Wo àwọn mínísítà tó bá Buhari ṣiṣẹ́ tó ń jẹ́jọ́ lọ́dọ̀ EFCC fẹ́sùn ìwà àjẹbánu

Oríṣun àwòrán, Others
Ní ọjọ́rú ni ìròyìn kan gbòde pé wọ́n ń wá mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fọ́rọ̀ òṣìṣẹ́, Chris Ngige àmọ́ agbẹnusọ rẹ̀, Fred Chukwuelobe ti sọ àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé ọ̀gá òun wà ní àhámọ́ àjó tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà ìyẹn Economic and Financial Crimes Commission, EFCC.
Ìkéde yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí àjọ EFCC gbé àtẹ̀jáde kan jáde níbi tí wọ́n ti fẹ̀sùn kan Ngige pé ó pawó tó lé ní N46bn tó jẹ́ owó tó wà fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Anambra ní póńpó nígbà tó wà nípò gómìnà ìpínlẹ̀ náà.
Bákan náà ni àjọ ICPC pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ EFCC tún fi ọ̀rọ̀ wá Ngige lẹ́nu wò lórí ẹ̀sùn pé àwọn aṣemáṣe kan wáyé nínú ìgbanisíṣẹ́ àjọ Nigeria Social Insurance Trust Fund, NSITF nígbà tó wà nípò mínísítà fọ́rọ̀ òṣìṣẹ́.
Chukwuelobe sọ pé ìròyìn tó gbòde pé wọ́n jí ọ̀gá òun gbé ló jẹ́ kí òun jáde sọ̀rọ̀ nípa ibi tó wà.
Ó ní "Ngige wà pẹ̀lú EFCC. Wọ́n kò ji gbé rárá."
Àmọ́ títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, EFCC kò ì tíì jáde sọ ohunkóhun nípa bóyá Ngige wà ní àhámọ́ wọn tàbí bẹ́ẹ̀kọ́.
EFCC fi Malami sí àhámọ́
Ṣáájú ni EFCC ti kọ́kọ́ fi agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà àti mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fọ̀rọ̀ òfin, Abubakar Malami sí àhámọ́ lẹ́yìn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí Malami kò ṣe rí ìdáǹdè tí wọ́n fún-un láti kúrò ní àhámọ́ náà gẹ́gẹ́ bí orísun ìròyìn kan ṣe sọ.
EFCC ní àwọn fi Malami sí àhámọ́ láti wá sọ tẹnu rẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án lórí owó tí Abacha jí kó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè èyí tí orílẹ̀ èdè Switzerland àti Island of Jersy ní UK dá padà fún Nàìjíríà.
Àjọ náà sọ pé ojoojúmọ́ ni Malami yóò fi máa yọjú sí iléeṣẹ́ wọn fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò títí oṣù Kejìlá ọdún fi máa parí.
"Ní báyìí, ẹ̀sùn méjìdínlógún ni à ń ṣe ìwádìí Malami fún. Ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ, àṣìlò ọ́fíìsì àti ṣíṣe àtìlẹyìn fáwọn agbéṣùmọ̀mí láwọn ẹ̀sùn tí à ń ṣe ìwádìí rẹ̀ fún.
"A ò lè sọ pé iye kan báyìí ni pàtó ló jẹ́ nítorí a tún ń ṣe àwárí àwọn owó míì bí a ṣe ń bá ìwádìí wa lọ."
Àmọ́ Malami ti jiyàn àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án yìí.
Ó ní lásìkò ìgbà tí òun ṣe mínísítà fọ́rọ̀ ìdájọ́, òun ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn iléeṣẹ́ àti àjọ ìjọba míì láti ri pé òfin tó tako lílu owó ìlú ní póńpó fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa.
Stella Oduah fojúba ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ṣíṣe N5bn kúmọkùmọ
Níṣe ni ìjọba Nàìjíríà tún wọ́ mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fétò ìrìnnà òfurufú Stella Oduah lọ sílé ẹjọ́ lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kejìlá, ọdún 2025 lórí ẹ̀sùn ṣíṣe owó N5bn kúmọkùmọ lọ́dún 2014.
Ẹ̀sùn márùn-ún ni ilé ẹjọ́ gíga ti ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Abuja kà sí Oduah lọ́rùn tó fi mọ́ lílẹ̀dí àpopọ̀ àti fífi irọ́ gbowó.
Láàárín ọdún 2011 sí 2014 ni Oduah ṣe mínísítà lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan.
Lára àwọn ẹ̀sùn náà ni pé Oduah purọ́ gba N2.4bn gba ti Broad Water Resources lábẹ́ iléeṣẹ́ ètò ìrìnnà òfurufú pẹ̀lú pé àwọn fẹ́ fi owó náà ra àwọn iohun èlò ìmọ̀ ẹ̀rọ.
Oduah àti èèyàn, Gloria Odita ló jọ ń jẹ́jọ́ lórí àwọn ẹ̀sùn náà ṣùgbọ́n tí àwọn méjéèjì sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn.
Adájọ́ Hamza Muazu gba béélì Oduah àmọ́ tó ní kó fi ìwé ìrìnnà rẹ̀ kalẹ̀ fún ilé ẹjọ́, pé kò gbọdọ̀ ṣe ìrìnàjò kúrò ní Nàìjíríà láì gba àṣẹ lọ́wọ́ ilé ẹjọ́.
Àwọn mínísítà Buhari tí EFCC ń wádìí wọn báyìí
- Timipre Sylva
Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí tó di ipò tó ṣe pàtàkì mú lásìkò ìṣèjọba ààrẹ Muhammadu Buhari ni Timipre Sylva tó ti fìgbà kan rí ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa.
Òun ni mínísítà kejì fọ́rọ̀ epo bẹntiróòlú lábẹ́ ìṣèjọba àná.
Ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kọkànlá ọdún yìí ni EFCC kéde Sylva gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá fẹ́sùn ṣíṣe owó ìlú tó tó bílíọ̀nù mọ́kànlélógún náírà (N21bn) kúmọkùmọ.
- Abubakar Malami
Malami ni mínísítà fétò ìdájọ́ àti agbẹjọ́rò àgbà Nàìjíríà tó lábẹ́ ìṣèjóba àná àmọ́ tí àjó EFCC ń ṣe ìwádìí lórí àwọn onírúurú ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé EFCC kò ì tíì só ohunkóhun lórí rẹ̀, Malami fúnra rẹ̀ gbé àtẹ̀jáde síta pé EFCC ránṣẹ́ pe òun.
Ó sọ pé ohun tí wọ́n ń pe òun fún kò ṣẹ̀yìn owó $346.2m tí Switzerland dá padà fún Nàìjíríà lára owó tí olórí orílẹ̀ èdè yìí tẹ́lẹ̀ rí, Sani Abacha lọ kó pamọ́ sílẹ̀ òkèèrè.
- Hadi Sirika
Hadi Sirika jẹ́ mínísítà fétò ìrìnnà òfurufú tó ṣe ìfilọlẹ̀ ọkọ̀ òfurufú 'Nigeria Air' èyí tí ìṣèjọba tó wà lóde gan pè ní ìwà màgòmágó.
Mínísítà fétò ìrìnnà òfurufú tó wà lóde báyìí, Festus Keyamo sọ pé ọkọ̀ òfurufú náà kìí ṣe ti Nàìjíríà bíkòṣe ti orílẹ̀ èdè Ethiopia tí wọ́n fi àsíá ti Nàìjíríà sí.
Keyamo sọ èyí lásìkò tí wọ́n ń bi í léèrè nípa ọkọ̀ òfurufú náà èyí tí Sirika ṣe ìfilọ́lẹ̀ nígbà tó kù díẹ̀ kí ìṣèjọba Buhari wá sópin.
Ní báyìí, EFCC ti gbé Sirika lọ sílé ẹjọ́ láti ṣàlàyé ara rẹ̀ lórí àwọn ìwà àjẹbánu tó wáyé lórí iṣẹ́ àkànṣe náà.
Lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án ni pé ó mọ̀ọ́mọ̀ gbé iṣẹ́ àkànṣe náà fún ọmọ rẹ̀ àti ọkọ ọmọ̀ rẹ̀.
- Godwin Emefiele
Bí í tilẹ̀ jẹ́ pé òun kìí ṣe mínísítà, ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó dipò tó ṣe kókó mú lábẹ́ ìṣèjọba tó kọjá ni Godwin Emefiele gẹ́gẹ́ bí gómìnà ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà.
Láti ìgbà tó ti kúrò lórí ipò ló ti ń jẹ́jọ́ lórí lílu owó ìlú ní póńó àti níní ohun ìjà lọ́wọ́ lọ́nà àìtọ́.
Ẹjọ́ rẹ̀ ṣì wà láwọn ilé ẹjọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko àti Abuja.
Àwọn mínísítà ohun àmúṣagbára tí wọ́n kojú ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu:
- Timipre Sylva - Mínísítà kejì fọ́rọ̀ epo bẹntiróòlù lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Buhari (2019–2023)
- Saleh Mamman — Mínísítà fọ́rọ̀ ohun àmúṣagbára lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Buhari (2019–2021)
- Diezani Alison-Madueke — Mínísítà fọ́rọ̀ epo bẹntiróòlù lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan (2010–2015)
- Muhammad Wakil — Mínísítà kejì fọ́rọ̀ ohun àmúṣagbára lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Goodluck Jonathan (2014–2015)
- Olu Agunloye — Mínísítà fọ́rọ̀ ohun àmúṣagbára lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Olusegun Obasanjo (2003)
- Dan Etete — Mínísítà fọ́rọ̀ epo bẹntiróòlù lábẹ́ olórí orílẹ̀ èdè ọ̀gágun Sani Abacha (1995–1998)















