Ìjọba Osun ní ọlọ́pàá ń dúnkokò mọ́ òun, ọlọ́pàá ní kó mú ẹ̀rí wá

Ademola Adeleke ati Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Osun

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/NPF/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijoba ipinlẹ Osun ti fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa pe o n dunkoko mọ awọn oṣiṣẹ oun nitori oṣelu.

Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ ni ijọba Osun ti sọ ọrọ naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn oloṣelu kan n lo awọn ọlọpaa lati dunkoko mọ awọn oṣiṣẹ oun, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Atẹjade naa ti kọmiṣọna fun eto iroyin, Kolapo Alimi fi lede, sọ pe awọn ọlọpaa ọhun n fi ẹsun iwa ọdaran kan awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa.

O wa rọ ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria, Kayode Egbetokun, ko kilọ fun awọn oṣiṣẹ rẹ ki wọn ma fi ara wọn silẹ gẹgẹ bii irinṣẹ fun oloṣlu.

Alimi sọ pe "gẹgẹ bii ijọba to n bọwọ fun ofin, o jẹ iyalẹnu fun wa pe awọn ọlọpaa n gbogun ti awọn oṣiṣẹ wa nitori oṣelu.

"Lasiko yii to yẹ ki awọn ọlọpaa gbajumọ eto aabo to mẹhẹ, niṣẹ ni wọn n ṣe ẹru fun awọn oloṣelu, eyii to yato si ojuṣẹ ti wọn wa fun.

Alimi sọ pe gbogbo ọmọ Naijiria ni ọlọpaa wa fun, nitori naa ileeṣẹ ọhun ko gbọdọ fi ara rẹ silẹ fun awọn oloṣelu lati maa lo bii irinṣẹ lodi saraalu.

"Ijọba Osun gbọdọ mu ẹri jade lati gbe ẹsun ti wọn fi kan lẹyin"

Nigba ti BBC Yoruba kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun lori ẹsun yii, wọn ni awọn ti ri ẹsun ti ijọba Osun fi kan awọn amọ ijọba naa gbọdọ fi ẹri kin ẹsun naa nidi.

Agbẹnuṣọ ileeṣẹ ọlọpaa Osun, Abiodun Ojelabi sọ fun BBC pe wọn gbọdọ tọka si iṣẹlẹ kan ni pato lati fidi ẹsun naa mulẹ.

O ni "Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ti ri atẹjade ijọba Osun, wọn si ti fesi.

"Wọn (ijọba Osun) ko le ṣadede kọ ọrọ sita pe ọlọpaa n dunkoko mọ wọn lai fi ẹri kankan gbe ẹsun naa nidi, a fẹ ki wọn tọka si iṣẹlẹ kan tabi meji nibi ti ọlọpaa ti gbogun ti wọn tabi dunkoko mọ araalu."