Ìjọba Kogi kéde kónílé-ó-gbélé láwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan nítorí ètò àbò tó mẹ́hé

Gomina ipinlẹ Kogi, Usman Ododo ati ẹṣo alaabo rẹ

Oríṣun àwòrán, Kingsley Femi Fanwo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Pupọ ninu awọn ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Kogi ti n kede konile-o-gbele bayii latari eto abo to mẹhẹ nipinlẹ naa.

Akọroyin wa to wa ni Kogi sọ pe igbesẹ naa ko ṣẹyin bi ijinigbe ṣe di tọrọkọbọ lagbegbe naa lẹnu ọjọ mẹta yii.

Ti ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn agbebọn kan yabo ṣọọṣi C/S kan lasiko ti wọn jọsin lọwọ lọjọ isinmi ti wọn si ti ji oluṣọ agutan atawọn ọmọ ijọ gbe lọ nibẹ.

Ni ijọba ibilẹ iwọ oorun Yagba ni konile-o-gbele naa yoo bẹrẹ lati aago meje alẹ si aago marun un idaji lojojumọ.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ alaga ijọba ibile iwọ oorun Yagba, Babarinde Sunday, fi lede lo ti fi idi iroyin naa mulẹ.

O ni lasiko igbele yii ni awọn agbofinro yoo maa kaakiri igboro ilu lati ri daju pe ẹnikẹni ko rin gberegbere kiri lasiko naa.

Atẹjade naa sọ pe ẹnikẹni to ba tapa si ofin igbele naa yoo foju wina ijọba lai ro ti irufẹ ẹni ti ẹni naa n ṣe.

Lẹyin naa lo rọ awọn ọdọ, adari ilu atawọn awakọ ki wọn maṣe fi oju kere ofin konile-o-gbele naa.

Àwọn jàndùkú ṣíná ìbọn fún àwọn aráàlú tó dènà wọn ní Kogi, èèyàn mẹ́ta jáde láyé

Awọn agbebọn to fi aṣọ boju wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eeyan mẹta ti jade laye ni ilu Irunda, to wa ni ijọba ibilẹ ila oorun Yagba, nipinlẹ Kogi lẹyin ti awọn agbebọn kan sina ibọn bolẹ fun wọn loju popo.

Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna eto iroyin ipinlẹ ọhun, Kingsley Femi Fanwo fi lede, o ni ijọba ipinlẹ ọhun ba awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn kẹdun.

Iku awọn eeyan mẹta naa lo waye lagbegbe to yatọ sira awọn amọ ohun to ṣokunfa iku wọn ko yatọ sira.

Bi awọn janduku ṣe dana ibọn ya awọn araalu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Fanwo ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe asiko ti awọn janduku kan gbiyanju lati sa mọ awọn agbofinro lọwọ ni araalu dena de wọn ti wọn si ṣina ibọn fun awọn araalu naa.

O ni "iroyin to tẹ ijọba lọwọ ni pe awọn araalu bẹgi dina awọn janduku kan to fẹ salọ.

"Awọn ọdaran naa ṣina ibọn bolẹ fawọn araalu ọhun, eyii to yọri si iku eeyan meji nilu wọn nigba ti ẹnikan farapa lẹyin to fara gbọta ibọn, amọ o ti n gba itọju.

"Iṣẹlẹ yii lo mu ki awọn ọdọ kan ya bo aarin igboro ti wọn si bẹrẹ ifẹhonuhan.

"Nigba ti awọn ologun de agbegbe naa lati da alaafia pada, awọn ọdọ ọhun di awọn ologun naa lọwọ, awọn kan lara awọn olufẹhonuhna naa tun kọju ija si wọn eyii to yọri si ẹnikan ninu awọn ọdọ naa."

Kọmiṣọna ọhun ni yatọ si ọdọ kan to ku nibẹ, pupọ ninu awon ologun naa lo tun farapa yanayana.

Ẹwẹ, gomina Ahmed Usman Ododo ti ke si awọn ọdọ naa ki wọn ṣe suuru ki wọn si gba alaafia laaye lagbegbe wọn.

Ododo sọ fun wọn pe ko tọ fun awọn araalu lati maa kọju ija si awọn agbofinro labẹ botiwu ko mọ.

Gomina tun rọ awọn agbofirno atawọn ologun lati maa ṣe suuru pẹlu awọn araalu lasiko laasigbo laarin awọn mejeji.