Wo ìdí tí àwọn POS tí kò bá fi orúkọ sílẹ̀ yóò ṣe kan ìjàngbọ̀n lọ́dọ̀ CBN àti bó ṣe kàn Opay àti Moniepoint

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ri si iforukọsilẹ awọn ileeṣẹ ni Naijiria, Corporate Affairs Commission (CAC), ti kede pe oun yo bẹrẹ si n da seria fun awọn to n ṣe PoS lia forukọsilẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2026.
Ninu atẹjade kan ni CAC ti sọ pe iwuwasi awọn oni PoS ti ko forukọsilẹ lodi si ofin dida ileeṣẹ silẹ ti ọdun 2020 ati eto paṣipaarọ owo banki apapọ CBN.
Atẹjade naa ni "iwa aibikita yii ti awọn banki ori ayelujara kan gba laaye n fi owo awọn araalu sinu ewu. Opin si gbọdọ de ba."
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ko si PoS kankan ti awọn yoo gba laaye lati maa ṣiṣẹ lai kọkọ forukọ silẹ pẹlu CAC, awọn agbofinro yoo si bẹrẹ iṣẹ lori eyii kaakiri Naijiria.
CAC ni "gbogbo oni PoS ti ko ba forukọsilẹ ni a maa gbẹsẹle.
"Bẹẹ naa ni a o maa ṣọ gbogbo awọn banki ori ayelujara to n gba awọn eeyan laaye lati maa ṣiṣẹ lai forukọsilẹ lojulẹsẹ ki a le fi ẹjọ wọn sun CBN.
Ajọ naa rọ gbogbo awọn to n ṣe PoS atawọn to n lo ẹrọ naa ki wọn bẹrẹ iforukọsilẹ ni kia lai fi akoko ṣofo.
Ṣaaju asiko yii ni CAC ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣe iforukọsilẹ awọn oni PoS kaakiri Naijiria bẹrẹ lati ọdun 2024 nigba to rọ awọn banki ori ayelujara pe ki wọn forukọ awọn to n lọ ẹrọ wọn fun PoS silẹ.
CAC yoo bẹrẹ si n sọ Opay ati MoniePoint loju lẹsẹ
Gẹgẹ bii atẹjade naa ṣe sọ, lara awọn banki ori ayelujara ti awọn eeyan n lo fun PoS julọ ti awọn yoo maa ṣọ lojulẹsẹ ni Opay ati MoniePoint.
Eyii ko ṣẹyin bi wọn ṣe ni awọn ileeeṣẹ naa n gba awọn ti ko forukọsilẹ lati maa ro ẹrọ wọn fun PoS.
Wọn ni awọn yoo fi ẹjọ awọn ileeṣẹ naa sun CBN ko le da seria to yẹ fun wọn.
Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn to n ṣe PoS, Association of Mobile Money and Bank Agents in Nigeria (AMMBAN) ko tii sọ nnkankan lori ọrọ naa.















