Kí nídìí táwọn Ajẹ́rìí Jèhófà kìí fí gba ẹ̀jẹ̀ bí obìnrin tó ní àìsàn jẹjẹrẹ ṣe kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀

Omolola Mensah to wọ ankara alawọ yẹlo ati buluu, to si de wiigi kekere, ń rẹ́rìn-ín sí ẹ̀rọ ayàwòrán

Oríṣun àwòrán, Omolola Mensah

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Níṣe ni awuyewuye gba orí ayélujára kan lópin ọ̀sẹ̀ lẹ́yìn tí obìnrin kan tó gbajúmọ̀ fún títa oúnjẹ tútù lórí ayélujára, Omolola Mensah tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Auntie Esther kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ nílé ìwòsàn nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀.

Auntie Esther tó gbajúmọ̀ lórí ìkànnì X látàrí iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bí ó ṣe máa ń bá àwọn èèyàn ra oúnjẹ tútù, kàn sójú òpó náà nínú oṣù Kọkànlá láti bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ nítorí àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn tó ní.

Àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí òpó ayélujára sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún-un nípa dídá owó mílíọ̀nù lọna ọgbọ̀n náírà fún-un láti fi ṣe ìtọ́jú ara rẹ̀.

Auntie Esther, ẹni ọdún méjìdínlógójì, tó jẹ́ ọmọ ìjọ Ajẹ́rìí Jèhófà fi sójú òpó náà pé àwọn ẹ̀yà ara òun tó wà nínú ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.

"Àwọn dókítà ní àwọn yóò fún Auntie Esther ní ẹ̀jẹ̀ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ chemotherapy ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ torí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Ajẹ́rìí Jèhófà"

Aunty Esther ní àwọn dókítà sọ fún òun, ni ìbẹ̀rẹ̀ ètò ìtọ́jú "chemotherapy" pé òun máa gba ẹ̀jẹ̀ ṣùgbọ́n òun àti àwọn ẹbí òun ti fẹnukò pé òun máa bẹ̀rẹ̀ sí ní gba abẹ́rẹ́.

"Mo bọ̀wọ̀ fún gbogbo nǹkan tí àwọn èèyàn bá ń sọ ṣùgbọ́n abẹ́rẹ́ àti jíjẹ àwọn oúnjẹ tí yóò máa fún mi lẹ́jẹ̀ ni èmi àtàwọn ẹbí mi fẹnukò láti ṣe.

"Dókítà mi ti gba ìpinnu mi yìí wọlé, tí wọ́n sì ní díẹ̀ díẹ̀ ni ètò ìtọ́jú ọ̀hún yóò máa lọ títí tí chemotherapy fi máa bẹ̀rẹ̀."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ilé ìwòsàn Lakeshore Cancer Centre tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko ni Auntie Esther ti ń gba ìtọ́jú.

Àmọ́ awuyewuye bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó bá a gba owó fún ìtọ́jú àìsàn rẹ̀, Obi-Dickson, jáde sọ̀rọ̀ pé níṣe ni Auntie Esther kọ̀ láti sọ hulẹ̀hulẹ̀ bí ètò ìtọ́jú rẹ̀ ṣe ń lọ sí.

Obi-Dickson dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tí wọ́n ṣe àtìlẹyìn fún Auntie Esther àti pé ó ti ń dáhùn sáwọn ìtọ́jú tí wọ́n ń fún-un. Ó ní wọ́n ti ń gbìyànjú láti ri dájú pé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ sókè bí ó ṣe yẹ kó tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ míì tó kàn.

Ó ní àwọn dókítà ní àwọn máa nílò láti fún Auntie Esther ní ẹ̀jẹ̀ kí wọ́n tó lè tẹ̀síwájú pẹ̀lú chemotherapy ṣùgbọ́n ó ní òun kò ní gba ẹ̀jẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ Ajẹ́rìí Jèhófà, tó sì ní òun máa lo ìlànà míì láti pọnkún ẹ̀jẹ̀ òun bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìlànà náà kò lè yá tó tí wọ́n bá fún-un ní ẹ̀jẹ̀.

Èyí ló bí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n dá owó fún ìtọ́jú obìnrin náà ninú pé kí wọ́n kó owó náà fún ẹlòmíràn tó ṣetán láti gba ìtọ́jú tó péye dípò ẹni tó kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn míì wòye pé ó yẹ káwọn èèyàn gba ìpinnu rẹ̀ wọlé nítorí wọ́n nílò láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀sìn àti ìgbàgbọ́ rẹ̀.

Kí ló dé táwọn Ajẹ́rìí Jèhófà kìí ṣe fá gba ẹ̀jẹ̀?

Ìjọ Ajẹ́rìí Jèhófà lórí ìtàkùn ayélujára sọ pé àwọn máa ń wá ọ̀nà tó dára jùlọ láti fi wá ìlera tó peye fáwọn ọmọ ìjọ wọn.

"Tí a bá ní ìpèníjà ìlera, a máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà tó mọ́ṣẹ tí wọ́n sì lè ṣe iṣẹ́ abẹ láì ṣe pé wọ́n ń fa ẹ̀jẹ̀ sí èèyàn lára. A dúpẹ́ lórí àwọn ìdàgbàsókè tó ń wáyé lẹ́ka ètò ìlera.

"Ọ̀pọ̀ ìlànà ìtọ́jú tí kò nílò gbígba ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n ti ń lo láwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà tó sì ti ń jẹ́ ohun táwọn ọmọ ìjọ náà ti ń jẹ àǹfàní rẹ̀ káàkiri àgbáyé.

"Ní àwọn orílẹ̀ èdè kan, àwọn èèyàn le bèèrè fún ìlànà ìtọ́jú tí kò nílò gbígba ẹ̀jẹ̀", ìjọ náà kọ sórí òpó wọn.

Wọ́n ní ìpinnu láti má gba ẹ̀jẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ní ìpèníjà ìlera jẹ́ ohun tó nííṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn àti ìgbàgbọ́ wọn.

Wọ́n ní ìwé mímọ́ yálà ti ìgbà nnì àti tuntun ni wọ́n pa á láṣẹ pé kí èèyàn jìnà sí gbígba ẹ̀jẹ̀ ẹlòmírà sára.

Bákan náà ni wọ́n sọ pé Ọlọ́run rí ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ẹlẹ́mìí, tó sì jẹ́ àwọn máa ń kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ láti ṣe ìgbọ́nràn sí Ọlọ́run tó ń fún èèyàn ní ẹ̀mí.

Lára àwọn ibi tí wọ́n kà nínú bíbélì pé Ọlọ́run ti pa wọ́n láṣẹ láti má gba ẹ̀jẹ̀ ni:

Genesis 9:4

Ṣùgbọ́n ẹ ò gbọdọ̀ jẹ ẹran tí ẹ̀jẹ̀ bá ṣì wà lára rẹ̀

Leviticus 17:10

Mo máa gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ ọmọ Israeli kankan tàbí àjòjì kankan tó bá ń gbé nínú wọn tó bá máa ń jẹ ẹ̀jẹ̀, mo máa yà wọ́n kúrò lára àwọn èèyàn.

Deuteronomy 12:23

Ṣùgbọ́n ẹ ri dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀, nítorí ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí, ẹ ò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀mí pẹ̀lú ẹran.

Acts 15:28, 29

Ẹ jìnà sáwọn oúnjẹ tí wọ́n máa ń fún àwọn òrìṣà jẹ, láti ẹ̀jẹ̀, ẹran tí wọ́n fún lọ́rùn pa àtàwọn ìwà ìbálòpọ̀ tí kò tọ́. Ẹ máa ṣe rere tí ẹ bá jìnà sáwọn nǹkan wọ̀nyí.

Leviticus 17:14

Nítorí gbogbo ẹ̀mí ohun tí a ṣẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi sọ fáwọn ọmọ Israeli pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan nítorí ẹ̀mí gbogbo ohun abẹ̀mí ni ẹ̀jẹ̀ wọn; ẹnikẹ́ni tó bá jẹ wọ́n ni a máa gé dànù.