Àwọn afurasí tọ́wọ́ tẹ̀ ṣàlàyé bí wọ́n ṣe pa òṣìṣẹ́ FRSC àti ọmọ rẹ̀ tí wọ́n jí gbé l'Ogun

Aworan Lasisi Funmilayo Oluwamayokun, ati ọmọ rẹ, Lasisi Sewa.

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

L'Ọjọru, ọsẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun fi oju awọn afurasi mẹta kan ha f'awọn akọroyin lori iku oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ oju popona tijọba apapọ, FRSC, Lasisi Funmilayo Oluwamayokun, ati ọmọ rẹ, Lasisi Sewa.

Ẹni ọdun mejidinlogoji ni wọn pe Lasisi Oluwamayokun, nigba ti ọmọ rẹ, Lasisi Sewa jẹ ọmọ ọdun mejila.

Fajemirokun Victor, ẹni ọdun mejidinlogoji; Gboyega Daramola, ẹni ọdun mọkandinlogoji ti wọn tun n pe ni Abere Ifa, ati Sunday James, toun naa jẹ ẹni ọdun mejidinlogoji ni awọn afurasi mẹta ti ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa tẹ.

Nigba ti ọga ọlọpaa ipinlẹ Osun, Ibrahim Gotan, n sọrọ lasiko to n foju wọn han niluu Osogbo, o ṣalaye pe ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun 2025 ni ọrọ naa bẹrẹ lọdọ awọn, nigba ti awọn kan wa fi ẹjọ sun ni ileeṣẹ wọn to wa ni Ikoyi.

"Ẹjọ ti wọn mu wa ni pe ẹnikan to n jẹ Fajemirokun Victor, ẹni ogoji ọdun di awati lati ọjọ keji, oṣu Kọkanla, lẹyin to rin irin ajo lati ilu Osogbo lọ si Ori Oke Adura to wa ni Ikoyi fun eto adura," ọga ọlọpaa sọ bẹẹ.

Siwaju sii lo sọ pe: "Gbogbo ẹrọ ibanisọrọ Victor lo ti ku, to si jẹ pe gbogbo akitiyan lati tọpinpin rẹ lo ja si pabo.

"Lẹyin eyi ni wọn tare ẹjọ naa lo si ẹka to n ri sọrọ ijinigbe lati ṣe iwadii, ti wọn si ṣawari ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla rẹ loju ọna marosẹ Ibadan si Ife lasiko iwadii.

"Awọn ọtẹlẹmuyẹ wọnu gbogbo igbo to wa lagbegbe naa, ṣugbọn ti won ko kofiri ohun to jọ mọ ijinigbe. Ṣugbọn iwadii siwaju sii lo jẹ ka ṣe aṣeyọri lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gotan fidi rẹ mulẹ pe ọjọ naa ni wọn fọwọ ṣikun ofin mu Gboyega Daramola, ẹni ti wọn n pe ni Abẹrẹ Ifa to jẹ babalawo, to si jẹwọ pe ẹnikan to n jẹ Fajemirokun Victor jẹ ọkan lara awọn onibara oun.

O sọ pe ọjọ keji, oṣu Kọkanla ti Victor kuro nilẹ, lo mu obinrin kan ati ọmọ rẹ wa lati fi ṣetutu ọla, to si ti pa awọn mejeeji. Bakan naa lo tun darukọ awọn miran ti wọn jọ mọ nipa iṣẹlẹ naa, Sunday James, Kehinde ati Idowu."

"Ju gbogbo rẹ lọ, Damilọla lo mu awọn ọtẹlẹmuyẹ lọ si odo adagun Esa-Odo lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla, nibi ti wọn ti ṣawari oku Oluwamayokun, ti wọn si rii pe ọpọ ẹya ara rẹ to ṣe papaki ni wọn ti ge lọ," Gota n sọ siwaju.

O ni eyi lo jẹ ki iwadii tun gbe wọn lọ sipinlẹ Ekiti, nibi ti wọn ti mu Sunday James nibi to sapamọ si, to si lo jẹwọ pe oun loun dumbu iya ati ọmọ, labẹ aṣẹ ọga rẹ to jẹ babalao, iyẹn Abẹrẹ Ifa.

James naa lo mu wọn lọ sinu igbo ti oku Sewa, ọmọ ọdun mejila naa wa, ti wọn si ti yọ awọn ẹya ara rẹ. O lawọn ti ko awọn oku naa lọ si ile igbokusi ti awọn olukọni ti UNIOSUN.

Bakan naa lo sọ pe awọn ọlọpaa Interpol lo rọwọ to Victor ni orileede Ghana to salọ, ko to di pe wọn fa a le wọn lọwọ.

Abẹrẹ Ifa, ọkan ninu awọn afurasi ba awọn akọroyin sọrọ

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Daramọla sọ pe ẹsun apaayan ni wọn fi kan oun nigba ti wọn fọwọ ṣikun ofin mu oun.

"Ẹnikan to n je Dare lo mu Victor wa sile ọdọ mi, kii ṣe TikTok lo ti mọ mi. Bo ṣe mọ mi niyẹn, to si maa n wa sile ọdọ mi ni gbogbo igba. Oṣu to kọja lo pe mi pe oun fẹẹ ba mi sọrọ, to si tun wa sile mi

"Oun pẹlu Dare ni wọn jọ wa sile mi, wọn ni ki n mu foonu mi rin jinna, oun naa si mu foonu rẹ jinna. O si ṣalaye pe oun lọ si ọdọ Aafa kan to sọ pe obinrin kan toun n fẹ ni Abẹokuta lo n lo ogo oun, ati pe bi obinrin naa ko ba ku, oun ko le ri ogo oun lo.

"O sọ pe nnkan ti bajẹ foun kọja sisọ, mo wa sọ fun un pe to ba to asiko to fẹẹ ṣe nnkan to ba fẹẹ ṣe, ko wa yọju si mi."

Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe ile iwosan loun wa lọjọ kinni, oṣu Kọkanla lọdọ iyawo oun to ṣẹṣẹ bimọ, ti Victor fi bẹrẹ sii pe oun lori foonu wi pe oun ti wa nile ọdọ oun.

"Agogo mẹjọ alẹ lo de lọjọ naa, mo si sọ fun un pe a ko le rira nitori mo wa nibi kan, ati pe o di ọjọ keji ka to le rira, mo si ni ko lọ wa otẹẹli kan sun si. Nigba to di ọjọ keji, lo mu obinrin naa ati ọmọ ẹ wa.

"O ni ṣe koun pa awọn mejeeji, mo wa sọ pe ko le pa wọn sile ọdọ mi. Mo wa pe Goriite ati Idowu lati wa ba mi, ṣugbọn ki n to de lati ile iwosan ti mo lọ, Ifa kan ni wọn n da lọwọ. Awọn yẹn lo sọ fun mi pe ki n ma ṣe nnkan ti Victor fẹẹ ṣe.

"Igba to ya ni wọn mu awọn mejeeji lọ sinu igbo lati lọ pa ọmọ ati iya. Nko ba wọn lọwọ si, ṣugbọn ohun ti mo fi jẹbi ni pe emi ni mo pe awọn mejji ti wọn ṣe iranwọ lati pa wọn."

Victor naa sọrọ

Victor, afurasi ti wọn lo ji Oluwamayokun ati ọmọ rẹ Sewa gbe lati pa wọn sọrọ, o si jẹ ko di mimọ pe ọdun 2024 loun pade obinrin naa ni Ori-Oke Ogooluwa.

Ọkunrin loun ati Oluwamayokun jọ n yan ara wọn ni ale latigba naa ni, ko too di pe nnkan bẹrẹ sii yi biri foun, to di pe gbogbo dukia toun ni, lo n parẹ mọ oun loju.

"Ọdọ Abẹrẹ Ifa ni mo ti lọ ṣe iwadii nipa ohun ti mo fẹẹ ṣe, mo si fi fọto obinrin naa han an lori foonu lati ba mi fi Ifa beere si. Abẹrẹ Ifa lo sọ pe ki n mu obinrin naa wa ba oun.

"Abẹrẹ Ifa sọ pe ti mo ba mu obinrin naa wa, awọn yoo pa a lati fi ṣetutu ọla fun mi, ati pe gbogbo nnkan ti mo ti padanu ni mo maa ri pada.

"Nko lọ sọdọ Aafa kankan tẹlẹ, Abẹrẹ Ifa lo sọ fun mi pe obinrin naa lo n lo ogo mi, wi pe afi ki n mu wa lati fi ṣetutu ọla, ti maa si gba ogo mi to n lo pada."

Ni bayii, ọga ọlọpaa, Gotan ti wa fidi rẹ mulẹ pe bo tilẹ jẹ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju, awọ nyoo foju gbogbo afurasi naa han niwaju ile-ẹjọ nigba ti asiko ba to.