Wo onírúurú ikọ̀ agbésùnmọ̀mí, ajínigbé àti ẹlẹ́yàmẹ̀yà mẹ́sàn án tó ń da ètò àbò Naijiria rú

Agbebọn kan ninu nigbo nipinlẹ Zamfara
Àkọlé àwòrán, Inu igbo kijikiji ni ọpọ awọn agbebọn naa n gbe
    • Author, Chiagozie Nwonwu
    • Role, BBC Africa
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Lọwọ yii, iṣẹlẹ ijinigbe lo n fi Naijiria logbologbo amọ ọpọ iṣoro lo n koju orilẹede naa ni ẹka eto abo.

Lẹnu aipẹ yii ti Aarẹ Amẹrika, Donald Trump kede pe wọn n ṣekupa awọn ọmọlẹyin Kristi ti ijọba ko si bikitia tunbọ jẹ ki ọpọ oju wa lara orilẹede naa to tobi ju France ati Germany papọ lọ.

Oniruru ẹya bii 250 lo wa ni Naijiria, ti pupọ awọn to wa ni iha Ariwa jẹ Musulumi ti awọn to si wa ni iha guusu jẹ Kristẹni.

Lara awọn iṣoro orilẹede naa ni awọn ọdaran ajinigbe, awọn alakatakiti ẹsin, awọn to n fẹ yapa kuro lara Naijiria atawọn to n kọlu awọn agbẹ lori ilẹ wọn ni aringbungbun Naijiria.

Eyii ni atupalẹ awọn ẹgbẹ agbebọn to n da Naijiria ru atawọn ibi ti wọn ti n ṣọṣẹ:

Ẹgbẹ awọn ajinigbe ti ijọba n pe ni 'awọn janduku'

Pupọ ninu awọn to wa ninu ẹgbẹ yii ti wọn n pe ni janduku lo wa lati ẹya Fulani darandaran ti iṣẹ oojọ wọn jẹ sinsin maalu lati ibẹrẹpẹpẹ.

Pupọ ninu wọn ti fi iṣẹ ẹran sinsin silẹ fun ijinigbe pẹlu oniruru ohun ija oloro lọwọ wọn lati igba ti Aarẹ Muammar Gadaffi ti ṣubu ni Libya lọdun 2011.

Igbagbọ wa pe ohun ti wọn n ṣe ko lọwọ ẹsin ninu bikose bi wọn ṣe maa ji eeyan gbe ti wọn yoo si pa obitibiti owo wọle ni kiakia.

Alupupu ti wọn n lo fun wọn laaye lati le de awọn inu igbo ti ọkọ ko le de, awọn alupupu naa si n ran wọn lọwọ lati ṣọṣẹ lai fọtape.

Wọn ko ni olori kan pato amọ pupọ wọn ni wọn n korajo lati inu idile tabi ẹlẹgbẹjẹgbẹ.

Lọdun 2022, ọlọpaa gbe obititibiti owo kalẹ fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn ti irawọn tan lara wọn bii Ado Aleru ati Bello Turji, ijọba tun kede wọn bii ẹgbẹ agbesunmọmi.

Pupọ ninu awọn janduku yii lo ti n lo oju opo TikTok bayi lati 'buga' nipa awọn aṣeyọri wọn ninu ijinigbe ati iṣẹrubalu.

Boko Haram - Ẹgbẹ alakatakisi ẹsin Islam

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọdun 2014 ni irawọ Boko Haram tan kalẹ kari aye lẹyin ti wọn ji akẹkọọ Chibok ti ye wọn le ni 200 gbe nile ẹkọ wọn lọdun naa lọhun.

Ọdun 2002 ni ọkunrin kan to n jẹ Mohammed Yusuf da ẹgbẹ naa silẹ niluu Maiduguri.

Orukọ abisọ ẹgbẹ ọhun ni Jama'atu Ahlis Sunna Lidda'awati wal-Jihad, afojusun wọn si ni lati sọ Naijiria di orilẹ ẹsin kan ṣoṣo – Islam.

Gẹgẹ bii afojusun wọn, ẹṣẹ ni lilọ sile ẹkọ lati kawe amọ ọdun 2009 ni wọn di ẹgbẹ agbesunmọmi loju paali lẹyin ti ijọba ṣekupa Yusuf to jẹ olori wọn lẹyin ti ọlọpaa mu.

Labẹ adari wọn tuntun, Abubakar Shekau, Boko Haram gba ọpọ ilẹ ni iha ariwa, wọn si yan awọn 'emir' sibẹ lati maa ṣakoso rẹ.

Lẹyin awọn ọmọ Chibok, Boko Haram ti ji ọpọ obinrin ati ọmode gbe, ti wọn si fi pupọ awọn eeyan naa ṣe ẹru yatọ si pe wọn fi ipa ba wọn lopọ.

Lẹyin iku Shekau lọdun mẹrin sẹyin, Boko Haram ti pin si ẹgbẹ kekeke mii ti wọn si n wu iwa ọdaran kan naa.

Lara awọn ibi ti ẹgbẹ naa n kọlu julọ ni ile ijọsin awọn ọmọlẹyin Kristi, ile ẹkọ, mọṣalaṣi atawọn ilu kekeke.

Iswap - Ọkan lara ẹgbẹ to yapa kuro lara Boko Haram

Pupọ ninu awọn adari Boko Haram bii Abu Musab al-Barnawi ti igbagbọ wa pe oun ni ọmọ Mohammed Yusuf to da ẹgbẹ naa silẹ lo da ẹgbẹ Islamic State in West Africa Province (Iswap) silẹ lọdun 2016 lẹyin igbagbọ wọn pe Abubakar Shekau n ṣe si ofin Islam latari bo ṣe n pa awọn Musulumi.

Boko Haram maa n kọlu awọn Mọṣalaṣi ati ọja nigba ti Iswap n kọlu awọn ọmọ ogun ati ileeṣẹ ijọba.

Ede aiyede aarin wọn yii n mu ki wọn maa kọju ija sira wọn, koda wọn ṣi ba ara wọn ja lagbegbe Lake Chad ninu oṣu yii.

A gbọ pe asiko ija awọn mejeji ni Shekau pa ara rẹ pẹlu ado oloro to so mọ aṣọ ọrun rẹ.

Iswap ṣi n ṣọṣẹ titi di asiko yii to bẹẹ ti wọn fi gbẹmi ọgagun kan nileeṣẹ ologun Naijiria, Brig Gen Musa Uba lẹyin ti wọn dena de ikọ rẹ n Borno.

Ẹnu lọlọ yii ni ile ẹjọ sọ adari Iswap, Hussaini Ismaila si ẹwọn ogun ọdun fun ikọlu to ṣe lọdun 2012.

Igbagbọ wa pe ẹgbẹ naa lo tun kọlu ile ijọsin kan niluu Owo, nipinlẹ Ondo ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2022.

Amọ awọn agbẹjọro ijọba sọ pe awọn agbesunmọmi al-Shabab ni Somalia lo kọlu ile ijọsin naa.

Ansaru - Ẹgbẹ to yapa kuro lara Boko Haram

Ẹgbẹ yii ti kuro ni agbegbe ti Boko Haram ati Iswap ti n ṣọṣẹ.

Igbagbọ wa pe ẹgbẹ naa lo kọlu ọkọ reluwee kan to n rinrinajo lati Abuja si Kaduna lọdun 2022, nibi ti wọn ti pa eeyan meje, ti wọn tun ji awọn to le ni ọgọrun gbe lọ.

Ọwọ ọlọpaa tẹ olori wọn, Khalid al-Barnawi, o si n jẹjọ lori ipa to ko ninu ikọlu si ọọfisi ajọ UN niluu Abuja lọdun 2011 atawọn ikọlu mii.

Mahmuda - Ẹgbẹ to yapa kuro lara Boko Haram

Ẹgbẹ yii ti igbagbọ wa pe wọn yapa kuro lara Boko Haram ti korajọ si agbegbe Kainji Lake National Park lati ọdun 2020.

Pẹlu igbagbọ pe awọn naa ni ibaṣepọ pẹlu Islamic State, wọn maa n ṣe waasi fun awọn eeyan amọ ọrọ wọn ko lagbara to ti Boko Haram.

Ori alupupu lawọn naa ti maa n ṣọṣẹ lati kọlu awọn ọja atawọn fijilante to n ṣọ araalu ni Kwara.

Ninu oṣu Kẹrin ọdun yii, wọn kọlu awọn fijilante atawọn ọja kan nibi ti wọn ti pa ọpọ eeyan.

Lara awọn ibi ti wọn n kọlu julọ ni Kwara, Kebbi ati ipinlẹ Niger.

Afihan iye awọn ti agbesunmọmi ti pa ni Naijiria lati ọdun 2014 si ọdun 2025, gẹgẹ bii atẹjade Acled.

Lakurawa - Ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Islam

Ẹgbẹ ọhun to ṣẹṣẹ ko ara wọn jọ maa n kọlu Sokoto, Kebbi ati Niger.

Awọn alaṣẹ sọ pe wọn ni ibaṣepọ pẹlu ẹgbẹ agbesunmọmi mii ni orilẹede Mali ati Niger.

Lakọkọ, wọn ni awọn ni yoo maa daabo bo araalu lọwọ awọn agbebọn amọ naa ti n gbogun ti araalu bayii.

Lara nnkan ti wọn ṣe ni yiyẹ foonu araalu wo lati ri pe awọn orin to wa nibẹ wa ni ilana ẹsin Islam, wọn maa n na araalu to ba ṣẹ ni bulala, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ijọba kede wọn gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesunmọmi lẹyin ti wọn bẹrẹ ikọlu si awọn adari ilu, ijinigbe ati iji maalu.

JNIM - Ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Islam lagbegbe Sahel

Bo tilẹ jẹ pe Mali ati Burkina Faso ni wọn ti n ṣọṣẹ julọ, Nasr al-Islam wal Muslimin (JNIM) maa n ṣere wọ Naijiria lẹẹkọọkan.

Ẹgbẹ naa ṣe ikọlu ni aala Benin to sunmọ Naijiria lọdun 2025 amọ ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2025, wọn kọlu ipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti ji olujọsin to le ni ọgbọn lọ ni ṣọọṣi CAC Oke Isegun, Eruku.

Wọn sọ pe ikọlu naa ni akọkọ ikọlu wọn ninu Naijiria.

Ikọlu awọn darandaran ati awọn agbẹ - ija lori ilẹ

O ti pẹ ti ikọlu lemọlemọ ti n waye laarin awọn darandaran atawọn agbẹ ni aringbungbun Naijiria.

Pupọ awọn darandaran naa ni Musulumi nigba ti pupọ awọn agbẹ si jẹ ọmọlẹyin Kristi.

O ti pẹ ti awọn Fulani darandaran ti maa n ko ẹran wọn lati jẹ oko kaakiri amọ pẹlu ọlaju to de lode oni ati idagbasoke awujọ, eyii ti n ṣoro.

Awọn agbẹ n fẹsun kan awọn Fulani pe wọn n fi ẹranko wọn jẹ ere oko wọn wọn nigba ti awọn Fulani n sọ pe ti Oluwa ni ilẹ, awọn le lọ ibikibi to wa wu wọn lati fi ẹran jẹ oko.

Lara awọn ibi ti ikọlu awọn darandaran si awọn agbẹ ti n waye julọ ni ipinlẹ Plateau, Nasarawa, Benue ati Taraba.

Nigba mii ti Fulani ba kọlu awọn agbẹ, awọn agbẹ naa maa n gbẹsan, eyii ti ko jẹ ki ija ọhun tan nilẹ.

Ipob - ẹgbẹ to fẹ yapa kuro lara Naijiria

Lati nnkan bii ọgọta ọdun ṣeyin ti awọn kan ti n pe fun idasilẹ orilẹede Biafra ni ọrọ naa ti n ja nilẹ.

Ọrọ naa bẹrẹ lẹyin ti awọn ẹya Igbo sọ pe ijọba Naijiria n fi ọwọ rọ wọn sẹyin ninu eto iṣẹjọba, ipo adari ilu atawọn nnkan mii.

Ẹgbẹ Indigenous People of Biafra (Ipob), ti Nnamdi Kanu dari wọn lo n lewaju ninu ẹgbẹ to n pe fun iyapa naa.

Lọdun 2009, Kanu da redio Radio Biafra silẹ nibi to ti maa n sọrọ tako Naijiria to si maa n sọrọ gbe orilẹede Biafra lẹyin lati ilu London.

Nigba ti yoo di ọdun 2017, ijọba Naijiria kede Ipob gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesunmọmi latari bi awọn kan to jẹ alatilẹyin wọn ṣe n da ilu ru.

Ẹgbẹ Eastern Security Network (ESN), to jade lati ara ẹgbẹ naa n jo ile, wọn gbẹmi araalu bẹẹ ni wọn tun n da oniruru rogbodiyan silẹ.

Nipinlẹ Imo ati Anambra, ESN ri daju pupọ eeyan ni kii jade nile ni gbogbo ọjọ Aje, ẹni to ba jade yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

Fun ọpọ ọdun ni ẹgbẹ yii fi n gbẹmi awọn eeyan pataki nilẹ Igbo, ti wọn si n da ọrọ aje ru ni gbogbo ọjọ aje.

Ninu ọdun yii Simon Ekpa to jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Ipob ri ẹwọn he lori ẹsun igbesunmọmi ni Finland.

Lọsẹ to kọja ni Nnamdi Kanu naa ri ẹwọn gbere he ni Naijiria lori ẹsun igbesunmọmi yii kan naa.