'Ifá kọ́ la fi n yan Awujale ilẹ̀ Ìjẹ̀bú, bá ṣe n ṣe rèé'

Aworan Awujale Adetone

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọjọ Aiku, ọjọ kọkanla oṣu Keje, ọdun 2025 ni Awujalẹ, Oba Sikiru Kayode Adetona darapọ mọ awọn babanla rẹ ti ọpọ eeyan kaakiiri agbaye si ṣedaro ori adẹ ọhun.

Ọdun 1960 ni Ọba Adetona jẹ Awujalẹ gbogbo ilẹ Ijẹbu.

Ni bayii ti ori itẹ naa ti ṣofo bayii, ọpọ ọmọ oye lo n gbero lati kopa ninu idije lati jẹ ọba.

Bi o tilẹ jẹ pe, ọpọ awọn ọmọ Ijebu ni ko ti ni anfaani lati mọ ilana ọba jijẹ nitori igba pipẹ ti Oba Adetona fi wani ipo naa.

Awọn olori idile ọba to kan lasiko yii ti bẹrẹ jiroro lori ọmọ oye ti wọn yoo fa kalẹ bi eto oye oba jijẹ ṣe ti bẹrẹ bayii.

BBC News Yoruba kan si Bagbimọ Akile Ijebu, Oloye Fassy Yusuf lati tan imọlẹ si bi oye ọba jijẹ ṣe ma n waye nilẹ Ijẹbu.

O ni eto oye oba jijẹ to fẹ waye lasiko yii nii yoo waye ni ilana oye ọba jijẹ ti ọdun 1957.

Oloye Yusuf ni, ọpọ iroyin ofege lo ti n lọ kiri nipa ipo ọba jijẹ nilẹ Ijebu paapa bi awọn kan ṣe n lọ kiri lati ṣapejuwe ara wọn gẹgẹ bii Adele.

Gẹgẹ bii oloye ati agbẹnusọ fun Awujale to waja, o ṣalaye awọn igbesẹ ti yoo waye ṣaaju eto ọba jijẹ

Yusuf fi di rẹ mulẹ pe idile mẹrin lo n jẹ ọba niluu Ijebu, Gbelegbuwa, Anikinaiya, Fusengbuwa, ati Fidipote.

"Pẹlu ilana yii, idile Fusengbuwa ni oye Awujale kan lati jẹ.

"Idile Anikinaiya ni Oba Adetona to waja ti wa, to si jẹ Fusengbuwa lo kan lati di Awujalẹ."

Ki ni yoo sẹlẹ ti Oba ba waja niluu Ijebu Ode?

Yusuf ni ohun akọkọ ti awọn afọbajẹ yoo ṣe lasiko ti Awujalẹ Ijẹbu ba waja ni pe ki wọn yan Adele Oba ti yoo dele de ọba tuntun.

"Ti Oba ba ti waja niluu Ijebu Ode, a o yan adele ti yoo dele de Awujale, ti Olisa tabi Ọgbẹni Ọja yoo si jẹ olori awọn Adele Oba.

"Lẹyin eyi ni akọwe ijọba yoo kọ lẹta si ẹbi ti o kan lati pese Awujale.

"Lẹyin ti a kọ lẹta, ni Ẹbi yoo jokoo, ti wọn yoo si ṣe idanwo fun awọn to fi ifẹ han si ipo. Abajade idanwo naa ni wọn o jabọ fun Ọgbẹni Odi, iransẹ ọba, lati fi jisẹ fun awọn afọbajẹ.

"Awọn afọbajẹ ni Olisa, Ogbeni-Oja, Egbo, Apebi, Olotufore, Olotu-Olowa, Ogbeni-Odi-Imesi, Ekeji-Odi-Iletu, Oliwo, Agbon, Kakanfo, Lapoekun ati Balogun ti Ijebu-Ode.

"Awọn mẹsan an lo wa bayii, ti wọn yoo si jiroro lori eeyan ti wọn ba mu. Awọn ni yoo fi orukọ ẹni ti wọn ba mu ranṣẹ si ijọba.

"Ijọba ni yoo kede ẹni ti yoo jẹ ọba, ti ipebi yoo si bẹrẹ ṣaaju ki wọn to gbe ade si ọba lori."

Ṣe lootọ ni pe Ifa lo ma n yan Awujale?

Baagbimọ Ijebu Ode, ẹni to tun jẹ agbẹnusọ fun Oba Sikiru Adetona to ti waja ṣalaye pe ko si nnkan to jẹ mọ pe ifa ni wọn ma n fi yan Awujale ni Ijebu-Ode.

"Ni ilẹ Ijebu Ode, ko si ninu iwe pe ka kan si ifa.

"Igbesẹ yii ni mo ti ṣalaye fun yin, o wa ninu eto oye oba jijẹ ti 1957 ati 2006 ijọba Ogun naa tẹlẹ.

"Boya awọn ẹbi wa a le lo ifa lati mọ ẹni to tọ si."

Ṣe Adele ti wa bayii niluu Ijebu Ode?

Oloye Fassy Yusuf ni bayii ko si ẹnikẹni to n dele fun Awujale ṣugbọn ijọba yoo kede igbimọ Adele naa nitori ki se eeyan kan lo ma n jẹ.

"Lẹyin ọjọ mẹjọ ti a fi ṣe idarọ Awujale to lọ ni ijọba yoo kede awọn Adele, eyi yoo si waye titi ọjọ Aje to n bọ."

Taa ni Ọba Sikiru Olukayode Adetona?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kẹwaa oṣu Karun un, ọdun 1934 ni wọn bi Ọba Sikiru Olukayode Adetona, gẹgẹ bi Arẹmọ ni agboole ọba Ogbaagba.

O lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ Baptist School, Ereko, Ijebu Ode, Ogbere United Primary School, Oke Agbo, Ijebu Igbo, ati Ansar-Ud-Deen School, Ijebu Ode laarin ọdun1943 si1950.

Ile ẹkọ Olu-Iwa (to ti di Adeola Odutola) College, Ijebu Ode lo ti ka ẹkọ girama laarin ọdun 1951 si 1956. Lọdun 1957 si 1958, Arẹmọ Adetona ṣiṣẹ ni ẹka oluwadii owo nileeṣẹ ijọba Western Region, niluu Ibadan, ko to o di pe o kọwe fi iṣẹ silẹ lati lọ kẹkọọ nipa iṣiro owo ni orilẹede United Kigdom.

Ọjọ kẹrin oṣu Kini, ọdun 1960 ni ijọba Western Region kede iyansipo rẹ gẹgẹ bi Awujale tuntun, to si gba ọpa aṣẹ lọjọ kejidinlogun oṣu Kini ọdun naa. Amọ o, ọjọ keji oṣu Kẹrin lo to o gba ade ti wọn si ṣe iwuye lẹyin to ti ṣe awọn etutu oye tan.

Ọba Adetona ni ọba ilẹ Yoruba to ti i pẹ julọ lori itẹ lati bi ọpọ ọdun sẹyin.

Ṣaaju ko to jọba, awọn marun un mii ni wọn jọ dije dupo gẹgẹ bi ọmọ oye, amọ oun ni awọn afọbajẹ dibo fun ni ibamu pẹlu abala ofin kọkanla to wa fun ọrọ oye jijẹ ni Western Region lọdun 1957.

Gomina igba naa fọwọ si nnkan ti awọn afọbajẹ fẹ, eyi to sọ ọ di ọba titi di akoko iku rẹ.