Kí ló mú àwọn jàǹdùkú gún Ọlọ́pàá kan pa l'Ondo, tí iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣe fi pańpẹ́ mú afurasí méjì?

Ọlọ́pàá mẹ́ta ń wọ́ afurasí kan nilẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọrọ di boo lọ, kò yàgò fún mi ni agbegbe Arakale n'ilu Akure ni olu ilu Ipinlẹ Ondo, lasiko ti edeaiyede waye larin awọn to n ta òṣìṣẹ́ ọlọkọ ero to ń ta tikẹti ati Ọlọpaa kan to n se isẹ ni ayika agbegbe naa.

Lasiko àbẹ̀wò BBC News Yoruba si agbegbe naa, awọn osojumikoro to ba ileeṣẹ wa sọrọ salaye pe ikọ Ọlọpaa naa n ṣe isẹ rẹ lọwọ lagbegbe naa lasiko ti oni maruwa kan wa ọkọ rẹ lọna aitọ.

Wọn salaye pé, ni kete ti Ọlọpaa naa ri iṣẹlẹ yii, o gbiyanju lati sọ fun oni maruwa naa lati wa ọkọ rẹ si ẹba ọna ti ko ni ṣe idiwọ.

Kí ni Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yí?

Sugbọn lasiko naa ni awọn oṣiṣẹ to n ja tikẹti naa de pẹlu ero pe se ni Ọlọpaa naa fẹ gba owo ẹyin, eyi lo fa ija, ti awọn to n ja tikẹti naa si gun Ọlọpaa yii, pẹlu ọ̀bẹ.

Osojumikoro miran ti ọrọ rẹ yatọ sọ pé, ṣe ni Ọlọpaa naa fẹ́ gba owo lọwọ oni maruwa náà, idi niyi ti awọn to n ja tikẹti fi da si ọrọ naa ko to di wahala eyi to gbẹmi ikọ Ọlọpaa naa.

Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ondo DSP Ayanlade Olushola sọ di mimọ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ni Ọjọru ọsẹ yi.

Ayanlade sọ pe ede-ai-yede lo waye laarin awọn janduku kan ati Ọlọpaa to wa loju isẹ ti awọn janduku naa si gun Ọlọpaa naa.

O salaye pe kete ti Kọmisọna Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo gbọ ọrọ naa o pasẹ fun awọn ikọ Ọlọpaa to n risi iṣẹlẹ pajawiri lati lọ si oriko naa. Kete ti wọn de oriko naa wọn fi panpe ọba mu awọn afunrasi meji ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

Awọn mejeeji yi ni Shina Jacob ẹni ọdun marundinlọgbọn àti Felix Olalekan ẹni ọdun mejilelọgbọn.

Ayanlade salaye pe loju kan naa ni wọn gbiyanju lati doola ẹmi Ọlọpaa ti wọn gun lọbẹ naa, sugbọn ẹpa o boro mọ, Ikọ Ọlọpaa naa ku lasiko to n gba iwosan.

Alukoro naa sọ siwaju si pe lẹyin iṣẹlẹ yi ni wọn lọ kakiri agbegbe Arakale ati awọn oriko miran ti awọn janduku pọ si lati ri daju pe, wọn fọ Ipinlẹ Ondo mọ pátápátá.

O salaye pe ko si ikọ ileeṣẹ Ọlọpaa to lẹtọ labẹ ofin lati tẹ ẹtọ awọn ara ilu mọlẹ, bẹẹni wọn ko ni foju ire wo ẹnikẹni to ba sakọlu si awọn ikọ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo.

Ayanlade sọ siwaju pe awọn afunrasi mejeeji yoo foju ba Ileẹjọ laipẹ fun idajọ to tọ lori iṣẹlẹ naa.