Wo àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn fún ẹ̀sùn aṣemáṣe pẹ̀lù akẹ́kọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, Philipine Star
Eke ti dele aye tipẹ, gẹgẹ bi iṣekuṣe pẹlu awon akẹkọọ naa ṣe ti pẹ to ti n ṣẹlẹ laaarin awọn olukọ ile ẹkọ giga ati awọn akẹkọọbinrin to yẹ ki wọn kọ lẹkọọ gidi.
Lọpọ igba, ipa ni awọn olukọ ọkunrin naa maa n fi mu akẹkọọbinrin ti wọn ba da oju sọ lati ba ṣe aṣemaṣe.
Bi akẹkọọ naa ko ba gba, wọn yoo ri i pe ko yege ninu idanwo, eyi si maa n mu awọn akẹkọọ mi-in ṣe ohun ti wọn fẹ lai sọ fun ẹnikẹni.
Awọn kọọkan to ba ni igboya, ti wọn sọ ohun ti olukọ n daamu wọn fun lo maa n pada di ọran si lẹkṣọra bẹẹ lọrun.
UNICAL: Ọjọgbọn Cyril Ndifon, gbàdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún
Iru iṣẹlẹ yii to n ja ran-in lọwọ ni ti Ọjọgbọn kan ni Yunifasiti Calabar, Ọjogbon Cyril Ndifon, ti kootu ran lẹwọn ọdun marun-un bayii fun ẹsun aṣemasẹ kan naa.
Ọga ẹka imọ ofin tẹlẹ ni Ọjọgbọn Ndifon, ṣugbọn iwadii fi han pe o maa n fi ilọkulọ lọ awọn akẹkọọbinrin
Adajọ James Omotosho to gbọ ẹjọ rẹ laipẹ yii niluu Abuja, ri i pe Ọjọgbọn Ndifon jẹbi ẹsun meji ninu mẹrin ti wọn fi kan an.
Ajọ ICPC ati awọn ajọ mi-in naa tun fi ẹsun kan Ndifon.
Lasiko ti Ndifon wa nipo olori ẹka ofin ni Yunifasiti Calabar, ẹsun ti ICPC fi kan an ni pe o maa n beere fun fọto ihoho awọn akẹkọbinrin.
Wọn fẹsun kan an pe o beere fọto ihooho akẹkọọbinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni TKJ, o si tun ni ko gbe nnkan ọkunrin oun sẹnu.
Lẹyin ti wọn ri i pe o jẹbi, kootu ko fi aaye owo itanran silẹ fun Ọjọgbọn ti wọn ti figba pipẹ da duro nile ẹkọ naa.
Díẹ̀ lára àwọn olukọ ile ẹkọ giga ti iṣẹ ti bọ lọwọ wọn nitori ẹ̀sùn yìí:
- Ọmọwe Samuel Omoniyi Oladipo (UNILAG)
- Ọmọwe Boniface Igbeneghu (UNILAG)
Ikọ iroyin BBC Africa Eye lo tanna wa idi wọn ni 2019.
Wọn fidi ẹsun iṣekuṣe naa mulẹ, igbimọ fasiti yii si ri i pe bẹẹ lo ri.
Wọn kọkọ da wọn duro fun asiko iwadii naa, ki wọn too le wọn lọ pata lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un ọdun 2021.
- Ọjọgbọn Richard Akindele (O. A.U, 2018)
Monica Osagie ni ọmọbinrin naa to fẹsun ibeere fun ibalopọ kan Ọjọgbọn Richard Akindele, ti ẹka ẹkọ eto ati iṣiro ni Obafemi Awolowo University (O.A. U).
Igbimọ fasiti wadii ọrọ, wọn da Akindele duro.
Ajọ ICPC da si ọrọ naa, Akindele si gba idajọ ẹwọn ọdun meji, leyin to jẹwọ pe oun jẹbi.
- Ọmọwe Adebayo Mosobalaje (O. A. U, 2021)
Olukọ ẹka ede Gẹẹsi ni ọkunrin yii ni O.A U, bo tilẹ jẹ pe o taku pe oun ko jẹbi ẹsun iṣekuṣe pẹlu akẹkọọ, iṣẹ bọ lọwọ rẹ loṣu Kẹsan-an ọdun 2021.
- Ọmọwe Mohammed Idiagbon ( UNI ILORIN, 2016):
Fọnran ohun ti Ọmọwe Idiagbon, olori ẹka ede Gẹẹsi ni Uni Ilorin nigba naa ti n ba akẹkọọbinrin kan, Faith, tami oge lu sita.
Faith lọ sọdọ tiṣa naa lati ṣalaye nipa idanrawo ranpẹ, (test) ti ko ṣe, fọnran naa si ka ibi ti akẹkọọ yii ti n fi ede gẹẹsi sọ pe ' I don't like it', sita.
A gbọ pe nigba ti Ọmọwe Mohammed n fi ọwọ kan an nibi ti ko yẹ ni Faith bẹrẹ si i fi ede oyinbo sọ pe oun ko fẹ bẹẹ.
Ọrọ naa lo jẹ ki wọn ni ki olukọ yii lọọ rọọkun nile, o si pada kọwe fiṣẹ silẹ.
- Ọmọwe Solomon Olowookere (UNI ILORIN, 2019):
Akẹkọọ ọmọ ọdun mẹtadinlogun (17) ni wọn ni Ọmọwe Olowookere fipa ba lo pọ n'Ilorin.
Igbimọ oluwadii gba iṣẹ lọwọ rẹ lẹyin iwadii wọn.
Aba to de fifi ilọkulọ lọ akẹkọọ ti wa nilẹ nile igbimọ aṣofin orilẹede yii, nibi ti wọn ti pe fun ẹwọn ọdun marun-un si mẹrinla fun olukọ to ba tasẹ agẹẹrẹ si akẹkọọ.
Ṣugbọn aba naa ko ti i di ofin.














