Ajínigbé jí àwọn ọmọ ilẹ̀ China méjì gbé lẹ́nu isẹ́ ní Kwara

Aworan awọn agbebọn meji to boju-bomu pẹlu ibọn ti wọn gbe dani

Oríṣun àwòrán, Arise TV

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn ajinigbe to n ṣọṣẹ lẹmọlẹmọ nipinlẹ Kwara tun gba ọna miran yọ pẹlu bi wọn ṣe ji awọn ọmọ orilẹede China meji gbe lasiko ti awọn oyinbo naa n ṣiṣẹ oju ọna tijọba gbe fun wọn.

Iwadii BBC News Yoruba fidi ẹ mulẹ, pe awọn oyinbo yii wa lara ikọ to n ṣe isẹ opopona BUA Bode Saadu/Kaiama/Kosubosu, nigba ti awọn agbebọn naa sọsẹ.

Aarọ ọjọ Aje to kọja ni a gbọ pe awọn agbebọn naa yabo opopona ti awọn ọmọ ilẹ China ọhun ti n ṣiṣẹ oju ọna.

Ṣugbọn agbegbe Ejidongari, nijọba ibilẹ Moro, ipinlẹ Kwara ni iṣẹlẹ yii ti waye ni pato.

Iro ibọn to n ro lakọlakọ latọwọ awọn ajinigbe ni awọn ara adugbo naa kọkọ bẹrẹ si i gbọ, eyi lo si ko ipaya ba gbogbo wọn kawọn agbebọn naa too nawọ gan meji lara awọn oyinbo China.

Bi wọn ṣe mu wọn ni wọn gbe wọn lọ sibi ti ẹnikan ko mọ.

A kò tí ì gbọ́ nǹkan kan látọ̀dọ̀ àwọn ajínigbé náà- Ọlọ́pàá Kwara

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Adekimi Ojo lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nipinlẹ naa, pẹlu rẹ ni awọn ọlọpaa miran

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lalẹ Ọjọbọ, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Adekimi Ojo, sọ pe:

"Loootọ ni wọn ji awọn oyinbo China meji gbe lẹnu isẹ, ṣugbọn a ko ti i gbọ nnkan kan latọdọ wọn, awọn ajinigbe naa ko ti pè titi di akoko yii"

Bakan naa, ni ana ọjọ Ẹti, CP Adekimi tun sọ fun awọn oniroyin pe isẹ n lọ lati doola awọn oyinbo naa.

Olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa nipinlẹ Kwara ni Adekimi ti sọrọ naa lasiko to n ṣafihan oniruuru afurasi ọdaran ti ọwọ ọlọpaa ti ba ni ipinlẹ Kwara.

Ọga ọlọpaa naa sọ pe gbogbo igbesẹ agbofinro ko ṣee maa fi lede lori afẹfẹ, o ni ṣugbọn awọn yoo ri i pe awọn to wa nigbekun ajinigbe gba itusilẹ.

Tẹ o ba gbagbe, lati bii oṣu meji sẹyin ni ijinigbe ti di lemọ-lemọ nipinlẹ Kwara, paapaa julọ, ni ẹkun Guusu ipinlẹ naa. (Kwara South).

Ijinigbe awọn olujọsin mẹjidinlogoji to waye ni ilu Eruku, ipinlẹ Kwara, jẹ ọkan gboogi to milẹ titi, lẹyin rẹ ni ijinigbe eeyan mẹwaa to tun waye ni ilu Isapa ati awọn ilu mi-in.

Lọtẹ yii, apa Ariwa Kwara (Kwara North) ni ijinigbe yii ti waye.