba ti ohun dele wọn ni aarọ oni ọjọ abamẹta.

Ìwádìí BBC Yoruba rèé lórí bóyá Lere Paimo, àgbà òṣèré kú àbí ó wà láàyè

Aworan Oloye Olalere Osunpaimo

Oríṣun àwòrán, Instagram

‎Ni owurọ ọjọ Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni iroyin kan jade pe gbajugbaja oṣere tiata, Oloye Olalere Osun Paimo ti jade laye ṣugbọn lẹyin ọpọ iwadii a ri pe iroyin ofege ni.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ, Association of Nigeria Theatre Arts Practitioners (ANTP), Ọmọọba Adejonwo Oluwafemi Femson buwọlu fun awọn akọroyin fidi rẹ mulẹ pe irọ to jina si otitọ ni iroyin ọhun.

Femson ni o ṣeni laanu pe awọn eeyan kan n gbe irufẹ iroyin ofege bayii sita, to si fi di rẹ mulẹ pe oun ti ba mọlẹbi oloye naa sọrọ.

"A ti ba iyawo Baba Eda Onile Ola sọrọ, o si jẹ ko di mimọ pe alaafia ni Baba wa ninu ilera to peye.

"A n rọ awọn araalu lati ye gbe iroyin ofege sita lati fi si ọpọ eeyan lọkan.

"Oloye Olalere Osun Paimo (MFR), ọkan ẹgbẹ Association of Nigeria Theatre Arts Practitioners (ANTP), wa laaaye ."

Ohun to yẹ ko mọ nipa Oloye Lere Paimo

Oloye Lere Paimo, jẹ oṣere tiata, oludari sinima ati agbesinima jade lati orilẹede Naijiria.

Wọn bi ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 1939 niluu Ile Ikoyi Odan, Osupa niluu Ogbomoso nipinlẹ Oyo.

Baba rẹ jẹ agbẹ oni tabako, ti iya rẹ si jẹ onisowo ọja.

Lere Paimo bẹrẹ ẹkọ alakọbẹrẹ ni Ogbomoso, ko to di pe o morile orilẹede Ghana..

Lẹyin eto ẹkọ rẹ, o pada si orilẹede Naijiria, to si n gbe ni ilu Osogbo nipinlẹ Osun nibi to ti ṣisẹ gẹgẹ bii olukọ ni ile ẹkọ Baptist Missionary School.

Lere Paimo bẹrẹ iṣẹ tiata ni ọdun 1958 nigba to darapọ mọ egbẹ oṣere Oyin Adejobi, ti Pa Oyinade Adejobi da silẹ. Nigba to ya, o darapọ mọ ẹgbẹ oṣere Duro Ladipo.

O di ilumọka lẹyin to kopa ninu sinima kan Ogbori Elemosho, nibẹ lo ti jẹ Soun Ogunola.

Ni ọdun 2005, ijọba orilẹede Naijiria fi ami ẹyẹ Member of the Federal Republic (MFR) fi da Lere Paimo lọla fun iṣẹ ribiribi to ti ṣe ninu ere sinima.

Bakan naa lo tun yege ninu ere kan ti a n pe ni Who Wants to Be a Millionaire, to si gba ẹbun milọnu kan naira.