Ọdún Orò tó ní kí aráàlú fìdí mọ́lé láì tan iná ní Oregun l‘Eko di wàhálà, ọlọ́pàá kó àwọn Ọ̀jẹ̀ méjìlá, ariwo sọ

Eegun alare ati awọn eeyan rẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni iwe kan to n kede ọdun egungun to si tun ni kawọn eeyan ma jade lawọn asiko kan niluu Oregun, ipinlẹ Eko, gba ori ayelujara kan.

Bi iwe ọhun ṣe wa lori ayelujara ni wọn tun pin i kiri lojukoju .

Ninu iwe naa ni wọn ti kede pe ọdun egungun fẹ waye lọjọ kẹtadinlọgbọn si ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2025 yii, l'Oregun.

Wọn ni wọn yoo ṣe oro oru lati aago mẹwaa alẹ si mẹrin owurọ ọjọ keji.

Iwe naa tun kede pe awọn eeyan Oregun ati alejo to ba fẹ wọ ibẹ gbọdọ dopin wiwa nita lati aago mẹwaa alẹ si aago mẹrin idaji awọn ọjọ meji naa.

Ikọ Eleegun ni ẹnikẹni ko gbọdọ tan ina lati aago mẹwaa alẹ titi di ọjọ keji, wọn si gbọdọ wa ninu ile lai jade titi ti asiko oro yoo fi lọ

Gẹgẹ bi iwe ikede naa ṣe ṣalaye, Olu ilu Oregun, Ọba Olusesan Olukunmi Akingbola, lo fi ikilọ naa sita.

Ninu ikilọ ọhun ni wọn ti ni awọn eto kan yoo waye lati ọwọ alẹ wọ oru ọjọ keji.

Wọn ni ẹnikẹni ko gbọdọ tan ina lati aago mẹwaa alẹ naa titi di ọjọ keji, bẹẹ ni wọn si gbọdọ wa ninu ile lai jade titi ti asiko oro egungun naa yoo fi lọ.

Wọn fi kun un pe awọn ti fi to ọlọpaa leti, wọn yoo si wa ni awọn ibi to yẹ bi eto naa ba ti n lọ lọwọ.

Ikọ eleegun ti i ṣe Ọjẹ parapọ ni wọn lo wa nidii eto naa.

Bi ẹnikẹni ba kọti ọgbọin si ikilọ yii bi wọn ṣe wi, oluwa rẹ yoo ri esi aigbọran lẹsẹkẹsẹ bi ikede naa ṣe sọ.

Iwe ikede ti awọn Eleegun n [pin kiri nipa ọdun Oro ti yoo waye ni Oregun nilu Eko, to si n sọ pe kawọn eeyan fidi mọle, ki wọn ma si tan ina alẹ.

Oríṣun àwòrán, Lagos Police Command

Ọlọ́pàá Eko tako ìkéde náà, mú àwọn tó ń kéde rẹ̀ kiri

Ọjọ keji ti iwe ikede awọn Ọjẹ jade ni ileeṣẹ ọlọpaa Eko tako o.

Alukoro ọlọpaa Eko, SP Abimbola Adebisi, fi atẹjade sita l'Ọjọru lorukọ Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Olohundare Jimoh.

Ninu atẹjade naa lo ti ni ọwọ ti ba mejila ninu awọn to n pin iwe ikede oro egungun naa, ti wọn pe ara wọn ni Ọjẹ parapọ ilu Oregun.

Ileeṣẹ ọlọpaa Eko sọ pe ikede to fẹ di irin ẹsẹ awọn araalu lọwọ, ti ko ni i jẹ ki wọn jade naa lodi si ẹtọ ọmọniyan.

Yatọ si mimu awọn eeyan naa labẹ ofin, Kọmandi ọlọpaa Eko tun paṣẹ pe oro egungun naa ko gbọdọ waye, nitori ko si itẹwọgba fun un.

Ọlọpaa Eko sọ pe ikede iru eyi di ẹtọ tawọn eeyan ni lati rin, lọwọ. O tako sisọ ero ọkan wọn ati iyi to wa fun wọn jijẹ ọmọniyan.

Olopaa Eko ni ko si ọdun ibilẹ ti yoo ko araalu laya soke, ti awọn yoo wa fi aaye gba iru rẹ lati waye

Gbogbo eyi ni wọn lo le ko ipaya ba araalu, ko si da omi alaafia to n toro ru pẹlu.

"Ko si ẹgbẹ to gbọdọ ṣe ofin lọwọ ara rẹ, tabi ko paṣẹ bi ara Eko yoo ṣe rin nigbakigba."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade awọn ọlọpaa naa wi.

Wọn fi kun un pe ikede konilegbele naa ti ko ipaya ba awọn eeyan Oregun ati agbegbe rẹ, eyi ni wọn ṣe fofin de ọdun oro egungun naa lati ma ṣe waye.

Olopaa Eko ni ko si ọdun ibilẹ ti yoo ko araalu laya soke, ti awọn yoo wa fi aaye gba iru rẹ lati waye.

Wọn rọ araalu lati maa ba iṣẹ wọn lọ, ki wọn ma si ṣe ko aya soke rara.

Bi ẹnikẹni ba kọ eti ikun ninu awọn Ọjẹ, to tun gbe igba oro egungun yii lati ṣe, ọlọpaa Eko ni tọhun yoo foju wina ofin bo ṣe yẹ.