Láti ìgbà tí wọ́n ti jí Ọba wa gbé lọ, ọlọ́pàá kò dá sí wa, àwa nìkan là ń sá kiri, ìjọba Kwara, ẹ gbà wá – Mọ̀lẹ̀bí Ọba tí wọ́n jí gbé

Oríṣun àwòrán, Buhari Ọlatunde
Awọn mọlẹbi ọba kan ti wọn ji gbe nipinlẹ Kwara, Alhaji Kamilu Salami, to jẹ Ojibara ti ilu Bayangan, nijọba ibilẹ Ifelodun ti ke gbajare si ijọba ipinlẹ naa fun iranlọwọ lati doola ori ade ọhun pada.
Ninu atẹajade kan ti mọlẹbi kabiesi, eyii ti agbẹnusọ rẹ, Alhaji Rafiu Ayinla Lawal fi lede ni wọn ti rawọn ẹbẹ ọhun.
Atẹjade naa sọ pe lati igba ti awọn agbesunmọmi ti ji ọba naa gbe, ọlọpaa ko sọ nnkankan nipa rẹ mọ, bẹẹ ni ko ran awọn lọwọ lati doola rẹ, awọn nikan ni wọn n sa kiri.
Mọlẹbi ọba naa sọ pe lati ọjọ kọkandinlọgbọn ti wọn ti ji ọba naa gbe ni ọkan gbogbo ilu wọn ko ti balẹ mọ.
Wọn tun fẹsun kan ọlọpaa pe lati igba ti awọn ti n ṣe wahala lati ri ọba ọhun pada ọlọpaa "ko sọ nnkankan nipa rẹ bẹẹ ni ko maa bun araalu gbọ" nipa bi ọrọ naa ṣe n lọ.
Gẹgẹ bii oun ti Lawal sọ, niṣe lo da bii igba ti ọlọpaa ti gbagbe Ojibara si ahamọ ajinigbe ti ko si bikita nipa boya wọn tu silẹ tabi wọn ko tu silẹ.
Wọn ni "o ṣe pataki lati sọ lasiko yii pe mọlẹbi kabiesi nikan lo n ṣe wahala lati ri pe o bọ lọwọ awọn janduku naa.
"Nitori naa a fi tọwọtọwọ bẹ ijọba ipinlẹ Kwara ko dide fun iranlọwọ wa.
"Ilu nikan ko le danikan gbe ẹru yii, a nilo iranlọwọ ijọba ipinlẹ lati kun wa lọwọ lori igbiyanju wa."
Mọlẹbi ọba naa tun bẹ awọn agbofinro fun iranlọwọ, wọn tun rọ wọn ki wọn maa kede faraye ibi ti wọn ba ṣiṣẹ de lori igbiyanju ati doola ori ade naa.
Wọn pari atẹjade naa pẹlu igbagbọ pe Ojibara yoo pade wale pẹlu iranlọwọ ọlọpaa ati ijọba ipinẹ Kwara.
Alaye ree lori bi wọn se ji Ọba Ojibara ti ilu Bayangan, Alhaji Kamilu Salami gbe lọ ninu oko rẹ
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn ajinigbe kan tun kọlu agbegbe Bayangan nijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara, ti wọn si ji Ori Ade ilu naa gbe lọ.
Nnkan bi ago mẹsan an abọ owurọ ọjọ Satide ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti Oba, Ojibara ti ilu Bayangan, Alhaji Kamilu Salami wa ninu oko rẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Buhari Ọlatunde to jẹ ọmọ agbegbe naa sọ pe, awọn Ọba alaye to ku ni ìjọba ibilẹ Ifẹlodun ti n se ipade lati jiroro lori igbesẹ ti wọn yoo gbe lori iṣẹlẹ naa.
Ọgbẹni Ọlatunde tẹsiwaju pe awọn ajinigbe naa ti kan si mọlẹbi kabiyesi, ti wọn si n beere fun aadọjọ miliọnu naira, owo itusilẹ ki wọn to yọnda Ọba alaye naa.
Lasiko to n akọroyin BBC Yoruba sọrọ, kansilọ to n soju ilu Bayangan nijọba ibilẹ Ifẹlodun, Hon. Quadri Ọlaitan sọ pe, kabiyesi wa ninu oko pẹlu awọn ọmọ isẹ rẹ lasiko ti awọn ajinigbe yabo wọn .
Hon. Quadri ni, awọn ajinigbe naa ti pe, ti wọn si bere fun aadọjọ miliọnu naira.
"Pẹlu alaye pe, wọn tun ti pe ni irọlẹ ana ti wọn din owo itusilẹ naa ku si ọgọrun kan million naira."
Hon. Quadri ni gbogbo ilu naa n sa sokesodo ni bayii lati wa ọna ti wọn fẹ gbe ọrọ owo naa gba.
O fikun pe, awọn ọdẹ ilu naa ti wọ inu igbo lọ lati ọjọ Ṣatide ti iṣẹlẹ naa ti waye, sugbon wọn o ko ti ri kabiyesi, Ọba Ojibara ilu Bayangan, Alhaji Kamilu Salami.
Akọroyin wa kan si Alukoro Ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyemi Toun ṣugbọn titi di asiko yii, ko gbe ipe wa lati sọrọ lori iṣẹlẹ naa.
Hon Quadri Ọlaitan tun ba BBC Yoruba sọrọ ni owurọ onii, to si tun fidi rẹ mulẹ pe wọn ko ti ri Ori Ade ọhun.
Lori awuyewuye boya wọn ti yọnda kabiesi, Hon Qudri Ọlaitan ni irọ to jina si otitọ ni.















