Mi ò lè pe ohun tó wáyé ní Guinea- Bissau ní ìdìtẹ̀gbàjọba, ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé - Goodluck Jonathan

Aworan Aarẹ nigba kan ri lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan ni orilẹede Guinea Bissau

Oríṣun àwòrán, PATRICK MEINHARDT / AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Aarẹ orilẹede Naijiria nigba kan ri, Goodluck Jonathan ti sọrọ sita lori iṣẹlẹ iditẹgbajọba to waye lorilẹede Guinea-Bissau, to si ni ohun iyalẹnu lo jẹ pe Aarẹ orilẹede naa, Umaro Embalo lo kede iditẹgbajọba ọhun sita.

Gẹgẹ bii o ṣe sọ, Jonathan ni iditẹgbajọba ti wọn gbimọpọ lo waye lorilẹede Guinea Bissau.

"Ohun to waye ni Guinea-Bissau, mi o ni pe ni iditẹgbajọba. Ko ki n ṣe iditẹgbajọba, mo le pe ni erepa nitori Aarẹ Embalo lo kọkọ kede pe awọn ologun ti gba ijọba ṣaaju ki awọn ologun to jade sita sọrọ pe awọn ti gba akoṣo orilẹede naa.

"Embalo lo kede iditẹgbajọba, eyi to jẹ ohun iyalẹnu, ki n ṣe iyẹn nikan, nigba ti iditẹgbajọba yii n waye, Embalo n lo foonu rẹ fi ba awọn akọroyin agbaye sọrọ pe awọn ologun ti mu oun si ahamọ,"

Gomina ipinlẹ Bayelsa nigba kan ri ni ohun to ṣẹlẹ ni Guinea-Bissau jẹ ohun to dun oun pupọ gẹgẹ bii ẹni to gbagbọ ninu ijọba awarawa.

"Mo jẹ ọmọ aadọrun ọdun lati orilẹede Naijiria, mo mọ bi wọn ṣe ma n ṣe awọn olori ijọba lasiko iditẹgbajọba. Aipẹ yii mo sọju ECOWAS ni Mali, ti iditẹgbajọba si waye lasiko naa.

"Ologun ko ni gba ijọba, ko wa jẹ pe aarẹ to wa lori ipo yoo ni anfani lati ma ba awọn akọroyin sọrọ pe ọwọ ti tẹ oun, Ta lo n tan ara wọn?

"Ko da, ọrọ yii dun mi ju ọjọ ti mo pe Buhari pe mo ki ku orilẹ lọ nigba ti mo padanu eto idibo aarẹ lọ

Bawo ni eto idibo Guinea-Bissau se lọ?

Jonathan tẹnumọ pe eto idibo orilẹede Guinea Bissau waye lai si rogbodiyan kankan, to si pe fun pe ki wọn kede esi eto idibi naa.

"Eto idibo waye lai si rogbodiyan, ti gbogbo wa si n reti ki wọn kede si idibo naa sita fun araalu.

"Nigba ti wọn fẹ ṣetan ni, ti a n duro pe ki wọn kede esi idibo, ni Embalo kede pe iditẹgbajọba ti waye, ti ọwọ si ti tẹ oun.

"Ṣugbọn, ko si ọwọ kankan to tẹ. Ọrọ temi fun ajọ ECOWAS ati AU ni pe wọn gbọdọ kede esi idibo naa,"

Ológun gbàjọba Guinea-Bissau lọ́jọ́ kejì tí wọ́n gbé ààrẹ lọ

Ọgagun Horta N'Tam, olori Guinea-Bissau tuntun lo wa niwaju ninu aworan yii, awon iṣọngbe rẹ ninu ologun lo wa pẹlu rẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọgagun Horta N'Tam, olori Guinea-Bissau tuntun lo wa niwaju ninu aworan yii, awon iṣọngbe rẹ ninu ologun lo wa pẹlu rẹ.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ijọba tuntun ti bẹrẹ ni Guinea-Bissau pẹlu bi wọn ṣe bura fun olori ogun kan, Horta N'Tam, gẹgẹ bii olori orilẹede naa bayii.

Ẹ o ranti pe ana ode yii ni awọn kan to dihamọra ogun gbe aarẹ to wa nipo naa tẹlẹ, Umaro Sissoco Embaló, lọ.

Gbigbe ti awọn to dihamọra ogun naa gbe Umaro lọ, waye lẹyin ọjọ kẹta ti wọn dibo aarẹ lorilẹede naa, ti Umaro si ti reti pe ki wọn kede oun bii ẹni to jawe olubori.

Oni Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2025 yii ni ajọ eleto idibo Guinea-Bissau fẹ kede esi idibo naa tẹlẹ, ṣugbọn ọjọ naa gan-an ni awọn ologun kede Ọgagun Horta N'Tam bii olori orilẹede tuntun.

Iditẹgbajọba ti ko tete foju han lo waye lorilẹede naa lanaa ode yii, araalu sọ fun BBC pe awọn n gburoo ibọn, ṣugbọn awọn ko mọ ohun to n ṣẹlẹ.

Ni ti Jẹnẹra Horta N'Tam ti wọn bura fun bii olori orilẹede Guinea-Bissau, eyi to waye ni olu ileeṣẹ ologun ilẹ naa lonii Ọjọbọ, ọdun kan ni wọn ni yoo fi wa nipo naa.

Ṣaaju ni awọn ologun naa ti dena awọn eleto idibo lati ma ṣe kede esi ibo to yẹ ki wọn kede lonii, ti wọn si kede ijọba ṣọja bii eyi ti yoo maa ṣakoso lọ.

Awọn ologun naa kede pe awọn ti gbakoso Guinea-Bissau, bẹẹ ni BBC gbọ pe wọn ti fi Umaro Embaló si ahamọ.

Lori ẹrọ amohunmaworan orilẹede Guinea-Bissau ni awọn ologun naa ti kede pe awọn ti da ikọ ologun onirapada silẹ, awọn yoo si maa dari rẹ lọ titi digba ti ikede miran yoo waye.

Ṣé lóòótọ́ ni pé Umaro Sissoco ló ṣẹ̀tò ìgbàjọba rẹ̀?

Loju iwoye awọn ẹgbẹ kan lorilẹede Guinea-Bissau, wọn ni aarẹ ti wọn le lọ naa, Umaro Sissoco Embaló, lo ṣeto iditẹgbajọba to yọ ọ nipo.

Awọn ẹgbẹ naa sọ pe Umaro gbe igbesẹ ọhun lati ma ṣe jẹ ki esi ibo jade ni, nitori to ba lọ fidirẹmi.

"Ero rẹ lori ọna to gba yii ni lati ma ṣe jẹ ki ajọ eleto idibo gbe esi ibo jade lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kọkanla to yẹ ki esi idibo jade, nitori to ba kuna lati yege."

Bẹẹ ni ẹgbẹ Coalition Popular Front naa wi ninu atẹjade wọn l'Ọjọru.

Ẹwẹ, Embalo ti wọn gbe lọ ko ti i wi nnkan kan lori ẹsun yii.

O ti figba kan sọ pe aimọye igbiyanju lati gbajọba loun ti koju nigba toun wa lori aleefa.

Laarin aadọta ọdun si asiko yii, iditẹgbajọba to ti waye ni Guinea-Bissau ti to mẹsan-an.

Àwọn agbébọn mú Ààrẹ Guinea-Bissau lẹ́yìn ọjọ́ kẹ́ta ìdìbò ààrẹ

Aarẹ ti wọn mu naa, Umaro Sissoco Embalo nigba to n dibo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ orilẹede Guinea-Bissau, Umaro Sissoco Embalo ni awọn agbebọn kan ti mu bayii, lẹyin ọjọ kẹta ti idibo waye lorilẹede naa.

Oni Ọjọru, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kọkanla ni awọn eeyan kan to dihamọra, mu Aarẹ Umaro.

Eyi n waye lẹyin to dena alatako rẹ lati kopa ninu idibo to waye naa.

Nnkan bii aago kan ọsan ni awọn araalu bẹrẹ si i gburoo ibọn to n ro lakọlakọ bi wọn ṣe wi, ṣugbọn wọn ko tete mọ awọn to n yinbọn naa.

Ohun ti ọpọ eeyan n sọ ni pe mimu ti wọn mu aarẹ naa le ni i ṣe pẹlu iditẹgbajọba.

Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?

Aare Umaro Sissoco Embalo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu idibo to waye lọjọ kẹtalelogun oṣu Kọkanla yii ni Aarẹ Umaro Sissoco Embalo to wa lori aleefa ko ti jẹ ki alatako rẹ gan-an, Domingos Simoes Pereira, dije.

Fernando Dias ni wọn pada jọ du ipo aarẹ naa, ti igun mejeeji si ni awọn jawe olubori ni abala akọkọ idibo ọhun.

Ṣugbọn Fernando Dias sọ pe oun ko gba pe Umaro bori.

Olootu ijọba Guinea Bissau tẹlẹ, Domingos Simoes Pereira, ṣatilẹyin fun Fernando Dias, bo tilẹ jẹ pe wọn ko jẹ koun naa dije ninu ẹgbe PAIGC.

Ẹgbẹ PAIGC yii lo ṣatọna bi Guinea-Bissau ṣe gba ominira.

Ọjọbọ ọla yii ni ajọ eleto idibo ti ṣeleri lati kede ẹni to jawe olubori gan-an tẹlẹ.

Wọn kilọ fawọn oludibo, awọn oludije, ẹgbẹ oṣelu ati awọn akọroyin lati ma ṣe kede esi idibo kankan ṣaaju asiko naa.

Ninu eeyan 2.2 million to n gbe ni Guinea-Bissau, gbogbo wọn ni wọn fẹrẹ lẹtọ lati dibo.

Awọn ti wọn si jade dibo yii kọja ida marundinlaadọrin (65%).

Ṣugbọn lẹyin ọjọ kẹta ti ibo naa waye ni awọn kan yi ọrọ pada, wọn wọle gbe aarẹ to wa lori aleefa to si n reti ki won kede oun bii ẹni to tun jawe olubori lẹẹkan si i.

Ọkan lara awọn orilẹede Iwọ-Oorun Africa ni Guinea-Bissau, alajọsẹ awọn Potogi ni wọn lati ibẹrẹ aye wọn.

2019 ni wọn kọkọ yan ‎Umaro Sissiko Embalo sipo aarẹ.

Lati ọdun 1974 ti orilẹede naa ti gba ominira, o ti to igba mẹwaa ti wọn ti koju igbiyanju lati ditẹ gba ijọba.

Orilẹede Guinea Bissau ti fi ọpọ igba koju iṣoro airẹsẹ duro nipa oṣelu.

Ẹẹkan pere ni wọn ni aarẹ adiboyan nilana ijọba awa arawa to pari saa rẹ ri.