Wo bí obìnrin tí kò ní ilé ọmọ ṣe di ọlọ́mọ láyé nípasẹ̀ ọ̀rẹ́

Georgia gbe ọmọ ikoko dani pẹlu Daisy

Oríṣun àwòrán, Georgia Barrington

Àkọlé àwòrán, Daisy lo ba Georgia bi ọmọ rẹ, Ottilie, loṣu Kẹwaa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Obinrin kan, Georgia Barrington, ṣẹṣẹ di iya ọmọ ikoko obinrin kan ni, ṣugbọn oun funra rẹ kọ lo bi ọmọ naa bi obinrin ṣe n loyun bimọ. Kaka bẹẹ, ọrẹ rẹ timọtimọ Daisy Hope, lo ba a gbe oyun ọmọ naa, o fi mu ileri to ṣe fun Georgia nigba ti wọn wa lọmọge ṣẹ.

Bi igbin fa ikarahun a tẹle e ni ọrọ awọn obinrin meji yii. Orukọ ti wọn maa n pe ara wọn ni tẹgbọn-taburo to ni ẹmi kan naa.

Ibaṣepọ wọn yii naa lo pada di ohun ti ẹnikan fi aanu ṣe oore fun ikeji rẹ.

Nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹẹẹdogun, awọn dokita sọ ohun ti ọmọbinrin ki i fẹ gbọ fun Georgia- Ohun ti wọn sọ fun un naa ni pe ko ni ile ọmọ lati ọrun wa, wọn ni ko ni i bimọ laye rẹ, nitori ko ni ile ọmọ.

Arun ti wọn lo n ṣe Georgia ni Mayer-Rokitansky-Küster-Hauser (MRKH) syndrome, o si maa n ṣe ẹyọkan ninu ẹgbẹrun marun-un obinrin, fun Georgia ni tiẹ, niṣe lo jọ pe ko si ireti kankan fun un laye mọ nigba to gbọ ohun to n ṣe e naa.

" O ba mi lọkan jẹ, bii pe aye mi ti tuka yanga ni. Emi ti mo ti maa n ro o pe emi naa yoo di ọlomọ nigba ti mo ba dagba, o si di ohun ti ko le ṣee ṣe niṣoju mi, gbogbo ala mi parẹ mọ mi ninu."

Bẹẹ ni Georgia ṣalaye nigba to ranti iṣoro aye rẹ to ti pada waa di ayọ bayii.

Awọn ẹbi rẹ ran an lọwọ lati ṣalaye ohun ti wọn lo n ṣe e fun un, wọn si mu ọkan rẹ le gẹgẹ bii ọrẹ rẹ, Daisy Hope naa ṣe ṣe fun .

Daisy maa n ronu nipa bi ọrẹ rẹ to fẹran ọmọ ko ṣe ni i bimọ laye, o si maa n ro o pe ko yẹ ko ri bẹẹ.

"Mi o fẹ ko o maa banujẹ, mo si maa n fun un ni ọrọ itunu pe ohun to n ṣe e ki i ṣe opin aye rẹ. Mo sọ fun un pe mo maa ba a gbe ọmọ rẹ sinu mi lọjọ kan."

Daisy lo ṣalaye bẹẹ lori eto kan, Ready to Talk, eyi ti Emma Barnett jẹ atọkun rẹ.

"Emi gan-an ko ro pe ohun ti mo n ṣeleri ẹ nigba naa ye mi, ṣugbọn mo mọ pe ohun ti mo maa pada ṣe fun Georgia ni."

Georgia ati Daisy nigba ti wọn wa lọmọde

Oríṣun àwòrán, Georgia Barrington

Àkọlé àwòrán, Lati kekere ni Georgia ati Daisy ti jẹ ọrẹminu, wọn si jọ dagba papọ ni.

Ìgbìyànjú oyún bẹ̀rẹ̀ fún Georgia pẹ̀lù ìrètì

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti ọdun mẹwaa yoo fi kọja, Daisy bẹrẹ igbesẹ bi ileri rẹ yoo ṣe wa si imuṣẹ, nigba to si di 2023, awọn mejeeji bẹrẹ eto ilana ọmọ bibi ti i ṣe IVF.

Iṣẹ olugbẹbi ni Georgia lọ fun nile ẹkọ, o n ri i bawọn abiamọ ṣe n bimọ, ṣugbọn oun funra rẹ ko le ba ọlọmọ pe.

"Ẹnikan ti beere lọwọ mi ri, pe ṣe mo si ro pe iṣẹ to yẹ mi ni mo yan laayo yii, ṣugbọn ni ti ododo, iṣẹ yii ran mi lọwọ lati mu ọgbẹ ọkan mi san, mo mọ pe emi naa ṣaa ni ọmọ lọna kan abi omiran ti mo ba wa lawujọ awọn to n bimọ."

Bẹẹ ni Georgia ṣalaye.

Lẹyin ọdun diẹ si i, Daisy bimọ akọkọ ni tiẹ, Georgia lo si gba ẹbi fun un - bi Daisy ṣe di ọlọmọ ni tiẹ tun jẹ ki ọkan rẹ fẹ lati mu ileri to ṣe fun ọrẹ rẹ ṣẹ.

"Ifẹ ti mo ni si ọmọ mi ko ṣee fi ẹnu ṣalaye, mo si lero pe gbogbo eeyan lo yẹ ko le ni iru ifẹ bẹẹ si ọmọ ti wọn ba bi, mo fẹ ki gbogbo eeyan ni iriri iru ifẹ yẹn."

Daisi lo ṣalaye bẹẹ.

Loootọ, o ni oun ti ro pe bi oun ṣe loyun ọmọ oun nirọrun ni ti IVF toun fẹ ba Georgia ṣe naa yoo ri, ṣugbọn ẹni to ba debẹ lo le sọ.

'Ìrètì dòfo

Eto IVF naa bẹrẹ, Daisy loyun nilana to fẹ lo fun ọrẹ rẹ lati di ọlọmọ, o si jọ pe gbogbo ẹ n lọ letoleto bi wọn ṣe ro.

Ṣugbọn nigba ti wọn ṣe ayẹwo oyun naa lọsẹ meji, niṣe lo han pe ko si nnkan kan nibẹ. Ko soyun, ko sọmọ.

Georgia loun ranti igba ti nọọsi to ṣe ayẹwo naa sọ pe oun ko ri nnkan kan nibi ti wọn n ro pe oyun wa.

"Irẹwẹsi mu mi, gbogbo ireti mi si dofo."

"Mi o ri iru ibanujẹ to to bẹẹ yẹn ri laye mi, mo si bẹrẹ si i ronu pe emi ni mo fa a." Daisi lo ṣalaye bayii, nigba ti ai si oyun ninu rẹ naa han si i kedere .

Georgia ni tiẹ ko tete mọ ohun ti yoo tiẹ sọ si ohun to ṣẹlẹ naa, niṣe ni ireti rẹ dofo.

Nigba ti wọn yoo tun fidi ai si oyun ninu Daisy naa mulẹ si i fun wọn, osẹ kan lẹyin ayewo akọkọ ni wọn fidi ẹ mulẹ pe ọlẹ ti wọn gbe sinu Daisi ko di ọmọ.

Ṣugbọn wọn ko dakẹ iyanju, wọn gbiyanju lẹẹkan si i.

Ẹlẹẹkeji yii ni Daisy ti sọ pe : "Nigba ti mo loyun ikeji, mo ro o lokan mi pe eyi ko tun ni i da bii ti akọkọ, aye ko le buru si wa bii ti akọkọ mọ."

Georgia ati Daisy

Oríṣun àwòrán, Georgia Barrington

Àkọlé àwòrán, Daisy sọ pe latilẹ loun ti mọ pe oun yoo ba Georgia gbe oyun lọjọ kan.

Oyun padà d'ọmọ

Ọsẹ kẹfa lẹyin eyi, awọn mejeeji tun lọ ṣe ayẹwo, wọn n reti esi ayọ pẹlu ikayasoke.

Bẹẹ ni kinni kekere kan han loju ibi ti wọn ti n wo ọlẹ inu Daisy, o jọ pe oyun ọtẹ yii ti duro.

Ṣugbọn ki ilẹ ọjọ naa too ṣu, Daisy bẹrẹ si i ri ẹjẹ, ẹjẹ naa si pọ gan-an.

"Niṣe ni mo ro pe ohun to ṣẹlẹ lakọkọ tun ti n ṣẹlẹ lẹẹkeji ni, ẹru si ba mi gidi." Daisi lo sọ bẹẹ.

Wakati mẹfa lo fi ri ẹjẹ naa, o si ti ro pe oyun ọhun ti walẹ ni, ṣugbọn nigba ti awọn dokita ṣe ayẹwo, ọmọ ṣi wa nibẹ to n mi.

Bẹẹ lo si ṣe ti oyun naa bẹrẹ si i dagba to fi pe asiko ti yoo waye .

Igba ti wọn n fọkan si pe Daisy yoo tilẹ bimọ ko ti i to to fi bi i, o ya diẹ si asiko naa, ṣugbọn o bi i layọ ati alaafia, ọmọ ọbinrin.

Inu Georgia dun kọja alaye, ko tilẹ ranti wo iru ọmọ ti ọrẹ rẹ ba a bi, boya ọkunrin ni tabi obinrin.

"Bi mo ṣe ri ori ọmọ naa bayii to n jade bọ, mo bẹrẹ si i sunkun ni, gbogbo wa la n sunkun." Geogia lo sọ bẹẹ.

O ni o ṣi n da bii ala loju oun ni, pe oun naa ti di ọlọmọ niyẹn.

O ni oun ranti igba toun wa lọmọ ọdun mẹẹẹdogun ti wọn ni oun ko le bimọ laye. Bii koun da asiko ti ọmọ de yii pọ mọ ọdun naa lọhun-un, ti wọn sọ foun nibi ayẹwo GP surgery pe oun ko le lọmọ laye lo ri.

Bi Georgia ṣe n sọ pe ori oun sọ ire to si n dupẹ lọwọ ọrẹ rẹ, bẹẹ ni Daisy naa n sọ pe oun ti mọ pe oun yoo ran ọrẹ oun pataki yii lọwọ lati di ọlọmọ laye, labẹ bo ti wu ko ri.

" Ọrẹ tiwa kuro ni eyi ti ẹnikẹni le ri iru rẹ , nitori a ti la ohun to jẹ awa nikan la ṣe e funra wa kọja."

Daisy lo ṣalaye bayii, bo ṣe n sọ pe ọrẹ tawọn ko ṣee fi owo wọ.