A ní ìwé ilẹ̀ ìjọba, síbẹ̀, ìjọba Oyo fẹ́ lé wa lórí ilẹ̀ wá- Ọ̀kan lára àwọn tọ́rọ̀ kàn

Aworan awọn olufẹhonuhan lori ilẹ nipinlẹ Oyo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

‎Awọn olugbe agbegbe Alabata, olorisaoko, Amosun ati awọn olugbe agbegbe ogoji labẹ ijọba ibilẹ Akinyele lọ ti rọ Gomina Seyi Makinde ti Ipinlẹ Ọyọ lati mase fi katakata ijọba wo ile wọn lai ṣe wi pe ijọba mu adehun rẹ ṣe.

‎Awọn eeyan ọhun ni wọn gbe ọpọlọpọ takada dani, eyi ti wọn fi ṣe iwọde alaafia yika agbegbe Olorisaoko, ki wọn to pari rẹ si oju ọna opopona ilu Ibadan si Iseyin.

‎Ninu ọrọ rẹ, Olusoaguntan Samuel Omotunde Olaleye ṣalaye pe nisẹ ni ijọba Ipinlẹ Oyo n gba awọn sotun ati sosi nitori wi pe wọn ko fẹ mu ileri wọn ṣe.

‎Samuel Olaleye ṣalaye siwaju; "Ki ṣe wi pe ori ilẹ ijọba la kọle sii, ijọba fun wa ni iwe ilẹ ka to kọ ile wa, Erunmu ni ile iṣe reluwe wa tẹlẹ ki wọn to gbẹ wa si agbegbe wa, nitori ile iṣe reluwe, ni wọn ṣe gbe ile iṣe "Dry port" wa si agbegbe wa.

‎"A ko ba ijọba ja, ṣugbọn ki ijọba ma wo ile wa, ilẹ ti ko si wi pe wọn kọ kọ nkankan si ni ki ijọba lọ lọ, oun ta daye baa ni wi pe ijọba ma ń sọ igbẹ di igboro, ìjọba ki sọ igboro di ìgbẹ́.

"Olorisaoko, Alabata ati Ọpabunmi, Igboro ni wọn, wọn ki se inu igbo, ki wọn ma tu wa nilu, ki wọn si jẹ ko wa ni akosilẹ, ati ṣe ipade pẹlu aṣoju ijọba, o ti su wa"

‎Olanipekun Wasiu ṣalaye wi pe abule mẹtalelogoji lo wa ninu awọn ilu ti ijọba gbese le ilẹ wọn,

‎Wasiu ṣalaye "Ijọba kọ ti sọrọ kuna pẹlu wa papa julọ lori ọrọ ilẹ, ti ijọba baa fẹ lọ ilẹ, ati sọrọ lori ibiti wọn yoo ko awọn ti wọn wo ile won sì, ati sọrọ sisan owo gba mabinu.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎Nigbati ileeṣe reluwe bẹrẹ, won beere fun saari ile hectares ọgbọn (30)nigba to ya gomina ipinle Oyo Seyi Makinde ni ijọba Ipinlẹ Ọyọ nilo ilẹ ofi 1717,235 hectares Ile, ti wọn gba ni ọdun 2021, nigba ti o tun ya lari wi pe ijọba tun tii fee loju di ẹgbẹrun mẹta le die ilẹ ni ijọba tun gba.

‎Ijoba pin ile na si ọna mẹta ti ida kan yoo lọ fun awọn ti wọn fẹ wo ile wọn, sugbọn ohun ti a ri ni wi pe, ẹdun ọkan wa ti a ṣalaye fun ile ṣe ijoba lori ilẹ, ọtọ ni ọrọ ti wọn jise fun wa pada lati ọdọ gomina Ipinlẹ Ọyọ,

"A ko ni igbagbo ninu ileeṣe ijọba to ri si ilẹ, gbogbo ilẹ wa ni wọn ti taa tan ".

‎Nigbati o n ba akọroyin ileeṣe BBC Yoruba sọrọ, Iyaafin Mofoluke Adebiyi, ẹni ti o risi ileeṣe ijọba to risi ọrọ ilẹ, tẹnu bọrọ, "awọn ilẹ ti ijọba gba ni agbegbe ilu titun, ìjọba ko ti ṣe nkankan pẹlu enikeni lori ilẹ naa, a n igbiyanju lati mọ awọn ilẹ yẹn a si gbero lati san ọwọ gba mabinu fawọn ti wọn padanu awọn ilẹ ati ile.

‎"Ijoba ti bẹrẹ si ni baa awọn eeyan sọrọ, ati ṣe ipade pẹlu awọn tọrọ kan, ijọba si ma fun wọn ni owo gba mabinu, ki awọn eniyan wa ki wọn ní suuru,

"Awon ti ijọba baa gba ilẹ wọn ni a fẹ ní kí wọn ni suuru nitori gbogbo eniyan ni yoo jẹ anfaani rẹ ti idagbasoke baa ba awọn agbegbe yii".

‎Mofoluke ṣeleri lati pe ipade alaafia pẹlu awọn tí ọrọ ọhun kan ki igun mejeji le gbọ ara wọn yee.