Àwọn gómìnà Gùùsù Naijiiria ṣe ìpàdé l‘Ogun, wo kókó ohun mẹ́fà tí wọn ń fẹ́

Awon gomina Guusu atawon omo egbe naa mi-in

Oríṣun àwòrán, @Ogun Government

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọjọru, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni ipade awọn gomina ẹkun Guusu Naijiria waye nilee Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapo Abiodun, niluu Iperu Remo.

Ipade ọhun ko ṣẹyin iṣoro aabo to n koju Naijiria lasiko yii, paapaa ijinigbe ati ipaniyan.

Akojọpọ awọn gomina ilẹ Yoruba (South-West),awọn ti Guusu-Ila-Oorun (South-East) ati Guusu-Guusu ( South-South) lo peju sibi ipade naa.

Bakan naa ni ipade ọhun tun kan awọn ọba alaye, nibi ti kaluku ti sọrọ lori aabo, oṣelu, idagbasoke ati ifọwọsowọpọ to le ṣẹgun ipayinkeke.

Lajori ipade ọhun lẹyin ti wọn ba Aarẹ Bola Tinubu ati gbogbo ọmọ Naijiria kẹdun idojukọ yii ni pe wọn fi ẹnu ko si awọn igbesẹ kan ti wọn ni yoo gbogun ti iṣoro aabo.

Lara rẹ ni idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ti ọpọ araalu ti n pe fun tipẹ.

Awon lobaloba pelu Gomina Dapo Abiodun to gba alejo ipade naa

Oríṣun àwòrán, @Ogun Government

Èyì ni awọn koko igbesẹ ti wọn fẹnuko le lori nipade naa

  • Dida owo aabo ẹlẹkunjẹkun

Awọn gomina yii fẹnuko lati maa da iye kan ti wọn yoo bu fun wọn bii ẹdawo aabo.

Wọn ni ẹkun kọọkan yoo maa da tirẹ bii iranwọ ati atilẹyin, ko si fun nnkan mi-in ju aabo awọn ẹkun naa lọ.

Wọn fi kun un pe ipade oloṣooṣu kan naa yoo maa waye pẹlu, awọn olugbani-nimọran lori aabo ni yoo maa ri si eyi.

  • Ipese ilana ibaraẹnisọrọ lọna igbalode to ya kankan
  • Awọn gomina yii panupọ pe ibaraẹnisọrọ to ya ṣe pataki, pẹlu ipese awọn ẹrọ igbalode to le mu ki awọn ipinlẹ maa ba ara wọn sọrọ nipa ohun to ba n ṣẹlẹ, ti yoo si tun fi ri kọrọ ati gbangba agbegbe han .
  • Ìpè fun ọlọpaa ipinlẹ

Ipade naa tun ṣe atunwi ipe fun dida ọlọpaa ipinlẹ silẹ, bo ṣe ti pẹ ti wọn ti n kede rẹ pe awọn fẹ ko waye.

Wọn ni ohun to ṣe pataki lati ni, ni ọlọpaa ipinlẹ, nitori ko sẹni to le mọ ile e ṣọ bii onile funra rẹ, o si ti to ki ijọba apapọ pin agbara yii si ẹlẹkun-jẹkun bayii.

  • Idanimọ awọn eeyan ipinlẹ

Wọn lo ṣe koko ki ipinlẹ kọọkan ni Guusu ni akọsilẹ awọn eeyan ibẹ, nipa eto iforukọsilẹ to peye.

Wọn fẹnuko lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ National Identity Management Commission (NIMC) ki kaluku fi orukọ silẹ bii ara ipinlẹ to n gbe.

Gomina Dapo Abiodun ati awọn igbimọ Guusu

Oríṣun àwòrán, @Ogun Government

Ṣiṣe atilẹyin fun iṣẹ awọn ọdẹ ibilẹ ati fijilante

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa ni wọn fẹnuko lati ṣe atilẹyin fun iṣẹ aabo awọn ọlọde ibilẹ ati awọn fijilante.

Wọn lawọn yoo pese irinṣẹ, nnkan irinsẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ fun wọn.

  • .Ibojuto ọrọ ilẹ ati iru iṣẹ ti araalu n ṣe lori rẹ

Igbimọ gomina Guusu naa sọ pe ki kaluku mojuto ohun ti awọn eeyan n ṣe lori ilẹ ati bi ilẹ ọhun ṣe n to wọn lọwọ.

Wọn ni iṣẹ awọn ọba alaye ati baalẹ ni eyi lati bojuto.

Wọn ni ajọṣepo gbọdọ wa laaarin ijọba ati awọn olori agbegbe, lati ri I pe ko si ilokulo ilẹ bii awọn to n wa kusa lọna aitọ, tabi awọn iṣẹ mi-in to le fa ewu fun araalu.

Igbimọ yii ni oun ṣetan lati gbogun ti iwakusa lọna aitọ, eyi to ti fa iṣoro fun ayika, wọn ni awon eleto to n ri si ayika ko ni I gbẹyin ninu abojuto naa.

.Riro awọn lọbalọba lagbara:

Awọn ipinlẹ Guusu rọ awọn gomina rẹ lati ro awọn ọba alaye ati igbimọ wọn lagbara nipa pipese owo fun wọn, ti wọn yoo fi tun le maa mojuto aabo, iṣelu ati alaafia agbegbe wọn si i.

Nipari ohun gbogbo, wọn fẹnuko pe awọn ni gbagbọ ninu Aarẹ Tinubu (Vote of confidence), wọn ni o kaju rẹ, o si ku ifọmọniyanṣe bo ṣe n koju iṣoro aabo.

Awọn gomina naa ṣeleri atilẹyin wọn fun aarẹ pẹlu.

Diẹ lara awọn gomina to wa nibi ipade naa ni:

Biodun Oyebanji tipinlẹ Ekiti, Peter Mba tipinlẹ Enugu, Gomina ipinlẹ Ebonyi, Francis Nwifuru ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn ọba alaye bii Ọọni Ile Ife,Oba Enitan Ogunwusi, Alaafin Oyo; Oba Abimbola Owoade, Olowo tilu Owo, Oba Ajibade Gbadegesin, Alake ilẹ Egba; Oba Adedotun Aremu Gbadebo atawọn mi-in naa ko gbẹyin.