Ṣé ebi máa ń pa ọ́ tí o bá ń ṣe wàhálà lápọ̀jù? Ọ̀nà àbáyọ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Kate Bowie
- Role, Global Health, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Wahala aṣeju le ṣakoba fun eto ilera rẹ. o maa n fa ori fifọ, inu rirun, airi oorun sun, o si le mu ayipada ba bi o ṣe n jẹun si.
Ti a ba ṣe wahala laṣeju, o le maa jẹ ka maa ṣafẹri awọn ounjẹ didun bii chocolate ati pizza tabi ki ounjẹ ma tilẹ wu wa jẹ.
Amọ ki ni idi ti wahala aṣeju fi maa n ṣakoba fun bi a ṣe n jẹun si?
Ki ni wahala aṣeju?
Ọjọgbọn Rajita Sinha, to jẹ onimọ nipa iwuwasi eeyan sọ pe " Wahala aṣeju ni akoko ti ọkan ati ara eeyan ba n woye pe apa oun ko ka iṣẹ to wa niwaju rẹ, ti o si gbagbọ pe ko si ohun ti o le ṣe si ọrọ naa."
Awọn ohun to n ṣẹlẹ layika rẹ, wahala to wa ninu ọkan rẹ, ayipada ninu agọ ara rẹ bii ebi ọpagba tabi oungbẹ lo maa n pe ẹya kan ninu ọpọlọ ti orukọ rẹ n jẹ 'hypomones' pe wahala wa.
Sinha sọ pe ẹya yii le mu ki ẹje eeyan ṣadede ru soke ki ọkan irufẹ ẹni bẹẹ ti maa ṣiṣẹ pajawiri.
Ti eeyan ba n ṣe wahala diẹdiẹ, awọn onimọ ni o dara fun ẹda lati tete le ṣe awọn aṣeyọri kan amọ wahala aṣeju lewu fun eeyan.
Awọn ti wọn n ṣe wahala aṣeju tun le ni iṣoro to pọ si ti wọn ba koju iṣoro pẹlu ololufẹ wọn, iṣoro lẹnu iṣẹ tabi ninu eto iṣuna wọn.
Irufẹ awọn eeyan yii le ko sinu ibanujẹ ọkan, airi oorun sun, wọn tun le sanra lojiji.
Kini ni idi ti wahala aṣeju nipa lori bi eeyan ṣe n jẹun si?
Wahala aṣeju le jẹ ki ebi tete maa pa eeyan bẹẹ lo le mu ki eeyan gbagbe ebi.
Mithu Storoni, to jẹ onimọ nipa neuro-ophthalmology to tun kọ iwe "Stress-Proof" ati "Hyperefficient" sọ pe "mo ranti nigba ti mo n kawe fun idanwo mi, mo dubulẹ aisan."
Fun awọn kan, niṣe ni wọn maa gbagbe ebi gẹgẹ bii ohun ti Storoni sọ.
O ni "Amọ ni ida keji ẹwẹ, a mọ pe ni kete ti wahala ba ti pọju, ọpọlọ eeyan a maa bere ṣuga."
O ni eyii maa n jẹ ki awọn kan maa wa ounjẹ kiri lati le gbaradi fun ohun aimọ to n bọ lọna.
Ipa wo ni wahala aṣeju le ni lara bi eeyan ṣe n jẹun si?
Ipa ti wahala aṣeju n ni lara eeyan ju ki ebi kan maa pa tabi ki oju rẹ maa poyi nikan lọ.
Ti agọ ara rẹ ba ti ṣe wahala ju, iṣan to n gbe ẹjẹ ninu rẹ yoo maa bere ṣuga, eyii ti ko ni jẹ ki insulin ara rẹ - eroja to n ṣakoso bi ṣuga ṣe pọ to lara - ṣiṣẹ daadaa, gẹgẹ bii ọrọ Ọjọgbọn Sinha.
Inu ẹjẹ ni glucose maa n duro si dipo ki eeyan lo o, eyii to maa n jẹ ki iye ṣuga inu ara pọ lapọju.
Eyii maa n fi awọn eeyan sinu ewu to bẹẹ ti wọn le fi ni aisan itọ ṣuga, wọn tun le sanra ju bo ṣe yẹ lọ, eyii to le mu ki wọn ni aisan itọ ṣuga.
Ti eeyan ba sanra ju, o le mu ki iyatọ de ba bo ṣe maa n jẹun. Fun awọn ti wọ sanra, ara wọn maa n kọ insulin, to n tumọ si pe ti wọn ba ti ṣe wahala laṣeju ọpọlọ wọn a maa bere fun ṣuga.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi o ṣe le dẹkun ounjẹ ajẹju nitori wahala apọju
Lakọkọ, ma gbagbe pe oorun ṣe pataki pupọ, ma fi oorun dun ara rẹ.
Awọn onimọ ni ti wahala ba pọ ju fun, gbiyanju lati maa sun dede nitori oorun naa yoo jẹ ki ọpọlọ rẹ sinmi daadaa.
Ti o ko ba sun daadaa, ounjẹ to ni ṣuga yoo maa wu ọ lati jẹ daadaa eyii to lewu fun ilera rẹ.
Ere idaraya tun le ran ọ lọwọ lati gbe oju kuro lara wahala rẹ, ki ọpọlọ rẹ si le ṣiṣẹ daadaa.
Irufẹ ounjẹ wo ki o yẹra fun ti o ba n ṣe wahala lapọju?
Ọjọgbọn Sinha kilọ pe ki a ṣọra fun awọn ounjẹ inu agolo ati awọn ounjẹ atọwọda.
O ni "Yago fun awọn ounjẹ ti yoo jẹ ki iye ṣuga to wa ninu agọ ara rẹ tunbọ lọ soke.
"Maa jẹ awọn ounjẹ to ni eroja aṣaraloore protein bii ẹran, ẹwa ati ẹja."
Onimọ naa tun kilọ lodi si ọti mimu paapaa ti o ba fẹ maa fi pa ironu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images












