"Òfin Sharia wà lára nǹkan tó ń fa ìṣekùpani Kristẹni ní Naijiria"

Aworan ile igbimọ aṣofin orilẹede Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹgbẹ kan ti wọn pe orukọ ara wọn ni Council on Foreign Relation ni wọn farahan ni ile igbimọ aṣofin orilẹede Amẹrika, ti wọn si sọ pe ofin Sharia wa lara ohun to n dakun iṣẹlẹ iṣekupani kristẹni ni apa ariwa Naijiria.

Bakan ni ẹgbẹ naa tun pe fun ki ijọba wọgile ikọ agbofinro Hisbah to wa ni apa ariwa orilẹede Naijiria.

Ipe yii waye lasiko ti ẹgbẹ naa yọju si ijoko ile igbimọ aṣofin mejeeji ni Amẹrika nibi ti wọn ti n yanayana ọrọ lori ohun to n fa rogbodiyan ni Naijira, paapa eyi ti wọn ni o n ṣekupa awọn kristẹni.

Nigba to n sọrọ, Ebenezer Obadare, to jẹ ọmọ ẹgbẹ kilọ pe ijọba Sharia to wa ni awọn ipinlẹ mejila to n lo ofin Sharia jẹ ibi kan ti awọn alakakiti ẹsin Islam pọ si ju, ti wọn si n ṣe ikọlu.

Awọn ọmọ orilẹede Naijiria, paapa lati apa ariwa, ti bu ẹnu atẹlu iroyin naa pe ko ni ẹsẹ nilẹ rara

Bakan naa, kete ti iroyin yii jade ni ile ẹjọ giga ti ẹsin Islam ati awọn ẹgbẹ Musulumi lorilẹede Naijiria ti wọgile iroyin naa.

Eyi lo fa ti ileeṣẹ BBC fi gbera lati ṣe iwadii lori ki gan an ni anfani ofin Sharia ninu ofin orilẹede Naijiria ati lati mọ o ṣeeṣe ki wọn yọ kuro ninu iwe ofin

Ofin Sharia ninu iwe ofin Niajiria

Ọjọgbọn Bulama Bukarti, agbẹjọro kan ni ilu UK, sọ fun BBC pe erongba yiyọ ofin Sharia kuro ninu iwe ofin Naijiria ko ki n ṣe nnkan kekere rara.

"Ṣharia ati agbara to ni ni awọn ipinlẹ ti wọn ti n lo wa ninu iwe ofin, eyi yoo jẹ ko nira diẹ lati yọ kuro nitori aarẹ Naijiria nikan ko le gbe igbesẹ yii."

"Koda ile igbimọ aṣofin agba ko da ṣe eyi. Awọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ni lati da si. To si jẹ awọn ipinlẹ ti wọn ti n lo awọn ofin Sharia yii ko ni gba pe ki wọn yọ ofin naa kuro ninu iwe ofin orilẹede Naijiria," Bukarti ṣalaye

Agbẹjọro agba Bukarti fikun pe ọna kan soso ti wọn le fi yọ ofin Sharia kuro ninu iwe ofin orilẹede Naijiria ni pe ki atunṣe iwe ofin naa waye, eyi to si jẹ pe yoo nira pupọ ko to le waye.

Igba wo gan an ni ofin Sharia darapọ iwe ofin Naijiria?

Bukarti ni ofin Sharia ti wa ninu iwe ofin Naijiria lati ọdun 1979, bo ti lẹ jẹ pe o ni okiki ni ọdun 1999 lẹyin atunṣe iwe ofin orilẹede Naijiria waye .

O ni lẹyin ọdun 1999, ti atunṣe ti ba iwe ofin yii, o fun awọn ipinlẹ ni agbara lati ma lo ofin yii.

"Ohun to ṣẹlẹ ti wọn fi pe fun ofin Sharia ni ọdun 1979 ni pe ofin ti wọn ṣe ni ọdun naa faye gba awọn idunadura kan lori igbeyawo, ogun, idile ati awọn nnkan mii, eyi lo fa ti wọn fi ṣe idasilẹ ile ẹjọ Sharia."

"Ṣugbọn ni ọdun 1999, awọn eeyan kan fẹ ki ofin Sharia ma dasi iwa ọdaran, eyi lo fa ti wọn ṣe afikun ofin Sharia sinu iwe ofin orilẹede Naijiria, sugbọn bayii wọn ti fẹ sii," Bukarti ṣalaye

Awọn ipinlẹ mejila ti wọn n lo ofin Sharia ni Naijiria

  • Zamfara State
  • Kano State
  • Sokoto State
  • Katsina State
  • Bauchi State
  • Borno State
  • Jigawa State
  • Kebbi State
  • Yobe State
  • Kaduna State
  • Niger State
  • Gombe State