Ológun wọ́gilé èsì ìbò ààrẹ ní Guinea-Bissau lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba, kéde ọ̀gágun N'Tam gẹ́gẹ́ bí olórí, AU, ECOWAS fọnmú

- Author, Nicolas Negoce
- Author, Paul Njie
- Role, BBC Africa reporters
- Author, Natasha Booty
- Author, Wedaeli Chibelushi
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Wọ́n ti búra wọlé fún ọ̀gá ológun kan gẹ́gẹ́ bí olórí orílẹ̀ èdè lẹ́yìn tí àwọn ológun dìtẹ̀gbàjọba ní orílẹ̀ èdè náà.
Ọ̀gágun Horta N'Tam ni yóò ṣe ààrẹ fún ọdún kan lẹ́yìn tí wọ́n búra wọlé fun lọ́jọ́bọ̀ níbi ètò tó wáyé ní oríkò iléeṣẹ́ ológun orílẹ̀ èdè náà.
N'Tam tó jẹ́ pé òun ni olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò kó tó di pé wọ́n búra wọlé fun kò rẹ́rìn-ín gbogbo bí wọ́n ṣe ń búra wọlé fun.
Àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni ní Guinea-Bissau ló ti ṣáájú fẹ̀sùn kan Ààrẹ Umaro Sissoco Embaló tó ń kúrò lórí ipò wí pé ó mọ̀ọ́mọ̀ pè fún ìdìtẹ̀gbàjọba náà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ológun ni.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Wọ́n ní èyí jẹ́ ojúná láti ri pé èsì ìdìbò kò jáde nítorí tó fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò náà gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí àjọ Popular Front fi léde lọ́jọ́rú.
Bákan náà ni ẹni tó jẹ́ alátakò gbòógì sí ààrẹ, Fernando Dias náà fẹ̀sùn yìí kan náà kan ààrẹ Embaló.
Ṣùgbọ́n Embaló kò ì tíì fèsì sí gbogbo àwọn ẹ̀sùn yìí.
Ó ní òun borí ọ̀pọ̀ ìdìtẹ̀gbàjọba tí wọ́n gbèrò lé òun lórí láwọn ìgbà tí òun ti wà lórí ipò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ àmọ́ àwọn tó jẹ́ alátakò rẹ̀ sọ pé òun ló máa ń mọ̀ọ́mọ̀ gbé àwọn ìgbésẹ̀ náà láti dènà kíkojú àtakò.
Àwọn ológun tó gbàjọba ti wọ́gilé ètò ìdìbò tó wáyé náà, tí wọ́n sì ní àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò kò gbọdọ̀ gbé èsì ìbò kankan jáde.
Ikọ̀ ológun kan tí kò fẹ́ kí wọ́n dárúkọ òun sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn AFP pé Embaló wà ní àhámọ́ iléeṣẹ́ ológun tí wọ́n sì ń tọ́jú rẹ̀ dáadáa.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ̀gbàjọba náà, Ààrẹ àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Africa, Africa Union, Mahmoud Ali Youssouf pè fún ìtúsílẹ̀ Ààrẹ Embaló àti gbogbo àwọn aláṣẹ tó wà ní àhámọ́.
Bákan náà ló pè fún ìbọ̀wọ̀ fún ètò ìdìbò tó ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀ èdè náà.
Guinea-Bissau tó wà láàárín orílẹ̀ èdè Senegal àti Guinea jẹ́ orílẹ̀ èdè ìwọ̀ oòrùn Afrika tó gbajúmọ̀ fún ìwà gbígbé egbògi olóró, tí iléeṣẹ́ ológun rẹ̀ ti gbajúmọ̀ láti ìgbà tí wọ́n ti gba òmìnira lọ́dún 1974.
Láàárín àádọ́ta ọdún báyìí, Guinea-Bissau ti kojú ìgbèrò ìdìtẹ̀gbàjọba mẹ́sàn-án.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé yìí ni àwọn ológun kéde lọ́jọ́rú pé àwọn ti gbàjọba orílẹ̀ èdè náà.
Ṣáájú ni àwọn ológun tó gba ìjọba náà sọ fún BBC pé àwọn ti fi Embaló sí àhámọ́.
Níṣe ni ìró ìbọn ń dún lákọlákọ ṣùgbọ́n tí kò tètè yé ẹnikẹ́ni ohun tó ṣokùnfà ìbọn yínyìn náà tàbí bóyá ẹnikẹ́ni bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
Lẹ́yìn náà ni àwọn ológun ṣàfihàn ara wọn lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán pé àwọn ti wọ́gilé ètò ìdìbò ààrẹ tó wáyé ní orílẹ̀ èdè náà lọ́jọ́ Àìkú.
Wọ́n ní ìgbésẹ̀ náà wáyé láti dènà olóṣèlú kan tí wọn kò dárúkọ rẹ̀ tó ní àtìlẹyìn ẹni tó máa ń gbé egbògi olóró láti da orílẹ̀ èdè náà rú, tí wọ́n sì kéde títi gbogbo ẹnubodè tó wà orílẹ̀ èdè náà, tí wọ́n sì kéde kí onílé gbélé ni gbogbo alẹ́.
Ní ọjọ́bọ̀ ló yẹ kí èsì ìdìbò náà jáde – tí Embaló àti Dias sì ti ń kéde pé àwọn ni àwọn gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.
Dias ló ń rí àtìlẹyìn Olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀ èdè náà, Domingos Pereira, ẹni tí wọ́n yọ láti lè kópa íbi ètò ìdìbò náà.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́bọ̀ ni Embaló sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn France 24 pé wọ́n ti yọ òun nípò, tí ìjọba sì sọ fún BBS pé Dias, Pereira àti Botché Candé ti wà ní àhámọ́.
Nínú àtẹ̀jáde kan, àwọn olùbẹ̀wò ètò ìdìbò láti AU àti ECOWAS kọminú lórí bí wọ́n ṣe kéde ìdìtẹ̀gbàjọba orílẹ̀ èdè Guinea-Bissau.
Wọ́n ní níṣe ni àwọn èèyàn ti ń gbáradì fún èsì ìbò tí wọ́n ní ó lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀.
"Ó jẹ́ ohun tó yàwá lẹ́nu pé ìkéde ìdìtẹ̀gbàjọba yìí ń wáyé lẹ́yìn tí àjọ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìpàdé pẹ̀lú àwọn olùdíje méjì gbòógì níbi ètò ìdìbò náà, tí wọ́n sì ṣèlérí pé àwọn máa gba bí èsì ìdìbò náà bá ṣe lọ."
Portugal, tó jẹ́ orílẹ̀ èdè tó ṣe ìjọba amúnisìn níbẹ̀, ti pè fún pípadà sí ìjọba alágbádá, tí wọ́n sì ní kí gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ níbẹ̀ jáwọ́ nínú rẹ̀.
Nígbà tó máa fi di ọjọ́bọ̀, AFP jábọ̀ pé wọ́n ti ṣí àwọn ẹnubodè tó wọ orílẹ̀ èdè náà padà.
Embaló, ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́ta ló ń wá ìyànsípò fún sáà kejì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní òun kò ní wá ipò náà tẹ́lẹ̀.
Guinea-Bissau jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè tó tálákà jùlọ ní àgbáyé tí àpapọ̀ èèyàn tó wà níbẹ̀ kò ju mílíọ̀nù méjì lọ.
Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, Goodluck Jonathan ti padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn tó há sí orílẹ̀ èdè Guinea-Bissau látàrí báwọn ológun ṣe gbàjọba orílẹ̀ èdè náà.
Òun àtàwọn tí olórí àjọ AU àti Ecowas tí wọ́n jọ lọ ṣe àyẹ̀wò ètò ìdìbò náà ni wọ́n jọ padà sí Nàìjíríà.
Jonathan kọminú lórí báwọn ológun ṣe gbàjọba, tí ìjọba Nàìjíríà náà sì sọ pé ó jẹ́ ohun tó lòdì sí ìwé òfin.
Ṣáájú ni ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ti rọ ìjọba àpapọ̀ láti mọ bí wọ́n ṣe máa gbé Jonathan padà sílé látàrí bí àwọn ológun tó gbàjọba Guinea-Bissau ṣe kéde títi gbogbo ẹnubodè tó wọ orílẹ̀ edè náà yálà gbígba orí omi, ilẹ̀ tàbí òfurufú pa.

















