Ìgbà wo ní ìfẹnukonu kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀?

Àkójọpọ̀ àwọn ẹranko tó ń fi ẹnu kora wọn

Oríṣun àwòrán, Getty

Àkọlé àwòrán, The researchers found evidence of kissing in multiple species
    • Author, Victoria Gill
    • Role, Science correspondent, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ìfẹnukonu jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn, àwọn ẹranko tó fi mọ́ àwọn ọ̀bọ. Ní báyìí àwọn olùwádìí ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìwádìí nípa bí ìfẹnukonu ṣe bẹ̀rẹ̀.

Ìwádìí wọn fi hàn pé láti bíi ọdún mílíọ̀nù mọ́kànlélógún sẹ́yìn ni àṣà fífi ẹnu kora ẹni ti wà tó sì jẹ́ ohun tó gbajúmọ̀ láàárín ìran èèyàn àtàwọn ìran ọ̀bọ.

Ìwádìí náà tún sọ pé àwọn èèyàn tí wọ́n farajọ ẹranko farajọ èèyàn náà ṣeéṣe kí wọ́n fẹnuko ara wọn rí.

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe ìwádìí lórí ìfẹnukora ẹni lẹ́nu nítorí àwọn àdììtú kan tó wà lórí rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn tí wọ́n sì máa ń bá láàárín àwọn ẹranko náà.

Àwọn ọ̀bọ méjì tó ń fẹnukonu tí wọ́n sì dijú

Oríṣun àwòrán, Getty

Pẹ̀lú ẹ̀rí ohun tí wọ́n ṣàwárí nípa àwọn ẹranko míì tí àwọn náà máa ń fẹnukonu, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì wòye nípa bí ìfẹnukonu ṣe bẹ̀rẹ̀.

Nínú ìwádìí wọn tí wọ́n tẹ̀ síta nínú jọ́nà Evolution and Human Behaviour, wọ́n júwe ìfẹnukonu bíi ohun tí kò mú ìpalára dání, tó jẹ́ fífi itọ́ kan ara pẹ̀lú ètè àtàwọn ẹ̀yà ẹnu míì láì sí oúnjẹ níbẹ̀.

Àwọn èèyàn, ẹrank ọṣà àti bonobos ni wọ́n máa ń fi ẹnu kora gẹ́gẹ́ àlàyé Dókítà Matilda Brindle ti ilé ẹ̀kọ́ University of Oxford tó ṣáájú ìwádìí náà ṣe sọ.

"A lérò pé nǹkan bí ọdún mílíọ̀nù mọ́kànlélógún sẹ́yìn ni ìfẹnukonu ti wáyé láàárín àwọn ìnàkí."

Àwọn ìnàkí tó ń fẹnukonu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nínú ìwádìí yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rí ìwà ìfẹnukonu tó farajọ ti ìkoòkò, ajá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Wọ́n fi ìwádìí wọn sọrí ìnàkí láti ṣe ìwádìí wọn lórí bí èèyàn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ni fẹnukonu.

Ìwádìí náà tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn Neanderthal - tí ìrísí wọn farajọ ti èèyàn tí ìran wọn parẹ́ ní bíi ẹgbẹ̀rún ogójì sẹ́yìn – náà fẹnukonu.

Iṣẹ́ ìwádìí kan tó ti wáyé rí lórí àwọn Neanderthal ṣàfihàn pé àwọn èèyàn tó wà láyé lónìí àtàwọn Neanderthals jọ ní kòkòrò àìfojúrí kan tó máa ń wà nínú itọ́ èèyàn.

Dókítà Brindle ní èyí túmọ̀ sí pé ó ṣeéṣe kí wọ́n máa fi ẹnu kora fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí ẹ̀yà méjéèjì pín.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí yìí sọ orírun bí ìfẹnukonu ṣe bẹ̀rẹ̀, kò sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Ọ̀bọ méjì ń fẹnu ko ara wọn lórí igi

Oríṣun àwòrán, Getty

Onírúurú nǹkan ni àwọn èèyàn ti gbé jáde lórí èyí báwọn kan ṣe ní ó wáyé láti mọ ìlera ẹni tí èèyàn yóò jọ àṣepọ̀ pẹ̀lú ṣe le tó tàbí mọ bí wọ́n ṣe bara wọ mú si.

Dókítà Brindle ní òun gbèrò pé èyí máa lè ṣe okùnfà ìwádìí láti mọ ìdí tí ìfẹnukonu fi ń wáyé.

Ó ní ó ṣe pàtàkì láti mọ pé ìfẹnukonu jẹ́ ohun kan tí à ń ṣe tó farajọ ohun tí àwọn ohun abẹ̀mí tí kìí ṣe èèyàn náà ń ṣe.

"Kí a máa ṣe ìwádìí ìwà yìí, kí a kàn má máa ko dànù nítorí ó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ láàárín àwọn èèyàn.

Ọmọ Sumatran orangutan tó wà ní apá òsì ń fẹnukonu pẹ̀lú orangutan tó ti dàgbà tó wà ní apá ọ̀tún tí wọ́n sì jòkòó nínú igbó.

Oríṣun àwòrán, Chester Zoo

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀ àwọn ìnàkí ló máa ń fẹnukonu