Ohun ìyanu rere ń bọ̀ nínu ìjọba Tinubu, gbogbo ọ̀tá rẹ̀ ni ojú yóò tì - Remi Tinubu

Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi tó wọ aṣọ funfun àti adé aláwọ̀ búlúù ń gbé ọ̀pá àṣẹ aláwọ̀ Goolu fún aya ààrẹ Naijiria, Oluremi Tinubu ẹni tó wọ aṣọ oke ìró àti buba aláwọ̀ funfun, to si de adé funfun bakanna.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ilu Ile Ife sọkutu wọwọ ni ọjọ Aiku ana nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèkànlú wọ ilu naa lati ba Oonirisa ṣe ajodun ọdún kẹwàá to gorí ìtẹ́ àwọn baba ńlá rẹ.

Lara awọn èèkànlú to péjú síbi ayẹyẹ naa ni aya ààrẹ orílẹ̀èdè Naijiria, Oluremi Tinubu àti ààrẹ àná, Oloye Olusegun Obasanjo.

Nígbà to n sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ naa, aya ààrẹ sapejuwe Ọba Adeyeye Ogunwusi gẹgẹ bí ọlọgbọn ati oloye eeyan ninu awọn Oriade to wa ni orilẹ-ede Naijiria.

Gomina Adeleke, Aya ààrẹ, ọba Ogunwusi àtàwọn àlejò pàtàkì miran jókòó sórí àga ọlọ́lá

‎"Mo dupẹ pupọ lọwọ Ọba Adeyeye Ogunwusi fun oye Yeye Asiwaju ti Ilẹ Oodua ti wọn fi da mi lọla"

‎Aya Tinubu ni Ọba Adeyeye Ogunwusi, jẹ ọmọde lọjọ ori ṣugbọn iwa agbalagba mbẹ ninu wọn gidigidi..

‎"Ọba Adeyeye Ogunwusi jẹ ẹni to ni ifarada pupọ ni gbogbo ọna patapata.

‎Mo dupẹ pupọ lọwọ Ọba Adeyeye Ogunwusi fun oye Yeye Asiwaju ti Ilẹ Oodua ti wọn fi da mi lọla loni ọjọ Aiku ọjọ Keje osu Kejila ọdun 2025 yii.‎"

‎ Aya Aarẹ wa bẹ gbogbo ọmọ Naijiria pe ki wọn tubọ mu suuru fún Ààrẹ Bọla Tinubu lati f'ọkan balẹ tun Naijiria ṣe.

‎O fikùn pe akoko naa ti de bayii ti àyípadà rere yóò ba orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

‎"Opin yoo ba gbogbo wahala to n ṣẹlẹ ni orile-ede Naijiria lọdun yii.

Ọdun 2026 yoo si jẹ ọdún ayọ fun gbogbo ọmọ orile-ede Naijiria.

‎Gbogbo awọn to sọ isọkusọ si iṣejọba Ààrẹ Bọla Tinubu ni oju yoo ti patapata nigba ti wọn ba ri ohun iyanu ti yoo ṣẹlẹ ni orilẹ-ede yii.

Oloye Olusegun Obasanjo wa laarin gomina ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu àti Gómìnà ana ni ìpínlẹ̀ Ogun, Ibikunle Amosun, tí gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ agbada àti Sokoto pẹlu fìlà funfun

N ko le ni anfaani lati ba Ọọni ṣe ayẹyẹ ọgbọn ọdun lori itẹ àmọ́ máa ba se ayẹyẹ ogun ọdun -Olusegun Obasanjo

Nígbà tí òun náà ń sọrọ níbi ayẹyẹ naa, Ààrẹ àná lorile-ede Naijiria, Olusegun Obasanjọ, ni oun ko ni le ni anfaani lati ba Ọba Adeyeye Ogunwusi ṣe ayẹyẹ ọgbọn ọdun lori ìtẹ́.

O ni o seese kí òun má wa loke eepẹ lásìkò naa àmọ́ oun yoo gbiyanju lati ba sẹ ayẹyẹ ogun ọdun lórí apere.

‎Obasanjo wa rọ Ọba Adeyeye Ogunwusi pe ko tubọ ko awọn eeyan mọra ati ibi gbogbo ti kudiẹ kudiẹ ba wa ko ṣe atunse rẹ ni kiakia.

Ooni tí Ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi to wọ aṣọ agbada àti Sokoto aláwọ̀ funfun pẹlu ade aláwọ̀ búlúù ń ju ọwọ́ sáwọn èèyàn tó ń kí I, àwọn ẹmẹ̀wà rẹ rọgba yí I ká.

Irinajo ọdún mẹwa mi lórí itẹ kun fún oniruru ipenija - Ọọni Ife

Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ọọni ti Ile-ifẹ ti ṣapejuwe Irinajo ọdun mẹwa to lo lori apere awọn babanla rẹ, bíi oun to kun fun ipenija oniruru ni gbogbo ọna gbogbo.

‎Ọba Adeyeye Ogunwusi, wa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun Irinajo ọdun Mẹwa naa ti oun ti lo, ti oun si ni aseyọri lọpọlọpọ.

‎Ọba Adeyeye Ogunwusi tẹsiwaju pé, oun dupẹ lọwọ aya Ààrẹ, Oluremi Tinubu fun aduroti oun ni gbogbo igba ati akitiyan wọn lati jẹ ki orilẹ-ede Naijiria ko dara.