Ìdúró, ìjókòó tàbí kí ọkùnrin bẹ̀rẹ̀ tọ̀, èwo ló dára jù fún ìlera?

Ọpọlọpọ ọkunrin joko silẹ nigba ti awọn kan duro
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ko fẹrẹ wọpọ ninu awọn ọkunrin ti wọn maa n bẹrẹ, jokoo tabi loṣoo ti wọn ba fẹẹ tọ, ọpọ ọkunrin maa n duro tọ ni.

Ida perete awọn to maa n loṣoo tọ yii naa lo si saba maa n jẹ pe Musulumi ni wọn, ti wọn n tẹle ilana ti ẹsin Islam fi kọ wọn.

Ṣugbọn ninu ki ọkunrin duro, jokoo tabi bẹrẹ tọ, ewo lo daa ju fun ilera ni ibere to n jẹyọ ninu iroyin yii.

Bo si tilẹ jẹ pe ko si ibi kankan ti awọn eleto ilera ti fidi ẹ mulẹ, pe bibẹrẹ tabi jijoko sori awo ile igbọnsẹ tọ ni anfaani to n ṣe fun ara, sibẹ, ọpọ eeyan lo gba pe ilana yii lo mọ julọ ti eeyan ba fẹẹ tọ.

Idi eyi ni pe itọ ko ni i ṣan si ara ọkunrin to n tọ, ko si ni i ta sibi ti ko yẹ ko ta de. Ko ni i ko ẹgbin ba awọn nnkan bii burọọṣi ifọyin tawọn mi-in maa n tọju si ile iwẹ .

"Ko si ilana titọ kan to dara ju ikeji lọ, eyi ti kaluku ba fẹ lo n tẹle."

Dokita Mary Garthwaite, Aarẹ ẹka to n ri si ẹya ara ti eeyan fi n tọ ni UK lo sọ bẹẹ.

"Ìdúrótọ̀ ní ipa lórí ìtọ̀ tí yóò jáde àti bó ṣe máa sáré jáde tó"

Aworan ere ọmọdekunrin to n tọ ni iduro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iṣẹ iwadii kan ti wọn ṣe ni Leiden University, ni Netherlands, lọdun 2014, ṣe agbeyẹwo ọna ti ọkunrin ba gba tọ ṣe n ni ipa lara wọn, ati bi itọ ọhun yoo ṣe tete jade si.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wọn fẹnuko si pe bi ọkunrin ti isẹtọ ti ṣe ri ba jokoo lori awo ile igbọnsẹ to si tọ, o dara bẹẹ fun un ju ki o duro tọ lọ.

Eyi yoo jẹ ko tete ri itọ tọ, itọ naa yoo si tan ninu agbẹdu rẹ lasiko to n tọ, ko ni i sé tabi farapamọ sọhun-un.

Ṣugbọn fun awọn ọkunrin ti nnkan kan ko ṣe, wọn ni ko si iyatọ kan ninu iduro tabi ijokoo tọ fun wọn.

Wọn fi kun un pe idurotọ le mu ki atọ jade nigba ti ọkunrin ba n tọ, eyi ti ọpọ ọkunrin ki i fẹ ko ri bẹẹ.

Bakan naa ni wọn ni idurọtọ yoo tun mu ki awọn itọ kan ta si ilẹẹlẹ ibi ti ọkunrin ti duro tọ.

Ni 2023, YouGov ṣe iwadii kan lori ọna ti awọn ọkunrin n fẹran lati maa gba tọ lorilẹede mẹtala.

Iyatọ to gbooro ni wọn ri latọdọ awọn orilẹede ti wọn jọ wa ni kọntinẹnti kan naa.

Ida ogoji (40 percent) awọn ọkunrin Germany sọ pe awọn maa n jokoo bawọn ba fẹẹ tọ ni, ida mẹwaa pere lo ni awọn maa n duro tọ ni tawọn ni.

Ni UK, ida mẹsan-an (9%) lo n jokoo to, nigba ti ida mẹtalelọgbọn (33%) maa n duro tọ ni.

Eyi fi han pe bibẹrẹ tabi jokoo tọ wọpọ ni Germany, orukọ ti wọn maa n pe ọkunrin to ba n loṣoo tọ ni Sitzpinkler, eyi to tumọ so akọ ẹlẹdẹ.

Ni Brazil, wọn maa n sọ ọrọ kan pe obinrin ati ọpọlọ lo ni ibẹrẹ.

"Kò sí ẹ̀rí kan tó fi hàn pé àbùdá ọkùnrin ni láti dúró tọ̀"

Dokita Robert Dunbar, lati Yunifasit Oxford, jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa abuda eeyan.

O ni ki i ṣe abuda ni bawọn ọkunrin ṣe n duro tọ.

"Ko si ẹri kankan lati ara Iṣẹda eeyan to ṣalaye idi ti ọkunrin fi n duro tọ."

Dokita Dunbar lo sọ eyi.

"Ni ti ododo, ọ rọ awọn ọkunrin kan lọrun lati duro tọ, nigba ti awọn mi-in si maa n fẹ lati jokoo tabi bẹrẹ tọ."

Dokita Garthwaite lo ṣe afikun bẹẹ.

Nigba ti ko ti si imọran ilera lori ọna to yẹ ki ọkunrin gba tọ, awọn funra wọn ni wọn yoo maa yan eyi to ba wu wọn, to si rọ wọn lọrun.

Ṣugbọn bi o ba mu diduro tọ, yoo dara ki o ri i daju pe itọ ko ta sibi ti ko yẹ, o ko si jẹ ko gba ibi ti ko yẹ ko gba.

Jẹ ko lọ gbọọrọ sibi ti o n tọ si.