Wo bí àwọn ajínigbé, oníjìbìtì ṣe lè fi síìmù ìpè rẹ fa ọ̀ràn sí ọ lọ́rùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nigba mi-in, ọrọ ti ko kan eeyan lọwọ lẹsẹ le di akoba si ni lọrun, ti ọ̀nà láti bọ ninu rẹ yoo si le gidi, paapaa to ba kan awọn nnkan ayelujara bii siimu ipe, email, Whatsapp ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Idi ni pe awọn eeyan kan wa ti wọn ko niṣẹ meji ju ki won maa kọwọ bọ oju opo ẹni ẹlẹni lọ.
Awọn wọnyi si le fi lu jibiti tabi ki wọn fi daran bii ipaniyan, ijinigbe ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bi iru eyi ba ṣẹlẹ, ẹni to ra oju opo naa pẹlu owo ara rẹ ni ọlọpaa yoo mu, yoo si ti jẹ kisa ninu ìyà ki wọn too fidi ododo mulẹ.
Iru iṣẹlẹ yii lo ṣẹlẹ si ọdọbinrin kan, Ibrahim Mariam Titilayo, to n sínru ilu niluu Akure, ipinlẹ Ondo.
Wọn fi siimu ipe ti Mariam ra loṣu Kẹrin 2025, ṣe akoba fun un, to si di ero atimọle lori ẹsun ijinigbe ati ipaniyan to ti ṣẹlẹ loṣu kin-in-ni ọdun 2024.
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Mariam?
Gẹgẹ bi Tope Temokun, agbẹjọrọ fun Mariam ṣe ṣalaye loju opo ayelujara rẹ, o ni ọjó kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa ọdun 2025 ni awọn ọlọpaa wa lati Abuja lati mu Mariam Titilayo to n sinru ilu l'Ondo.
Ẹka to n ri si itọpinpin iwa ọdaran ni wọn gbe e lọ, nibi ti wọn ti gba foonu rẹ: iPhone 12 pro max ati foonu kekere Itel silẹ lọwọ rẹ, pẹlu ikanni WiFi to fi n lo foonu naa.
O ni nibẹ ni wọn ti fi awọn nọmba ẹrọ ibanisọrọ kan han an, ti wọn ni awọn kan ti lo o fun ijinigbe ati ipaniyan loṣu Kin-in-ni ọdun 2024.
Ọlọpaa kan, Inspector Dauda Adamu, ṣalaye fun agunbanirọ naa pe nọmba kan wa to so mọ NIN rẹ, o ni nọmba naa wa lara eyi ti wọn lo fun iwa ọdaran yii.
Bo tilẹ jẹ pe ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin ọdun 2025 ni Mariam ra siimu Airtel rẹ ọhun, (bi ileeṣẹ naa ṣe fidi ẹ mulẹ), ti wọn si daran loṣu Kin-in-ni ọdun 2024, sibẹ, ọran wọle tọ ọ lati ibẹ lọ.
Temokun sọ pe wọn ti i mọle l'Àkúré lọjọ naa, wọn si ni ko tun wa si Abuja fun itẹsiwaju ẹjọ.
Ọmọbinrin naa paara Abuja, wọn si figba kan tun ṣe ayẹwo ti ko beere fun un nileewosan bi wọn ṣe sọ.
Lilọ bibọ, idaamu ọkan, fifi ọpọ akoko ṣofo ati bẹẹ bẹẹ lọ ni agunbanirọ naa koju ki wọn too yọnda rẹ laipẹ yii.
Agbẹjọro rẹ ni awọn yoo gbe igbesẹ ofin lori iṣẹlẹ yii, lati beere ẹtọ rẹ fun ifiyajẹni ti koju.

Oríṣun àwòrán, @Tope Temokun
Mọ́ nípa báwọn oníjìbìtì ṣe ń gba orí afẹ́fẹ̀ já ojú òpó èèyàn gbà

Ibi gbogbo ni a ti n ko adiẹ alẹ ni iwa ọdaran bii eyi, bakan naa lo n ṣẹlẹ lawọn ilẹ okeere, to ba ṣaa ti jẹ pe eeyan n lo awọn ikanni ayelujara.
Wọnyi ni irufẹ awọn iṣẹlẹ yii miran to n koju awọn eeyan lagbaaye, titi kan awọn ẹka ileeṣẹ kiri ati ọna ti wọn n gba ṣe iṣẹ naa.
Ki awọn onijibiti ori ayelujara deede gba oju opo ẹlomiran mọ ọ lọwọ n ṣẹlẹ daadaa lasiko yii, to ba si ṣẹlẹ si eeyan, ohun ti eeyan yoo ṣe si i gan-an le ma tete yeni.
Eeyan le foju fo o nigba mi-in, pe ko si ewu, ṣugbọn ewu wa.
Bi eeyan ba ti bọ sọwọ awọn to n gba oju opo mọni lọwọ, ẹni naa ti wa ninu ewu ki awọn ọdaran tun maa dọdẹ rẹ si i.
Obinrin kan, Sue Shore, ṣalaye fun BBC nipa bi awọn to n gba oju opo ẹni ẹlẹni ,ṣe fooro ẹmi rẹ- a si ri i pe loootọ ni pe gbogbo aṣiri nipa rẹ ni wọn ti tu si ori ayelujara.
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Sue?
Ọna jibiti kan ti a mọ si Sim swap attack ni wọn gba mu Sue - niṣe ni awọn onijibiti ori ayelujara yoo dọgbọn bii pe awọn ni awọn ni siimu ipe kan, awọn si fẹ gba tuntun si foonu awọn tuntun.
Wọn lo ilana yii lati gba awọn oju opo obinrin naa. Sue funra ẹ sọ pe ohun to buru gbaa lo ṣẹlẹ soun.
"Awọn onijibiti naa gba akoso oju opo Gmail mi, wọn tun wa ti oju opo asunwọn ikowosi mi ni banki pa, ohun to si fa iyen ni pe wọn kuna awọn ibeere kan to ni i ṣe pẹlu oju opo naa." Sue lo ṣalaye bẹẹ.
Sue tun ni kaadi kan to fi n ra ọja, to fi orukọ rẹ ṣi, awọn ọdaran naa si fi kaadi ọhun ra ọja to le ni £3,000 .
Niṣe ni obinrin yii n paara awọn ẹka rẹ lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ, bẹẹ lo tun lọ sọdọ awọn oloju opo foonu rẹ naa ki wọn too ba a ṣi awọn oju opo ti wọn ti gba mọ ọn lọwọ pada.
Aṣe awọn ole naa ko ti i pari iṣẹ pẹlu rẹ.
"Awọn ọdaran naa tun ṣe eyi to buru jai nigba ti wọn gba oju opo WhatsApp mi.
"Wọn fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si ẹgbẹ ẹlẹṣin ti mo wa, pe mo n kilọ pe awọn kan n bọ lati waa gun ẹṣin wọn lọbẹ."
A wa oju opo awọn onijibiti naa pẹlu awọn oju opo bii ''haveibeenpwned.com ati Constella Intelligence lati mọ boya ṣaaju ni wọn ti tọwọ bọ awọn nnkan aṣiri nipa Sue.
Nọmba ẹrọ ibanisọrọ rẹ, oju opo email, ọjọ ibi ati ile to n gbe ni wọn gbe sita loju opo tẹtẹ tita kan ti i ṣe PaddyPower, ni 2010 ati eyi ti wọn fi gbe email rẹ jade ni 2019, pẹlu awọn nnkan mi-in nipa obinrin naa.
Hannah Baumgaertner, lati ileeṣẹ ayelujara Silobreaker, sọ pe o ṣee ṣe kawọn onijibiti naa ti lo aṣiri obinrin yii ti wọn mọ tẹlẹ, fi ṣe ti Sim swap attack to tun koju.
"Nigba ti wọn ti le ni anfaani si nọmba ẹrọ ibanisọrọ Sue,lo jẹ ko ṣee ṣe fun wọn lati gba awọn nọmba ikọkọ ti wọn ba fi ranṣẹ si i lati fidi ẹni to ni oju opo Gmail naa mulẹ."
Wọ́n ja Netflix gbà
Kinni kan ni, ki i ṣe gbogbo igba ni awọn onijibiti yii maa n dọdẹ ibi ti wọn ti le ri owo nla.
Obinrin kan, Fran, lati Brazil, ṣalaye fun BBC pe ṣadeede loun ri i pe ẹnikan ti ja oju opo Netflix oun gba, o si ti ṣafikun iye ti oun maa n san loṣu fun lilo oju opo naa.
"Wọn ni ki n san $9.90 (£7.50) lori kaadi ti mo fi n sanwo, emi si kọ ni mo ni mo ra nnkan yii.
"Mo sare pe awọn ẹbi mi lati beere, boya ẹnikan ti fi kun ohun ti a n lo ni, ṣugbọn gbogbo wọn sọ pe awọn ko ṣe ohun to jọ bẹẹ."
Fran lo ṣalaye bẹẹ.
Iru eyi to ṣẹlẹ si Fran yii wọpọ pupọ, ẹnikan lo kan jokoo sibi kan pari iṣẹ oju opo Netfilx naa.
Ko sẹni to mọ bi wọn ṣe wọ oju opo rẹ, o si ṣoro lati mọ.
Ṣugbọn a ri i pe oju opo email Fran ti koju jibiti ni aaye mẹrin, o kere tan, titi kan hacks of Internet Archive (2024), Trellov (2024), Descomplica (2021) ati Wattpad (2020), gẹgẹ bi oju opo havibeenpwned.com. ṣe sọ.
Nọmba ikọkọ to lo fun oju opo Netflix naa ko si nigboro ti oju gbogbo ti le ri i, ṣugbọn o le wa nibo miran.
"Awọn oju opo Netflix ti wọn ti ja gba yii pọ, ti wọn n ta fun ẹlomi-in, bẹẹ ni Disney ati Spotify naa."
Alon Gal, ọkan lara awọn to da ileeṣẹ ayelujara Hudson Rock, silẹ lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Hudson Rock
Nigba miran ẹwẹ, awọn onijibiti maa n pa ohun ti wọn ji loju opo ẹni to ni opo naa pọ mọ ohun ti ẹni naa fi sita gangan.
Leah, ẹni ti ko fẹ da orukọ rẹ gangan, ni ile itaja kekere kan , o maa n lo ipolowo lori Facebook, laipẹ yii ni wọn da oju sọ ọ, awọn onijibiti naa n pitu lati Vietnam.
"Mo gba email ẹtan kan lati @facebookmail.com', wọn ni o yẹ ki n ti da owo pada. Mo tẹ oju opo naa, mo si fi awọn nnkan nipa mi soju ayederu opo Meta naa, bawọn onijibiti yẹn ṣe gba okoowo mi mọ mi lọwọ niyẹn, bo tilẹ jẹ pe mo ni 2 factor authentication to le da aabo bo mi.
"Wọn wa gbe awọn fidio to n fi ibi ti won ti n ba ọmọ kekere ṣe iṣekuṣe soju opo mi, labẹ orukọ mi, eyi ti mi o fi le wọle soju opo naa mọ. Wọn tilẹ tun fofin de mi, mi o le fi Messenger sọ ohun to ṣẹlẹ si mi fun Meta."
Laaarin ọjọ mẹta to gba Leah lati ri okoowo rẹ gba pada, awọn onijibiti naa ti fi orukọ rẹ ṣe ipolowo ọlọpọ owo Pounds. O pada ri owo naa gba.
Alberto Casares, lati Constella Intelligence, wa oju opo awọn onijibiti naa, o si ri email Leah ati awọn aṣiri ẹ miran ti wọn fi ọna eru mu, ni Gravatar (2020) ati ti ọdun yii, Qantas (third-party breach).
"O jọ pe awọn onijibiti naa lo ọna kan to kari lati fi wọle si oju opo, pẹlu nọmba okoowo rẹ to fi sita, ti wọn fi wọ email rẹ."
O ni wọn le da a ṣe funra wọn, wọn si le sanwo fun awọn ti wọn n ṣe iru iṣẹ yii lati ba wọn mu ẹni ti wọn n dọdẹ
Jìbìtì ọlọ́pọ̀ èèyàn
Ki wọn maa kọwọ bọ oju opo elomi-in yii n wọpọ si i kaakiri agbaye, pupọ rẹ lo si n ṣẹlẹ ni 2025 yii, pẹlu awọn ti oju opo wọn fẹsẹ mulẹ gidi.
- Eeyan 6.5 million lo padanu oju opo wọn loṣu Kẹrin.
- 5.7 lo kan ni ti Quantas airline hack.
Gẹgẹ bi Proton Mail ṣe wi, o ti to 794 jibiti oju opo ti wọn ti ri ni 2025, ti wọn si mọ ibi to ti wa, o si ti le ni ọọdunrun miliọnu (300 million) eeyan ti wọn ti tu aṣiri ikọkọ wọn sita.
"Awọn onijibiti maa n sanwo lori aṣiri alaṣiri ti wọn ba ji, nitori awọn naa yoo pada fi pa owo nla ni nipasẹ ipa ti wọn fi n gba owo lọwọ awọn to ba ko si wọn lọwọ" Eamonn Maguire lati ileeṣẹ naa lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Palo Alto Networks
Yatọ si fifi to awọn onibaara ati awọn eleto leti nipa iwa jibiti yii, ko si ofin kan to tọka ohun ti ileeṣẹ le ṣe fun awọn to ba ko sọwọ onijibiti.
Wọn le moju to o lọpọ igba nikan ṣaa.
Lọdun to kọja, Ticketmaster ( nibi ti eeyan 500m ti lugbadi jibiti, ṣeto sanwo diẹdiẹ lori ọja fun awọn to ṣẹlẹ si.
Ṣugbọn lọdun yii, ileeṣẹ perete lo n ṣe iru ẹ.
Marks and Spencer ati Qantas, fun apẹẹrẹ, ko tilẹ ti i da awọn onibaara wọn lohun.
Co-op ni tiẹ fun wọn ni iwe ti wọn le fi ra ọja £10 - bi wọn ba ti na to £40 ni ṣọọbu naa.
Awọn kan maa n lọ si kootu lati gba owo itanran, ṣugbọn iru ẹjọ bẹẹ ṣoro lari jare, nitori o ṣoro lati mọ bo ṣe nipa lara awọn to kan.
Ṣugbọn awọn kan ti jare ri ṣaa.
Ileeṣẹ T-Mobile bẹrẹ si i sanwo fun awọn onibaara to kan ni 2021, eyi to kan awọn eeyan 76m .
Ileeṣẹ naa gba lati san $350m - bẹrẹ lati $50 si $300.












